2023 Presidency: Tunde Bakare ní ẹ̀yà kan ko jùkan lọ láti dari Nàìjíríà

Alákòso ijọ Latter Rain Assembly, olusọaguntan Tunde Bakare ní kò sí ẹ̀yà kankan tó ni ẹtọ láti maa nìkàn dári orilẹ̀-èdè Nàìjíría.
Bakare láìpẹ yìí ti kédé pe oun yóò di ààrẹ lẹ́yìn ààrẹ Muhammadu Buhari lọdun 2023, sàlàye pé ó jẹ ǹkan to maa ń ru òun nínú nígbà ti àwọn ẹ̀yà kan kò ṣe fí fọkan tan ti wọ́n ba jáde.
O ní bó tilẹ̀ jẹ́ pé pinpin ipo aarẹ ní ẹlẹkun jẹkun kò si nínú akọsilẹ ofin orilẹ̀-èdè yìí, síbẹ̀ ó ti mú ki ìsọkàn wà ní Nàìjíríà.
Olùsọ àguntan Bakare sọ èyí lásìkò to n fọ̀rọjomitoro pẹ̀lú àwọn oníròyìn lẹ́yìn to pari ìwáàsu nilé ìjọsin rẹ.

Bakare ní; "àsìkò ti to láti jọ jumọ jòkó ps láti jíròrò, tóri èyí ni mo se sọ pé ó yẹ ki ènìyàn bi ààrẹ Muhammadu Buhari ní láti jígìrì kúrò lóri à ń fari apákan dá apákan si pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀yà mẹya."
O máa ń bí mi nínú tí mo ba ń gbọ pé àwọn ẹ̀yà kan ko ṣe fọ̀kàn tan àwọn ẹ̀yà kan láti gbé agbára ìjọba Nàìjíríà fún.
Bakare ní kí Nàìjíríà tó le tẹ̀síwájú, ó ṣe pàtàkì kí gbogbo ẹyà parapọ láti yan ẹni tó tọ, ki wọ́n yee funra si pé ẹyà kan lo le ṣe ìjọba tàbi ẹyà kan kọ́.








