"Ọmọ mi kò húkọ́ rárá àmọ́ ó ń bì, ó ń rù, kò sì jẹun, àyẹ̀wò ló fihàn pé ó ní àrùn ikọ́ ife"

Àkọlé fídíò, Tuberculosis: Obìnrin kan tí ọmọ rẹ̀ ní àrùn ikọ́ ife sọ ìrírí àti bó ṣe borí àìsàn náà

Bi ẹnikan ba ni ikọ-ife ti ko si jade lati sọ ọ tabi gba itọju, o le pa ẹni naa tabi ko ba ẹya ara ti ikọ naa ti kan jẹ.

Obinrin kan , Mariam Quazim ti salaye bi ọmọ rẹ, Anif Qwuasim se la iriri ikọ ife kọja.

Lasiko to n ba BBC sọrọ, Mariam ni ọmọ oun ko hukọ rara, eyi to le mu ki awọn fura pe o ni arun ikọ ife.

“Amọ se lo n ru, ti ko si le jẹun daadaa, to si maa n bi.

Anif maa n jẹun tẹlẹ, amọ ko le jẹun daadaa mọ, idi ree ti mo se gbe wa sile iwosan.

Wọn se X-ray fun, ti iwadi si fihan pe arun ikọ ife lo n ba finra.”

Mariam wa fi tayọtay kede pe lẹyin ti wọn kọ oogun fun ọmọ oun, to si lo oogun naa daradara, ara rẹ ti ya pada.

“Ọsẹ meji lo fi lo oogun ti wọn kọ fun, ti ara rẹ fi bẹrẹ si ni ya pada.

Mo si n rọ awọn abiyamọ bii temi pe ti nnkan ba n se ọmọ wọn, se ni ki wọn tete gbe lọ sile iwosan.

Ọfẹ ni itọju ikọ ife, ẹ mase jẹ ka bo awọn ọmọ wa mọle.”

Obinrin ti ọmọ rẹ ni arun ikọ ise

Lara aisan to n pa eeyan julọ ni agbaye ni ikọ ife jẹ, o maa n ba ẹdọ ja ni – Dokita

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Bakan naa, dokita onisegun oyinbo to mọ nipa arun ikọ ife naa ba BBC Yoruba sọrọ, to si sọ nipa apẹrẹ bi a se le da arun ikọ ife mọ lara alaisan to ba ni.

Dokita Fadeyi Olatunbosun salaye pe arun ikọ ife maa n ba ẹdọ ta fi n mi ja ni.

“Ikọ maa n se akoba fun gbogbo ẹya ara, o maa n mu ko rẹ eeyan, ti alaisan naa ba ti n rin, yoo maa mi gulegule.

Bi kokoro aile foju ri to n fa aisan ikọ ife ba ti wọnu agọ ara kan, onitọhun yoo maa hukọ ẹjẹ.

Eyi la fi n mọ pe kokoro yii ti wọnu ara.”

Bakan naa ni Dokita Fadeyi ni ko si ẹni ti arun ikọ ife ko le mu, boya ọmọde ni tabi agbalagba.

Nigba to n salaye bi arun ikọ ife se maa n ran kaakiri ara ẹda, dokita naa ni ti ẹnikan to ni arun ikọ ife ba ti hukọ si afẹfẹ, ẹni to ba mi afẹfẹ naa simu, yoo ko arun ọhun ni.

“Bi alaisan ikọ ife ba hukọ sinu atẹgun, kọ orin tabi sọrọ, eyi yoo wọnu atẹgun lọ.

Ẹni to ba si mi iru atẹgun yii yoo ni ikọ ife ni.”

Dokita Fadeyi tun mẹnuba awọn ọna ta fi le se itọju arun asekupani naa.

Dokita Fadeyi Olatunbosun

Ọfẹ ni ijọba apapọ atijọba Ogun n se itọju arun ikọ ife – Kọmisana feto ilera ni Ogun

Kọmisana feto ilera nipinlẹ Ogun, Dokita Oluwatomi Coker, naa ba BBC Yoruba sọrọ ni ayajọ idena ikọ ife to maa n waye ni ọjọ kẹrinlelogun osu kẹta ọdọọdun.

Dokita Coker ni ẹnikẹni to ba ni ikọ ife, to n lọ si osu kan si osu mẹta, gbọdọ kan si dokita fun itọju.

“A n rọ awọn eeyan to ba ni arun ikọ ife lati jade wa sile iwosan fun itọju.

Awọn eeyan to ba n hu ikọ lati osu kan si osu mẹta, ti wọn n ru, to n rẹ wọn, aisan yii ti le de agọ ara wọn.

