Son Kills Father Over Chicken Head: Orí adìyẹ fà wàhálà láàrin Godwin àti bàbá rẹ̀ nípínlẹ̀ Ondo, ló bá ṣá bàbá rẹ̀ làdá pa

Ọwọ ẹlẹwọn kan jade sita ninu ahamọ rẹ.

Oríṣun àwòrán, Pbs

Ọjọ buruku eṣu gbomi mu lọjọ naa ti arakunrin kan ṣa baba rẹ lada pa nitori o fun lori adiẹ jẹ ninu adiẹ to pa lati fi ṣe aburo rẹ lalejo.

Godwin Matthew ẹni ọdun mẹrindinlogun la gbọ pe o ṣa baba rẹ lada pa nilu Akure.

Alukoro ọlọpaa Funmi Odunlami ninu atẹjade to fi sita sọ pe iyawo oloogbe naa lo fi iṣẹlẹ ipaniyan naa to awọn agbofinro leti ni agọ ọlọpaa to wa ni Ala.

''Ni ọjọ kẹsan oṣu Kẹsan ni arabinrin Christianah Audu Matthew mu ọrọ ipaniyan wa si agọ ọlọpaa pe ọmọ rẹ Godwin Matthew tẹle baba rẹ lọ si oko ṣugbọn awọn pada wa mọ pe o ṣa baba rẹ lada pa''

''Lẹyin iwadii afurasi naa sọ pe baba oun ni ki oun pa adiẹ fi ṣe aburo rẹ Emmanuel Audu lalejo.Nitori pe baba rẹ fun ni ori adiẹ ikan jẹ lo mu ki o ṣa baba rẹ lada pa''

Ileeṣẹ ọlọpaa tun ṣalaye fun awọn akọroyin ninu atẹjade naa pe awọn ti mu arakunrin ẹni ọdun mẹrinlelọgọta kan Ajayi Awe to fipa ba ọmọdebinrin ọmọ ọdun mẹfa kan lo pọ.

Gẹgẹ bi o ti se sọ, ni nkan bi ago mẹ́jọ alẹ ni arabinrin Obademi Fatimah kan wa fẹjọ sun lagọ ọlọpaa pe eeyan kan fipa ba ọmọde kan lo pọ.

Àkọlé fídíò, Adeyemi Olubunmi Crown: Láti ìgbà ti mo ti fún ọkọ mi ni ẹ̀bùn mọ́tò ni ìfẹ́ wa ti yàtọ̀

Ninu alaye yi, o ni ọmọ oun ti wọn forukọ bo lasiri ti wọn jijọ n gbe ni ile kan naa ni arakunrin Ajayi Awe fipa ba lopọ ninu ile rẹ.

Awọn ọlọpaa ni wọn ti mu afurasi naa lọ si ahamọ ti ọmọdebinrin to farakasa iṣẹlẹ naa si ti n gba itọju nile iwosan.

Bakan naa ni alukoro ọlọpaa ni afurasi ọhun ti jẹwọ ẹsun ti wọn fi kan.

O ni ko ni pẹ tawọn yoo fi gbe lọ si ile ẹjọ lẹyin iwadii ọlọpaa.