Chiwetalu Agu: Mí o kàbàámọ̀ pé mo wọ́ aṣọ''Rising Sun'' tí wọ́n torí rẹ̀ mú mí

Oríṣun àwòrán, Google
Ilumọọka oṣere tiata Nollywood ti awọn ọmọ ogun ati DSS Naijiria mu laipẹ yi, Chiwetalu Agu ti ṣalaye ohun ti oju rẹ ri ni ahamọ.
Lasiko to n ba awọn akọroyin sọrọ, o ni n ṣe ni wọn fi oun si iyara to dọti, ti ko si si aṣọ lori ibusun ti wọn fun oun.
Koda o ni ibusun ti wọn gbe fun oun ti ya jatijati pẹlu.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Chiwetalu Agu ti gba òmìnira lọ́wọ́ àwọn sọ́jà tó mú u
- Agbébọn jí ìbejì ọba gbé àti èèyàn mẹta míì ní Kwara
- Bimbo Oshin ṣàlàyé ọ̀rọ̀ ìkẹyìn tí ọkọ rẹ̀ sọ fun un kó tó kú
- Wo àwọn ohun mẹ́jọ́ tí àwọn olólùfẹ́ gbọ̀dọ̀ ṣe lẹ́yìn ìbálòpọ̀
- Ohun tó yẹ kí o mọ̀ nípa Ọ̀jọ̀gbọ́n Oyebode Adebowale, gíwá tuntun ní fásitì Ibadan
- Godwin ṣá bàbá rẹ̀ ládá pa nítorí orí adìyẹ, Ó ní...
- Ẹ wo bí arákùnrin kan ṣe fi ọrún àti ọfà pa èèyàn márún ún
- "Olórí ọmọ ogun Islamic State ní Ìwọ̀ Oòrùn Afrika, ISWAP ti jáde láyé"
- Sàdáńkátà! Ẹ̀yin ẹ̀létò ààbò, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ yín fún ìkọlù sí ilé Sunday Igboho - Ààrẹ Buhari
- Àwọn afurasí gbin ǹkan olóró abúgbàmù sí ṣọ́ọ̀ṣì bàbá Wike, ọwọ́ pálábá wọ́n ségi!
O ni nkan bi wakati mẹsan si mẹwaa ni wọn fi n beere ọrọ lọwọ oun ṣugbọn wọn ko fi ọwọ kan oun.
Lọjọ Iṣẹgun to kọja yi ni wọn tu Chiwetalu silẹ kuro lahamọ ajọ ọtẹlẹmuyẹ DSS lẹyin tawọn ọmọ Naijiria fẹnu si ọrọ rẹ.
Ṣaaju ni o ti kọkọ wa ni ahamọ lọdọ awọn ọmọ ogun ti wọn ni o wọ aṣọ to ṣafihan ikọ IPOB ti ijọba fofin de.
Ninu ifọrọwerọ yii bakan naa, Chiwetalu sọ pe oun pinu lati fara da nkan ti oju ba ri lai ba awọn agbofinbro naa ṣe agidi.
''Mo lọ sibẹ ki wọn baa le gbọ nkan ti mo fẹ wi ni. Mi o ba ija lọ. Ijọba yii n ṣe bi ologun pupọ. Ki lo de ti wọn yoo mura kankan mọ eeyan ti kii ṣe ologun''
''Aarẹ Buhari ni lati pa iwa bi ologun to n hu ti. Bi ọrọ ba de ilẹ, o yẹ ki o ṣe bi baba ni nitori ti ọrọ ba tẹsiwaju bayi, ipe fun iyapa yoo le ju bo se wa yii lọ."
Nigba ti wọn beere lọwọ rẹ boya wọn dun koko mọ debi pe ẹru n ba lasiko ti o wa ni ahamọ, Chiwetalu sọ pe wọnk o ṣe bẹẹ.
''Wọn ko ba ọrọ de ibẹ yẹn boya nitori pe emi naa hu iwa ọmọluabi. Ko buru pupọ ṣugbọn kii ṣe ibi ti mo fẹ pada lọ.''
Chiwetalu tun sọ pe oun ko ribi ba mọlẹbi oun sọrọ lasiko ti oun wa ni ahamọ, ti eleyi si fọwọ kan oun lẹmi.
Mi o kabamọ pe mo wọ aṣọ ti wọn tori rẹ mu mi
Agba Oṣere wa kede pe oun ko ko abamọ wiwọ aṣọ ti wọn tori rẹ mu u.
O ni aṣọ naa ṣafihan oorun to n ran ni ati pe imọ nipa Geography sọ pe iha ila oorun ni oorun ti maa n yọ jade, ti a si maa wọ ni apa iwọ oorun.
''Ko jẹ iyalẹnu. Lila bi oorun a maa waye titi laelale ni. Bi eeyan ba ti sinmi lati maa la, o ku ni yẹn''
''Wiwa ti a wa si ile aye, a wa lati dagba si, lati ja fun ẹtọ wa lai bikita ohun ti ẹlomiran n ro lọkan''