Ijọba apapọ ati ipinlẹ Ogun si maa n fun awọn araalu ni abẹrẹ ajẹsara lati dena aisan naa.

A tun maa n fun awọn alaisan yii ni oogun fun iwosan wọn.

Dokita Oluwatomi Coker
Àkọlé fídíò, Ta ni ojúlówó ọba ìlú Igboho láàrin Alepata, Onigboho ati Ona Onibode

Mo ní àìsàn ikọ́-ife f’ọ́dún mẹ́rìnlá láì mọ̀ - Janet Iyiola

Abileko Janet Iyiola

Gbogbo ọjọ kẹrinlelogun, oṣu Kẹta ọdun ni ayajọ ikọ-ife kari aye.

Ọjọ naa ni wọn ya sọtọ lati jẹ itaniji ati ilanilọye fawọn eeyan lati mọ nipa arun ti oyinbo n pe ni Tuberculosis, ti Yoruba n pe ni Ikọ́-ife.

Bi Ikọ́-ife ṣe jẹ arun to le gba ẹmi eeyan to, o ṣee ṣe ki eeyan ni i ko si ma mọ.

Gẹgẹ bo ṣe ṣe obinrin kan, Abilekọ Janet Iyiọla, fun ọdun mẹrinla gbako.

Obinrin naa padanu ẹsẹ rẹ latari ikọ-ife to n yọ ọ lẹnu lai mọ.

Ti mo ba n rin, ara aa maa ro mi, mi o le da iṣẹ ile kankan ṣe, mi o le lọ sọja lọọ ra nnkan wale - Arabinrin Iyiola

‘’Oju mi ri to. Ti mo ba n rin, ara aa maa ro mi. Mi o le da iṣẹ ile kankan ṣe. Mi o le lọ sọja lọọ ra nnkan wale.

‘’Ti mo ba ṣe igbọnsẹ, ọkọ mi lo maa ṣẹṣẹ ba mi gbe e danu to ba de lati ibi iṣẹ.

‘’A tiẹ n ro pe iba jẹdọ-jẹdọ ni.Gbogbo ìgbaròkó lo maa n ro mi, ati ẹsẹ mi naa.

‘’Mi o le rin, awọn ọmọ mi lo maa n mu mi dani ti mi o ba jokoo sori aga ‘wheel chair’

‘’Aimoye ibi ti mo lọ ki n le bọ ninu iṣoro yii. Obinrin pasitọ kan waa tọju mi, awọn ewe to ti ra lo ko somi to ni ki n maa fi wẹ.

‘’Bẹẹ ni mo ṣe fi wẹ fọjọ mẹta ki n too pa a ti.

’Bi mo ṣe pada mọ pe Ikọ-ife ni’

‘’Lọjọ kan ti mo n gbọ redio ni mo gbọ ti wọn sọ pe Ikọ-ife le ma jẹ ki eeyan le rin.

‘’Mo lọ sileewosan naa, wọn ṣe ayẹwo fun mi, wọn si ri i pe Ikọ-ife inu egungun ẹyin (T.B of the spine) lo fa iṣoro fun mi’’

Ọgbẹni Samuel Iyiọla to jẹ ọkọ Janet, ṣalaye pe nigba ti ayẹwo ti sọ ohun to n ṣẹlẹ loun ti bẹrẹ si i mojuto itọju iyawo oun.

Baba naa sọ pe oun ri i daju pe Janet ko pa ọjọ itọju rẹ jẹ titi ti alaafia fi de.

Oun si maa n lọọ gba oogun fun un.

Ki lohun ti awọn dokita sọ nipa Ikọ́-ife?

Ọ́Onimọ nipa ilera, Ajayi Oluyinka, lati ilu Ibadan, ṣalaye pe o yẹ kawọn eeyan maa ṣayẹwo nipa Ikọ-ife.

O ni aisan to n paayan ni ikọ yii, bẹẹ lo si le ba awọn ẹya ara to ba kan jẹ pẹlu.

‘ Ẹ jẹ kawọn ọrẹ yin lọọ fun ayẹwo ati itọju, paapaa awọn ti wọn ba ti ṣayẹwo ti wọn si ti fidi ẹ mulẹ pe wọn ni Ikọ-ife.

‘’Bi ẹnikan ba ni ikọ-ife ti ko si jade lati sọ ọ tabi gba itọju, o le pa ẹni naa tabi ko ba ẹya ara ti ikọ naa ti kan jẹ.

O fi kun un pe Abilekọ Janet Iyiọla ti n rin pada bayii, ko jokoo sinu aga mọ nitori itọju to gba lẹyin ayẹwo.