Mo gbà pé mo jẹ̀bi ẹ̀sùn tí EFCC fi kàn mí - Bobrisky

Oríṣun àwòrán, EFCC
Idris Okuneye, ti ọpọ mọ si Bobrisky ti sọ nile ẹjọ pe oun jẹbi ẹsun ti ajọ EFCC fi kan oun.
Ṣaaju ni EFCC ti kọkọ fẹsun kan ọkunrin to n ṣe bii obirin naa lẹyin to tabuku owo naira, eyii to mu ko dero ile ẹjọ.
Nigba ti wọn ka ẹsun rẹ fun nile ẹjọ, Bobrisky sọ niwaju adajọ pe oun jẹbi ẹsun mẹrin to rọ mọ titabuku owo naira.
Adajọ Abimbola Awogboro da ẹjọ meji lara ẹsun ti wọn fi kan ọkunrin naa nu, eyii to rọ mọ kiko owo pamọm lọna aitọ lẹyin ti agbẹjọro EFCC, Suleiman Suleiman ni ko ṣe bẹẹ.
Nigba ti wọn ka awọn ẹsun naa fun Idris, ti wọn si bere lọwọ rẹ boya o ni oye ẹsun ti wọn fi kan an, o fesi pe “bẹẹni, mo jẹbi.”
Aago mẹsan an aarọ kọja iṣẹju diẹ ni EFCC gbe Bobrisky wọle ẹjọ lati wa sọ tẹnu rẹ lori awọn ẹsun naa.
Ọjọru ọsẹ yii ni EFCC mu lori ẹsun titabuku owo naira ati kiko owo pamọ lọna aitọ.
Kí ló dé tí Bobrisky kò le sọ ohun tí iléeṣẹ́ rẹ̀, Bob Express, wà fún àti ẹ̀sùn N180m tí wọn fi kàn-án? - EFCC

Oríṣun àwòrán, @EFCC/BOBRISKY
Àjọ tó ń gbógúnti ìwà àjẹbánu ní orílẹ̀ èdè Nàìjíríà ti ní bí àwọn ṣe nawọ́ gán gbajúmọ̀ akọ tó ń máa ń múra bíi obìnrin, Idris Olanrewaju Okuneye, tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí Bobrisky, kìí ṣe láti dúnkokò mọ.
Ní ọjọ́bọ̀, ọjọ́ Kẹrin, oṣù Kẹrin ọdún 2024 ni ìròyìn gba orí ayélujára pé Bobrisky ti wà ní àhámọ́ àjọ EFCC.
Nígbà tí BBC News Yorùbá kàn sí agbẹnusọ àjọ EFCC, Dele Oyewale, ó ṣàlàyé pé ẹ̀sùn ṣíṣe owó náírà lọ́nà tó lòdì sí òfin ni àwọn fi ránṣẹ́ pé Bobrisky láti wá wí tẹnu rẹ̀.
Oyewale ṣàlàyé pé Bobrisky ló yọjú sí ẹ̀ka ilé iṣẹ́ àwọn tó wà ní ìlú Eko, tí àwọn sì fi í àhámọ́ fáwọn ẹ̀sùn náà.
EFCC fi sórí ẹ̀rọ ayélujára X wọ́n pé àwọn fi kélé òfin gbé Bobrisky lórí àwọn ẹ̀sùn kan àti pé lọ́jọ́ Ẹtì ni yóò fojú ba ilé ẹjọ́.
Lẹ́yìn tí ìròyìn yìí gbòde ni àwọn ènìyàn lórí ayélujára bẹ̀rẹ̀ sí ní fẹ̀sùn kan EFCC pé ṣe ní wọ́n mọ̀-ọ́n-mọ̀ fẹ́ dúnkokò mọ́ Bobrisky ni.
Àmọ́ agbẹnusọ EFCC, Dele Oyewale nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ètò iléeṣẹ́ ìròyìn TVC lálẹ́ ọjọ́rú ní irọ́ tó jìnà sí òótọ́ ni nǹkan táwọn ènìyàn ń sọ kiri ọ̀hún.
Ẹ̀sùn mẹ́fà ni EFCC kà sí Bobrisky lọ́rùn.
Oyewale ní ẹ̀sùn mẹ́rin lára àwọn ẹ̀sùn mẹ́fà náà ló dá lórí ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́ àtàwọn ẹ̀sùn míì.
Ó ṣàlàyé pé méjì yòókù ló dá lórí ọ̀rọ̀ àìlè kéde ohun tí iléeṣẹ́ Bobrisky, Bob Express dá lórí èyí tó kojú ẹ̀sùn lórí owó tó lé ní ọgọ́sàn-án mílíọ̀nù náírà.
Wọ́n ní àwọn ẹ̀sùn mẹ́rin lórí ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́ lòdì sí òfin kìíní ti ilé ìfowópamọ́ àpapọ̀ Nàìjíríà tọdún 2007 tó sì ní ìjìyà lábẹ́ òfin.

