Zakat-ul-Fitr: Ìtọrẹ àánú tó ń fọ àléébù ara ààwẹ̀ mọ́

Aworan Sheikh Haliru Maraya ati ọwọ to n wọn irẹsi

Òpó kẹta ninu ẹsin Islam ni Zakat ti a mọ si saka yiyọ ninu ọlá ẹni.

Ṣugbọn itọrẹ aanu kan wa to maa n waye bi aawẹ Ramadan ba ti fẹẹ pari, eyi ti a mọ si Zakat-ul-Fitri.

Zakat-ul-Fitri yii ni awọn mi-in n pe ni Jákà yiyọ nilẹẹ Yoruba.

Inu oṣu Ramadan lo ti maa n waye.

Iṣẹ rẹ ni lati fọ awọn aṣiṣe ati aleebu to le wa ninu aawẹ ta a gba loṣu Ramadan mọ.

Awọn aṣiṣe naa ko ba aawẹ jẹ tan pata, ṣugbọn o maa n din laada aawẹ ku ni.

Yatọ si pe Zakat-ul-Fitri n fọ aawẹ mọ, iṣẹ rẹ keji ni lati pese ounjẹ ati iranlọwọ fawọn alaini.

Yoo si tun mu idunnu wa fun ẹni to fun eeyan atẹni ta a ṣe itọrẹ aanu fun.

Sheikh Haliru Maraya lati ipinlẹ Kaduna, ṣalaye fun BBC nipa Zakat-ul-Fitri.

Àsìkò wo la n yọ Zakat-ul-Fitri?

Sheikh Maraya ṣalaye pe awọn onimọ kan ninu Islam (Shafii) gbagbọ pe eeyan le ṣe itọrẹ aanu yii lọjọ akọkọ Ramadan.

Nigba ti awọn abala Malikiya ati Hambaliya, gbagbọ pe bi aawẹ ba ti n ku ọjọ meji ti yoo pari leeyan le ṣe e titi di aarọ ọjọ ọdun Itunu-aawẹ.

Ki wọn too kirun ni yidi leeyan ti gbọdọ lọọ ṣe itọrẹ aanu naa to ba jẹ pe ọjọ ọdun lo fẹẹ ṣe e.

‘’Itọrẹ aanu teeyan ba ṣe lẹyin ti wọn ti kirun ọdun tan ki i ṣe Zakat-ul-Fitri mọ, o ti di ọọrẹ lasan.

’’ Wọn maa n jẹ ki irun kiki ni yidi Itunu-aawẹ pẹ, kawọn eeyan le sare yọ saka naa bi wọn ko ba ti i tọrẹ ọhun titi di aarọ ọjọ ọdun.

Ẹni ti ko ba yọ tiẹ ti wọn fi kirun tan ko yọ Zakat-ul-Fitri.

Kí lohun tí wọ́n fi ń yọ Zakat-ul-Fitri?

Sheikh Halliru Maraya, sọ pe oriṣiiriṣii ounjẹ ti wọn ba n jẹ lagbegbe tabi ilu kan ni wọn fi n ṣe itọrẹ aanu yii.

Paapaa julọ, ounjẹ to ba gbajumọ ju nibẹ.

‘’Ohun to daa ju ni lati yọ Zakat-ul-Fitri pẹlu ounjẹ teeyan naa ba n jẹ, ṣugbọn dandan kọ ni ko jẹ ounjẹ, eeyan le fi owo naa ṣe e.

To ba jẹ ounjẹ bii irẹsi, ẹwa, gaari,agbado leeyan fẹẹ lo, oṣuwọn ta a n pe ni ‘Mudu’ ni wọn fi n wọn ọn.

Mudu mẹrin fun ẹnikan si ni.

‘’To ba jẹ owo leeyan fẹẹ lo, iye owo mudu mẹrin fẹnikan leeyan yoo fi tọrẹ.

‘’Ẹni to ba din owo naa ku ko ṣe Zakat-ul-Fitri, itọrẹ aanu lasan lo ṣe.

Awọn wo ni Zakat-ul-Fitri jẹ dandan fun?

Sheikh Maraya sọ pe ẹni to ba jẹ Musulumi, ọmọ ni tabi ẹrú, ọkunrin abi obinrin, ọmọde abi agbalagba, dandan ni fun wọn lati ṣe itọrẹ aanu ipari Ramadan yii.

‘’Bi ẹnikan ba jẹ ọlọrọ, yoo ṣe itọrẹ-aanu yii funra rẹ ati fawọn eeyan to wa labẹ rẹ, iyẹn awọn to n bọ́.

‘’Fun awọn ọmọ orukan ti ko ni obi mọ, wọn le mu ninu ohun ti wọn ba ni, ki wọn ṣe e funra wọn.

‘’Awọn obi ni yoo ṣe Zakat-ul-Fitri fawọn ọmọ wọn obinrin ti ko ti i lọ sile ọkọ, koda bi wọn ba ti dagba.’’

Nipa oore ti itọrẹ aanu yii yoo ṣe, Maraya sọ pe yatọ si pe o ṣe afọmọ ẹṣẹ fun alaawẹ to yọ Zakat-ul-Fitri, yoo tun jẹ idunnu fawọn alaini ti wọn ṣe e fun.

Awọn naa yoo le ṣe ọdun ayọ lẹyin aawẹ ti wọn gba.

Kaluku yoo si le ṣe Alhamdulilah s’Oluwa Allah.