Ṣé Russia ń tan àwọn àjèjì lọ jagun ní Ukraine ni ?

Aworan awon ologun

Lati oṣu keji ọdun 2022 ti ogun ti bẹ silẹ laarin orilẹ-ede Russia ati Ukraine titi dasiko yii ni nnkan ko ti i fararọ.

Ko si seeyan ti yoo finu-fẹdọ di ẹru rẹ ti yoo ni oju ogun loun fẹẹ mule si.

Ọkunrin kan, Mohammed Asfan, fi iyawo ati awọn ọmọ rẹ meji silẹ si Guusu India lọ si orilẹ-ede Russia lati ṣiṣẹ oluranlọwọ fawọn ṣọja to n jagun ni Ukraine.

Ṣugbọn nigba to ya, awọn ologun sọ pe o ti ku.

Ogun jija kọ ni Asfan ba lọ si Russia, ipolowo to ri lori ẹka ayelujara YouTube, ṣalaye pe yoo kan maa jẹ oluranlọwọ fawọn ologun ni olu ileeṣẹ wọn ni.

Owo nla ti i ṣe 100,000 Rupees,(dọla 1,207) ni wọn ṣeleri lati san fun un loṣu.

Wọn ni Lẹyin oṣu mẹfa, yoo si tun le maa gbe Russia lọ titi lae bii ọmọ oniluu.

Ṣugbọn alọ rẹ ni iyawo, baba, awọn ọmọ rẹ meji pẹlu ẹgbọn rẹ ri titi dasiko yii, wọn ko ri Asfan Mohammed ko pada wale.

Bakan naa ni wọn ko ri i ba sọrọ lori foonu.

Kí ló ṣẹlẹ kó tóó di pé wọn ò rí Afsan mọ?

Ẹgbọn Afsan, Imran to ba BBC Punjab sọrọ,ṣalaye pe o pe oun lori foonu lọjọ kan lẹnuubode Ukraine, o ni awọn ologun ti gba iwe irinna oun, wọn si ti n jẹ koun lọọ maa koju ogun.

Eyi si yatọ si adehun to gbe e de Russia.

Ẹgbọn rẹ sọ pe oun ko gburoo rẹ latigba naa mọ titi toṣu meji fi kọja.

‘’Mo pe ileeṣẹ to n ri si irinajo lati India lọ si Russia lati beere aburo mi, wọn ni o ti ku.

To ba ti ku, ki wọn gbe oku rẹ wa sibi lẹsẹkẹsẹ. Baba mi ati iyawo rẹ wa ninu idaamu gidi nitori Asfan ti ko pada wale.’’

Bẹẹ ni Imran fi ẹdun ọkan sọrọ.

Ṣọọbu kan ni Asfan ti n ba wọn mojuto aṣọ tita ko too ri ipolowo to gbiyanju rẹ wo yii.

Awọn ọmọ meji to fi silẹ funyawo rẹ ko ti i pe ọmọ ọdun meji rara.

Iwadii ikọ iroyin BBC fi han pe o kere tan, meji ninu awọn ọkunrin India ti wọn lọ si Russia lati gbaṣẹ oluranlọwọ ologun yii ni wọn ti ku nibi ti wọn ti n jagun.

Iwaju ogun gan-an ni wọn tilẹ n fi wọn si bawọn ẹbi wọn ṣe ṣalaye laipẹ yii.

Aworan Iyawo Asfan pẹlu ọmọ rẹ to mu fọto ọkunrin naa dani

Ibi iṣẹ ọnà aṣọ ni Hemil gbà di ṣọja tó ń kọṣẹ ogun jíjà

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Iwadii fi han pe iru ipolowo to fa Asfan loju mọra to fi lọ si Russia naa ni ọmọkunrin kan, Hemil Mangukiya, ri to fi kuro nidii iṣẹ ọna aṣọ loṣu kejila ọdun 2023.

Ẹni ọdun mẹtalelogun (23) ni Hemil, India lo n gbe, iṣẹ awọn to n koṣẹ si aṣọ (embroidery) lo si n ṣe tẹlẹ.

Ṣugbọn nigba to ri ipolowo ti Russia ṣe lori oluranlọwọ ologun ti wọn n wa, o fiṣẹ ọna silẹ, o si gba Russia lọ.

Baba rẹ, Ashwin, ṣalaye pe oṣu mẹta ni wọn ni wọn yoo fi kọ ọ niṣẹ oluranlọwọ ologun.

O ni ṣugbọn nigba to debẹ lo di pe bi yoo ṣe maa jagun ni wọn n kọ ọ.

