Àlàyé rèé lórí àìsàn tó ń ṣe òṣèré tíátà Zack Orji, tó mú kí ayé máa lọgun ikú rẹ̀

Oríṣun àwòrán, Zack Orji @Facebook
Lẹnu ọjọ mẹta yii ni awuyewuye gba ori ayelujara kan, pe gbajumọ onitiata ọmọ Igbo nni, Zack Orji, ti jade laye.
Eyi ri bẹẹ latari iṣẹ abẹ kan ti wọn kede pe ọkunrin naa nilo lati ṣe kia, nitori ara rẹ ti ko le lẹnu lọọlọ yii.
Nigba to n tan imọlẹ si ọrọ yii, Aarẹ ‘Actors Guild of Nigeria (AGN), Emeka Rollas, sọ pe irọ gbuu ni pe Zack Orji ti ku.
Aarẹ AGN naa sọ pe ofege niroyin to kede iku gbajumọ oṣere ọmọ Igbo naa.
‘’Ẹ waa tẹti gbọ awa ti a ko ni i purọ fun yin, Zack Orji ṣi wa laye daadaa.
‘’A mọ pe ero awọn kan niyẹn, ṣugbọn Zack yoo ye, yoo si pada sẹnu iṣẹ.’’ Rollas lo sọ bẹẹ.
Nígbà wo ni àìsàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe Zack Orji?

Oríṣun àwòrán, Zack Orji @Instagram
Mínísítà fọ́rọ̀ Aṣa bèèrè ìrànwọ́ owó fún Zack Orji, kí ìtọ́jú rẹ̀ le yá kíákíá.
Arẹwa ọkunrin to duro deede to si mọ iṣẹ rẹ niṣẹ ni Zack Orji ko too di pe aisan bẹrẹ si i ṣe e.
Lọjọ Kọkandinlọgbọn, oṣu kẹsan-an ọdun 2023, oṣere tiata to maa n ṣere oloyinbo naa, di ẹni ti wọn gbe digba-digba lọ sileewosan kan l’Abuja.
Hannatu Musawa, Minista fun Aṣa ni Naijiria, beere iranlọwọ awọn eeyan fun Orji nigba naa, ki itọju rẹ le ya kiakia.
Latigba naa lo ti n gba itọju nileewosan, ko too di pe iroyin jade laipẹ yii pe o ti jade laye.
Emeka Rollas koro oju sawọn ẹka iroyin to n gbe iku Zack Orji lai ti i ku, o ni kẹnikẹni ma ṣe gba wọn gbọ rara.
Àlàyé díẹ nípa iru eeyan ti Zack Orji jẹ́

Oríṣun àwòrán, Zack Orji @Instagram
Gẹgẹ bi oṣere yii ṣe sọ fun BBC lasiko kan ti wọn fọrọ wa a lẹnu wo, o loun ki i gbe igbesi aye oun sori ayelujara.
Zack Orji sọ pe oju opo agbaye ki i ṣe ibi toun maa n sọ bo ṣe n lọ laye oun si.
Ọmọ Igbo ni Zack Orji, ṣugbọn orilẹ-ede Gabon ni wọn bi i si.
Ọmọ bibi Ngwoo, nijọba ibilẹ Udi, nipinlẹ Enugu ni.
Yunifasiti Naijiria, ni Nsukka lo ti kawe gboye.
Zack Orji ti figba kan ṣiṣẹ niluu oyinbo, South Africa atawọn orilẹ-ede mi-in ko too dara pọ mọ ẹgbẹ oṣere ni Naijiria.
Zack le sọ ede Igbo, Faranse ati ede oyinbo daadaa.














