Àwọn tó ń fi ẹsẹ̀ rìn láti Zimbabwe lọ sí South Africa sọ ìrírí wọn fún BBC

Oríṣun àwòrán, BBC/Ed Habershon
- Author, Jenny Hill
- Role, BBC News, Musina
Ọpọ awọn arinrinajo ni wọn n fi ẹmi ara wọ wewu lati wọ orilẹede South Afrika lati oju ọna Zimbabwe. Amọ nibayii ti eto idibo South Africa ti sunmọle, awọn araalu to korira awọn ọmọ ilẹ okeere n fẹ ki ijọba ti ẹnobode ti awọn eeyan naa n gba wọle pa..
Lara awọn ewu ti awọn arinrinajo naa n koju ni ifipabanilopọ.
Awọn to ba Portie Murevesi lopọ ko tilẹ wo boya o loyun ati pe oyun naa ti ga.
O sọ fun BBC pe yatọ si pe wọn fi agidi ṣi aṣọ oun wo, wọn tun fọ igo mọ oun niwaju ori.

Oríṣun àwòrán, BBC/Ed Habershon
Murevesi ti gba itọju bayii niluu Musina ninu ile ti ile ijọsin kan kọ si ala South Africa.
O ni “Nigba mii ti mo ba fẹ sun, mo maa n ri ohun ti awọn ọkunrin naa ṣe si mi.
Musina jẹ ibi kan pataki ti awọn aṣatipo maa n fori pamọ si ti wọn ba fẹ wọn South Africa.
Awọn arinrinajo naa ṣalaye pe lilu nilu bara, ifipanilopọ, iṣekupani, ijanilole atawọn iṣoro mii lawọn maa n koju loju ọna ọhun.
Ọkunrin ọmọ orilẹede Zimbabwe kan to pe orukọ ara rẹ ni George ṣalaye fun wa pe “ewu nla lo wa loju ọna naa.”
“A maa n ri eegun eeyan, bẹẹ la maa n ri awọn mii ti wọn ṣẹṣẹ pa ni nnkan bii oṣu meji si mẹta sẹyin.”
Ẹlomiran to tun jẹ arinrinajo ni “A ko le pada si Zaimbabwe mọ nitori ko si nnkankan fun wa nibẹ.
“Iyan n mu wa, ebi n pa wa, ko si ounjẹ fun ni Zimbabwe.”
Ko si ẹni to tii le sọ iye aṣatipo to wa ni South Africa, ṣugbọn eto ikaniyan kan fi han pe nnkan bii miliọnu meji abọ awọn ọmọ ilẹ okeere lo n gbe ni South Africa, eyi to jẹ ida mẹta gbogbo eeyan to n gbe nibẹ.
Ko si akọsilẹ iye eeyan to wọ orilẹede naa lai gba ọna to ba ofin mu.
Ni bayii ti idibo sunmọle ni oṣu Karun un, ọrọ awọn to n wọ ilu lai ba ofin mu ti di ọrọ oṣelu.
Ijọba South Africa ti ni oun yoo bojuto awọn ọna ti awọn eeyan n gba wọle.

Oríṣun àwòrán, BBC/Ed Habershon
Awọn arinrinjo naa sọ pe ko ju irin ẹsẹ iṣeju marun un pere lati rin lati abule kan ni Zimbabwe si South Africa.
Ko si si ogiri kankan to n dena awọn eeyan naa lati wọle lati Zimbabwe si South Africa.
Arinrinajo miran sọ fun BBC pe ọlọpaa maa n ko awọn lẹẹkọọkan amọ ọpọ igba ni wọn maa n wọle.

Oríṣun àwòrán, AFP
Nibayii, ijọba South Africa ti ṣetan lati gba iṣakoso ẹnubode rẹ.
Lọdun to kọja, Aarẹ Cyril Ramaphosa kede ofin tuntun lati daabo bo ẹnubode naa.
Kọmiṣọna to n ri si ọrọ ẹnubode, Mike Masiapato ni awọn yoo ran irinwo aṣobode sibẹ lati daabo ẹnubode ọhun.
Ṣugbọn o ni yoo gba awọn ni akoko diẹ lati daabo bo ẹnubode naa patapata.
Lori awọn ọmọ ilẹ okeere to n wọle lai gba iwe irinna, Aarẹ Ramaphosa sọ pe wọn n ṣakoba fun ọrọ aje orilẹede ọhun.














