Endsars Protest: Àwa ò bẹ̀rù, a ó ṣèrántí ọdún kan tí ìjọba Naijiria f'ẹ̀mí ṣòfò lásíkò ìfẹ́hónúhàn Endsars - Soworo, Falz

Oríṣun àwòrán, Others
Ijọba ilẹ Gẹẹsi ti parọwa si awọn eniyan wọn lati ṣọra fun ipinlẹ Eko ati Abuja lasiko iranti ọdun kan ti ifẹhọnuhan Endsars ṣẹlẹ kaakiri orilẹede Naijiria.
Ilẹ Gẹẹsi fi iroyin naa si oju opo ikanni wọn ti wọn ti n fun awọn eniyan ni imọran agbegbe ti wọn le lọ lorilẹede Naijiria.
Loju opo naa ni wọn ti ni o ṣeeṣe ki iwọde waye kaakiri orilẹede Naijiria, ti ijọba naa yoo si da awọn ọlọpaa sita lati ri pe ifẹhọnuhan kankan ko waye ni awọn agbegbe kan.
- Ọ̀kan lẹ́ẹ fọwọ́ mú o, nínú ká jẹ gbèsè tàbí ká fi kún owó orí tẹ́ẹ̀ ń san - Fashola
- Ṣé MTN ló fi fídíò ọ̀fẹ́ ṣọwọ́ síi yín láti ọwọ́ MTNCEO KARL? Ohun tí a mọ̀ rèé…
- Ọwọ́ ti tẹ ọlọ́pàá mẹ́ta tó gba N25000 lọ́wọ́ aráàlú lójú pópó tí wọ́n tún fọ́ wọn létí
- Òkóbó ni mí àmọ́ ìyàwó mi gbà láti fẹ́ mi lẹ́yìn tí mo sọ fun un - Pásítọ̀ Olumide Oni
Bakan naa ni wọn fikun pe nitori igbẹjọ adari ikọ IPOB to wa ni panpẹ ijọba apapọ, o ṣeeṣe ki awọn eleto aabo pọ yanturu kaakiri Abuja ati ẹkun ila ọrun Naijiria.
Nitori naa wọn kilọ fun awọn eniyan wọn lati ṣọra fun awọn agbegbe wọnyii ati pe ki wọn ṣọra fun ipejọpọ kankan nibi ti ero ba pọsi.
A ó ṣèrántí ọdún kan tí ìjọba Naijiria fi ẹ̀mí àwọn ènìyàn ṣòfò lásíkò ìfẹ́hónúhàn Endsars - Omoyele Sowore
Amọ, lara awọn ọdọ ni Naijiria ti ni ko si ohunkohun to le e da wọn duro lati ma ṣewọde lasiko iranti awọn ti ẹmi wọn lọ si iṣẹlẹ ifẹhonuhan Endsars to ti pe ọdun kan.
Ogunjọ, Osu Kẹwaa, ọdun 2021 ni awọn ọdọ ṣe ifẹhọnuhan ni agbegbe Lekki tako ifiyajẹni ati iṣekupani awọn ọmọ Naijiria gba ọwọ awọn ọlọpaa ni Naijiria.

Oríṣun àwòrán, Others
Lara awọn to fi ero wọn han naa ni ajafẹtọ ọmọniyan, Omoyele Sowore to ti sọ wi pe ilu Abuja yoo gbalejo ifẹhonuhan ni ọjọ ayajọ ifẹhonuhan Endsars.
''Ilu Abuja ti ṣetan! gbagede Unity Fountan ni a o ti bẹrẹ ifẹhonuhan''
''A ko le gbagbe lailai, ti idunkoko kankan ko si le e da wa duro! pẹlu asia #RevolutionNow, #endsarsmemorial, #NoRetreatNoSurender.''
Content is not available
View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.End of Facebook post
A ko le dakẹ lailai! lailai! lailai! loni tabi ni Ogunjọ, Osu Kẹwaa, ọdọọdun - FALZ
Ninu ọrọ tirẹ, gbajugbaja olorin takasufe, Folarin Falana ti gbogbo eniyan mọ si Falz ti ni idunkoko ijọba ko le e da awọn duro nitori awọn ko le e gbagbe lai iṣẹlẹ ọdun to kọja (20:10:20).
Falz fẹsun kan ijọba apapọ pe wọn pa awọn ọdọ alaiṣẹ ti wọn n bere pe ki awọn ọlọpaa ye pa wọn.
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
''Amọ lẹyin ọdun kan, ko si ẹni kankan ti wọn ṣi fi iya jẹ lori iṣekupani to waye naa.''
''Ko tan si bẹ, kọmiṣọnna ọlọpaa ni ẹnikẹni ko gbọdọ ṣe ifẹhonuhan, ti awọn ọmọ Naijiria si ṣetan lati ṣe idanilẹkọ ni ọjọ naa lati ṣeranti awọn ti ẹmi wọn lọ si iṣẹlẹ naa.''
''Amọ gbagede ti wọn ti fẹ ṣe ayẹyẹ naa sọ wi pe wn ko le e lo agbegbe naa mọ nitori awọn alagbara pe wọn lati oke pe, ko gbọdọ waye.''

Oríṣun àwòrán, Others
Falz ni ijọba Naijiria kan n gbiyanju lasan ni nitori awọn ko ni gbagbẹ awọn ẹmi to ṣọnu lasiko ifẹhonuhan naa.