Oríṣun àwòrán, bobrisky222/Instagram
"Àwọn èèyàn mẹ́tàlélógún láti mú láàárín ọdún yìí nìkan, ti Bobrisky kọ́ ni àkọ́kọ́"
Oyewalé fi kún ọ̀rọ̀ pé láti ọjọ́ Keje, oṣù Kejì ọdún 2024 ni alága àjọ EFCC, Ola Olukoyede ti gb;e ìgbìmọ̀ kan dìde láti ri dájú pé òfin tó de ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́ fẹsẹ̀ múlẹ̀.
Ó ní ìjìyà wà fún ẹnikẹ́ni tó bá ń ná owó náírà tàbí tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní agbo àríyá.
Ó ṣàlàyé pé òfin tuntun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fẹsẹ̀ múlẹ̀ ní iléeṣẹ́ EFCC ni àti pé láàárín ọjọ́ Keje oṣù Keji tí wọ́n ti gbé ìgbìmọ̀ náà kalẹ̀, èèyàn mẹ́tàlélógún ni ọwọ́ ti bá tí wọ́n sì ti fojú ba ilé ẹjọ́.
“Fún ìdí èyí, mímú Bobrisky kìí ṣe láti dúnkokò mọ bíkoṣe láti wá kojú àwọn ẹ̀sùn rẹ̀, a máa gbe lọ sí ilé ẹjọ́ tó bá di ọjọ́ Ẹtì.”
"Ìwádìí ń lọ láti mú àwọn ènìyàn ti ń ná owó tùùlù lójú agbo àríyá"
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí bí àwọn ènìyàn ṣe ń ṣàfihàn àwọn fídíò lọ́kan-ò-jọ̀kan lórí ayélujára níbi tí àwọn ènìyàn ti ń ná owó lójú agbo àríyá, Oyewale ní gbogbo rẹ̀ ni ìgbìmọ̀ náà ń rí àti pé ìwádìí ṣì ń lọ lọ́wọ́ láti mọ nawọ́ gán àwọn ènìyàn si.
“Ó ṣeéṣe kí a nawọ́ gán àwọn èèyàn púpọ̀ si láìpẹ́ yìí, tí wọn yóò si fojú ba ilé ẹjọ́.”
Bákan náà ló fi kun pé àwọn afurasí àádọ́jọ ló ń kojú ìgbẹ́jọ́ lọ́kan-ò-jọ̀kan lórí ṣíṣe owó náírà lọ́nà àìtọ́ káàkiri àwọn ilẹ́ ẹja ní gbogbo ẹ̀ka EFCC mẹ́rìnlá tó wà ní Nàìjíríà.
Agbẹnusọ EFCC náà ní láìpẹ́ yìí ni ìròyìn bí àwọn èèyàn ṣe ń gba ìdájọ́ lórí ṣíṣe náírà lọ́nà àìtọ́ yóò máa jáde.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ pé ìjìyà tí àwọn afurasí náà yóò gbà nílé ẹjọ́ kò sí lọ́wọ́ àwọn pé iṣẹ́ ti tàwọn ni láti ṣe ìwádìí afurasí, kí ilé ẹjọ́ sì gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀ bó ṣe yẹ.
Ó ṣo pé àjọ EFCC ń ṣiṣẹ́ takuntakun láti ri pé iṣẹ́ ìgbógunti ìwà àjẹbánu tí àjọ náà gbé dání ń lọ bó ṣe yẹ.















