Tunde Bakare: Ẹkùn tí Ààrẹ bá ti wá kọ́ ló pọn dandan, ọpọlọ orí rẹ̀ ló ṣe patàkì

Pasitọ Tunde Bakare

Oludasilẹ Ijọ Global Community Church, Latter Rain Assembly, Pasitọ Tunde Bakare ti sọ wi pe ẹkun ti aarẹ orilẹede Naijiria ba ti wa kọ lo pọn dandan, iṣejọba rere ni awọn eniyan nilo.

Pasitọ Tunde Bakare sọ eyi lasiko to lọ ṣe ipade idakọnkọ pẹlu aarẹ Muhammadu Buhari ni ilu Abuja.

O fi idunnu rẹ han si igbesẹ ile igbimọ aṣofin lati fi aṣẹ si ki awọn ọmọ Naijiria to wa ni oke okun naa ma a dibo fi ranṣẹ lati ori ẹrọ ayelujara.

Bakare ni igbese yii yoo fi ẹtọ awọn oludibo mulẹ, paapaa awọn ti ọjọ ori wọn ti to lati si ibo.

Pasitọ Bakare to dije dupọ aarẹ pẹlu Buhari ni ọdun 2011, ti bu ẹnu atẹ lu iṣejọba rẹ lọpọ igba.

Bakare ni ipade ti oun ṣe pẹlu aarẹ Buhari ni lati sọ gbogbo ohun to wa ni ọkan oun lori bi iṣejọba Naijiria ṣe ri.

Lori agbekan ipo aarẹ lati ẹkun kan si omiran, Bakare ni kii ṣe ọna to bojumu lati mu idagbasoke ba orilẹede Naijiria.''

Àkọlé fídíò, 2021 Twin Festival: Aráàlú ní Ifá ló sọ pé ìbejì yóò pọ̀ ní Igboora, kìí ṣe jíjẹ Ìlasa

Aṣiwaju ti yoo fun wa ni ijọba to ṣe e mu yangan lo yẹ ka wa:

''Ohun to yẹ ki a ma a wa ni ẹni to kunjuwọn ju, to ni ifẹ awọn araalu , to si fẹran orilẹede Naijiria.''

"To ba jẹ pe ẹya lo le mu ilọsiwaju ba orilẹede Naijiria, o yẹ ki ariwa orilẹede Naijiria to ti n ṣe ijọba ni apapọ fun ogoji ọdun ninu ọgọta ọdun ti Naijiria ti gba ominira.''

''Amọ niṣe ni ariwa orilẹede naa n jo ina ajorẹyin.''

''Ẹ tun wo aarẹ Obasanjo nigba to wa ni ipo to dena iṣuna fun ipinlẹ Eko to jẹ ẹkun ti oun tikalara rẹ ti wa''

''Bakan naa ki lo de ti Aarẹ Jonathan ko ri nkan ṣe si idagbasoke agbegbe ati ẹkun rẹ lasiko to wa ni ipo aarẹ?''

''Nitori naa ọrọ ẹya ko le e ṣe ijọba orilẹede Naijiria, ẹni to ba kunbjuwọn, to le mu wa de ilẹ ileri la nilo, lai wo apa ibi ti iru ẹni bẹẹ ti wa.''

''Amọ ti awọn oloṣelu ba ti jiroro ni aarin wọn lati yi ipo aarẹ si ọtun abi si osi, wọn gbọdọ tẹle ki otitọ ati ododo le jọba.''

Lori ọrọ atunto orilẹede Naijiria, Pasitọ Tunde Bakare ni ohun kan ṣoso to le e mu idagbasoke ba Naijiria niyẹn lasiko ti a wa yii, kii ṣe iyapa tabi ẹlẹyamẹya.

Àkọlé fídíò, Tunde Bakare: Àjọjẹ kò dún bẹ́nìkan kò ní ló fa ìjà S Igboho,bẹ́ẹ̀ ìjọbati gbẹ́rù kọjá orí

Bakan naa ni Pasitọ Bakarẹ lasiko to n fesi si ibeere pe ṣe yoo dije dupo aarẹ ni ọdun 2023, Bakare ni Ọlọrun ati awọn ọmọ Naijiria lo ku si ọwọ rẹ , ti wọn ba fẹ oun.

Bakare ni ilọsiwaju Naijiria lo jẹ oun logun lọwọ lọwọ bayii, ipo kipo ti oun ba si wa ni oun yoo ti ṣe iṣẹ ilu.

O ni asiko ti to lẹyin to ti di ipo adari ijọ mu fun ọdun mẹtalelọgbọn, ti awọn alatilẹyin rẹ si ti goke agba, asiko ti to lati ṣe iṣẹ ilu.