Masten Wanjala: Mo máa ń díbọ́n bíi olùkọ́ni agbábọ́ọ́lù láti tan àwọn ọmọdé tí mò ń pa

Masten Wanjala

Oríṣun àwòrán, Directorate of Criminal Investigation, Kenya

Ọkunrin kan, Masten Wanjala, ẹni ogun ọdun, ti jẹwọ pe oun ti pa ọmọdekunrin marun laarin ọdun mẹwa.

Bakan naa lo tun jẹwọ pe se ni oun maa n fun awọn ọmọ naa ni oogun mu, ki oun to pa wọn, ti oun yoo si tun mu ẹjẹ wọn lẹyin ti oun ba pa wọn tan.

Wanjala lo jẹwọ bẹẹ fun ileesẹ ọlọpaa ilẹ Kenya, to si ni ọmọ ọdun mẹrindinlogun ni oun wa, nigba ti oun pa ọmọdekunrin akọkọ.

O ni se ni oun maa n dibọn bii akọnimọọgba fawọn agbaabọọlu ke ke ke, ti oun yoo si tan awọn ọmọde naa lọ sibi to dakẹ lati pa wọn.

Nigba miran, Wanjala ni oun maa n ji awọn ọmọ naa gbe lati gba owo lọwọ awọn obi wọn.

Àkọlé fídíò, 2021 Twin Festival: Aráàlú ní Ifá ló sọ pé ìbejì yóò pọ̀ ní Igboora, kìí ṣe jíjẹ Ìlasa

Ilu Nairobi si lo ti ni oun ti maa n pa awọn ọmọde naa ati lẹkun ila oorun ati iwọ oorun orilẹede Kenya.

Wanjala sa kuro ni ahamọ ọlọpaa lẹyin ti ọwọ tẹ:

Niwọn igba to jẹ pe asegbe kankan ko si, asepamọ lo wa, ọwọ awọn agbofinro papa tẹ afurasi apaayan yii, ti wọn si fi si ahamọ, ko le foju ba ile ẹjọ.

Amọ nigba to ya ni iroyin gbalẹ kan pe Wanjala ti sa kuro ni ahamọ, ti ẹnikẹni ko si mọ ibi to wa.

Awọn ọlọpaa mẹta to wa lẹnu isẹ lasiko ti afurasi naa di awati lọjọru to kọja si ni ijọba ti sọ si ahamọ lori ẹnu pe awọn lo se onigbọwọ bo se salọ.

Ileesẹ ọlọpaa ni awọn fura pe Wanjala ri aaye sa kuro ni ahamọ lasiko ti awọn n pe orukọ awọn afurasi to wa nibẹ ni.

Idi si ree ti awọn alasẹ se kede pe wọn n wa ọdọmọkunrin mujẹ mujẹ naa, ki awọn eeyan si fi iroyin nipa rẹ to awọn leti.

Ninu oniruuru ọrọ ti awọn araalu n kọ sori ayelujara, ni wọn ti n tutọ soke, fi oju gba pe ejo lọwọ ninu.

Àkọlé fídíò, Adejoke Ewaede: Ìfẹ́ àṣà Yorùbá ló mú kí ń pinnu láti máa wọ aṣọ àdìrẹ̀ nìkan

Ọwọ araalu tẹ afurasi apaayan pada, wọn si lu pa:

Ni kete ti Wanjala ti sa kuro ni ahamọ ọlọpaa ni ọkan awọn araalu ko ti balẹ mọ, ti wọn si n tọ ipasẹ rẹ kiri.

Wọn tọpasẹ rẹ de ile kan ni abule Bungoma, ti wọn si lu pa nibẹ.

Ẹnikan ti isẹlẹ naa soju rẹ sọ fun iwe iroyin kan nilẹ Kenya pe afurasi ọhun lo pada sile lọdọ awọn obi rẹ, ti wọn ni awọn ti kọ lọmọ tẹlẹ.

Ileesẹ ọlọpaa Kenya ni bi o tilẹ jẹ pe o lọ fi ara soko sinu ile kan amọ awọn araalu ka mọ ibẹ, ti wọn si yin ni ọrun pa sibẹ.

Gẹgẹ bi iwe iroyin Reuters ti wi, wọn ti n se iwadii lọwọ lati ri daju pe Wandala ni eeyan ti wọn lu pa, bi o tilẹ jẹ pe wọn ni awọn obi rẹ ti da oku naa mọ bii ọmọ wọn.

Àkọlé fídíò, "Akokoro eyín lè ṣe ìpalára fún àtọ̀ ọkùnrin, ó sì lè yọrí sí ṣàkóbá fún ọkàn èèyàn"

Iya awọn ọmọ ti Wanjala pa ni o wu oun lati ba ọmọ naa sọrọ ki wọn to lu pa:

Amọ sa, ọkan lara iya awọn ọmọde mẹwa ti afurasi naa pa sọ fun BBC pe oun wu oun lati ba Wanjala sọrọ, ki wọn to lu pa.

O ni ohun ti oun ko ba bi ni pe ki lo de to se hu iru iwa ika bii eyi.

"Ko ba wu mi ki n ri ko kawọ pọnyin ro ẹjọ ninu igi niwaju adajọ lati sọ ohun to ri lọbẹ, to fi wa iru sọwọ.

Grace Adhjambo salaye pe o yẹ ko le sọ idi to fi pa awọn ọmọ wa, to si fi wa sinu irora ayeraye."

Ọkan lara awọn ọmọ kekere ti Wanjala pa yii ni oku Brian Omondi to ti n jẹra, to si wa lara oku awọn oku mẹrin ti ọlọpaa ri ni ẹba ilu Nairobi losu Keje ọdun 2021.

Ayẹwo awọn onimọ isegun oyinbo fi han pe wọn fun awọn ọmọ naa lọrun pa ni, ti wọn si tun lu wọn ni nnkan lori.

Àkọlé fídíò, Ridwan Oyekola: October 30 ni màá tún ìjà jà láti gba belt mi padà àmọ́ kò sí onígbọ̀wọ́

Awọn araalu fọnmu pe Wanjala ko iku ni ifa lai foju wina igbẹjọ:

Ileesẹ to n se iwadii iwa ọdaran lorilẹede Kenya wa n fi ika hanu pe afurasi naa ko iku nifa lai koju idajọ.

Koda, awọn araalu ti n pe pe ki ọga ọlọpaa lorilẹede Kenya kọwe fipo silẹ nitori bi afurasi naa se kuro ni ahamọ ọlọpaa.

Bakan naa ni awọn eeayn n fi awọn ọlọpaa se ẹlẹya lori ayelujara, ti iku Wanjala si tun ran awọn araalu leti ẹhonu wọn sawọn agbofinro lorilẹede naa.