‘Ẹka ayelujara ti wọn fi n tan awọn ọdọkunrin lọ si Ukraine’

Laipẹ yii ni orilẹ-ede India kede pe oun ṣawari oju opo ayelujara kan ti wọn fi n tan awọn ọdọ lọ si Russia, ti wọn n fipa mu wọn jagun.

Wọn ni iṣẹ to lowo gọbọi lori ni wọn fi n tan awọn ọdọ loju opo ọhun, ti wọn ba debẹ tan lo n di oju ogun lilọ.

Gẹgẹ bi ẹka to n ri si iwadii, (Central Bureau of Investigation) ṣe sọ, o kere tan, gende marundinlogoji (35) ni wọn ti fi ẹtan yii gbe de Russia.

Ileeṣẹ naa sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ lori awọn ọmọ India ti wọn n f’ẹtan ko lọ soju ogun yii. Wọn ni Moscow niṣẹ ti n lọ.

Bakan naa ni awọn fidio to n ṣafihan awọn to lugbadi ogun lilọ abaadi naa ti n ja ran-in lori ayelujara.

Ninu fidio kan to jade loṣu yii, awọn ọkunrin ọmọ India meje kan n bẹ ijọba india pe ki wọn dakun waa mu awọn pada sile.

Wọn ni fisa arinrinajo afẹ lawọn fi de Russia, ṣugbọn ni bayii, wọn ti fipa sọ awọn di ọmọ ogun wọn .

Ọkan ninu awọn eeyan to n bẹbẹ naa ni Gagandeep Singh.

‘’Wọn ni k’ọmọ mi maa jagun lọ ni Russia jẹjẹ abi ko lọ si ẹwọn ọdun mẹwaa’’

Aworan awon arinrinajo ti won o lo si enuubode Ukraine

Gẹgẹ bi iya rẹ,Balwinder Kaur, ṣe ṣalaye fun BBC Punjab, o ni awọn ologun Russia paṣẹ fọmọ oun lati maa jagun lọ jẹjẹ, abi ko lọ ṣẹwọn fọdun mẹwaa gbako bi ko ba fẹẹ jagun.

" A maa n duro dọwọ alẹ lati gba ipe rẹ lorii foonu ni.

‘’O sọ fun wa pe wọn ti ran awọn lọ sogun ni Ukraine. Gbogbo wa lọkan wa gbọgbẹ.’’

‘ Kò dín ní àjèjì 254 tó ti bá ogun lọ’

Iwoye Akọwe apapọ Nato, Jens Stoltenberg, ṣafihan pe eeyan 350,000 lo ti ni ijamba ni Russia latari ogun ti wọn n ba Ukraine ja.

Ko wulẹ sọ iye eeyan to ti di alaabọ ara atawọn to ti doloogbe.

Ẹka iroyin BBC Russia fi iwadii tiẹ han, pe ṣọja 46,678 lo ti ba ogun yii lọ.

Eyi lo fa a ti Russia fi n kọju sawọn ajeji, ti wọn n sọ wọn di ọmọ ogun.

Ni 2022, Russia fun awọn ajeji ti wọn ṣadehun ati jagun fun wọn fun ọdun kan lafaani lati gba iwe igbeluu.

Koda, wọn ṣe bẹẹ fawọn ti wọn ko ti i jagun ju oṣu mẹfa lọ.

Wọn gboju kuro nibi ofin to ni eeyan gbọdọ niwee igbelu, abi kẹni naa ti maa gbe Russia fọdun marun-un gbako ko too le jẹ anfaani yii.

Loṣu kin-in-ni, Aarẹ Putin tun gbe ofin mi-in to mu kinni naa dẹrun ju ti tẹlẹ lọ jade.

Pupọ awọn ajeji to n jagun fun Russia jẹ arinrinajo lati Aarin gbungbun Asia, awọn bii Uzbekistan,Tajikistan ati Kyrgyzstan.

Awọn mi-in wa lati Cuba, Nepal, India, Syria, Iraq, Serbia, Afghanistan, Somalia, Sri Lanka ati Malaysia.

Ẹgbẹẹgbẹrun ni wọn pe wọn.

Awọn arinrinajo ti iwe irinna wọn ti lejọ naa ti ba ara wọn lẹnuu ibode Ukraine togun ti n waye.

Bakan naa ni iwadii BBC Russia fi han pe ewu n bẹ loko Longẹ fawọn arinrinajo to wọ Russia lai ni iwe gidi, nitori bọwọ ba tẹ wọn, o le ja soju ogun.

Ẹka iroyin BBC kan si ileeṣẹ ọrọ abele ni Russia lati gbọ tẹnu wọn lori awọn ẹsun fifipa fun ajeji niṣẹ ologun yii, ṣugbọn wọn ko fesi kankan.