BBC ṣe àlàyé lórí ìṣọ̀rí iná ọba tó wà fáwọn oníbàárà àti iye owó iná tí ìṣọ̀rí kọ̀ọ̀kan yóò san

Àkọlé fídíò, Elecricity Tarriff: Tí o bá wà ní Band A, B, C, D, E, wo iye wákàtí tó fi lo iná ọba

Se ni ariwo gbalẹ ni irọlẹ ọjọru nigba ti ajọ to n ri si akosos ipese ina ọba (NERC) kede pe afikun ti ba owo ina ọba.

Ileesẹ NERC naa salaye pe awọn isọri onibara wọn to wa ni isọri kinni, ti wọn n pe ni Band A, ni alekun owo ina ọba naa kan.

NERC naa ni awọn onibara to wa ni Band A yii lo n jẹ anfaani ina ọba fun ogun wakati ni ọjọ kan.

Se ni ọpọ ọmọ Naijiria si figbe bọnu pe awọn ko mọ isọri pinpin ina ọba ti awọn wa, ati pe, isọri onibara ina ọba melo lo wa gan, eelo si ni ikọọkan wọn n san.

Idi ree ti BBC Yoruba fi se akojọpọ iwaddi lati wa idahun si awọn ibeere to n jẹ awọn onibara yii lọkan.

Ẹ wo fidio yii lati mọ atupalẹ iwadii BBC Yoruba naa.

Àkọlé fídíò, Ta ni ojúlówó ọba ìlú Igboho láàrin Alepata, Onigboho ati Ona Onibode

Àwọn oníbàárà iná ọba wo ló wà ní ‘Band A’ àti àlékún owó iná tí wọn yóò san?

Latigba ti ikede ti jade latọdọ ijọba apapọ, pe afikun ti ba owo ina tawọn araalu yoo maa san lorilẹ-ede Naijiria ni awuyewuye ti gbode kan latọdọ araalu.

Bo tilẹ jẹ pe Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC) sọ pe awọn ti wọn wa ni isọri ‘A’, ti wọn n lo ina fun ogun wakati lojumọ tabi ju bẹẹ lọ ni afikun naa kan.

Awọn ti wọn pin si isọri ‘A’ yii ki i san ju ẹgbẹrun lọna aadọta naira (50,000) lọ tẹlẹ.

Ṣugbọn pẹlu afikun yii, owo wọn le wọ 170,000 loṣu kan ṣoṣo ti wọn yoo maa san.

Ileeṣẹ Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC), fọwọ si afikun yii, wọn si gbe e jade lọjọ kẹta, oṣu kẹrin ọdun 2024.

Iwadii nipa isọri onibara ina ọba
Waya ina ọba

Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sáwọn oníbàárà tó wà ní ìsọ̀rí B, C, D ati E?

Ohun kan to daju ni pe ọpọ araalu ko tilẹ mọ pe isọri tabi ipin kankan wa fun ina ọba lilo.

Ohun to kan wọn ko ju ki wọn ṣaa ti ri ina mọnamọna lo lọ.

Ṣugbọn Igbakeji alaga NERC, Musiliu Oseni to ba awọn akọroyin sọrọ l’Abuja lori afikun naa, ṣalaye pe isọri A titi de E lo wa.

O ni bawọn ṣe pin awọn onibaara awọn niyẹn.

Oseni sọ pe afikun owo ina yii ko kan awọn ipin B titi de E, nitori wọn ki i lo ina fun ogun wakati lojumọ kan.

Gẹgẹ bo ṣe wi, ’’ Ẹrọ apinnaka ti NERC ni bayii ju 800 lọ fun isọri ‘A’, ṣugbọn a maa din wọn ku bayii si ẹẹdẹgbẹta (500).

‘’Eyi to tumọ si pe ida mẹtadinlogun (17%) ni yoo jẹ isọri A bayii.

Àwọn èèyàn yóò máa rí iná lò ju ti tẹ́lẹ̀ lọ- NERC

Igbakeji alaga NERC tẹsiwaju pe awọn ti paṣẹ fun ileeṣẹ DisCos to n ṣeto ina lati ri i pe awọn eeyan ti afikun yii kan n rina lo ju ti tẹlẹ lọ.

Bakan naa lo ni wọn yoo tete maa dahun si ibeere wọn lori ohun to ba yẹ lati mojuto .

Wo àwọn nǹkan èèlò ile tí yóò mú owó iná rẹ wọ 170,000 loṣu

Gẹgẹ bi iwoye awọn onibaara to wa ni isọri ‘A’, ẹni to ba n lo firiji kan, firisa kan (freezer), faanu mẹta, ẹrọ amuletutu meji, giloobu itanna mẹẹẹdogun ( 15 bulbs), aayọnu ilọṣọ kan, microwave kan ati kẹtu to n lo ina kan, ko maa mura 170,000 owo ina oṣu kan.

Ki afikun too de, 50,000 ni ẹni to ba n lo nnkan eelo ile bawọnyi maa n san, ṣugbọn pẹlu afikun yii, owo naa ti gbẹnu soke gidi.

Bakan naa, odiwon ina 757.57KwH ni aadọta ẹgbẹrun naira n ra tẹlẹ, ni bayii, ko le ra ju 222.2KwH lọ.

Ṣugbọn NERC ti sọ pe ko si iṣoro disu tabi bentiroolu rira fawọn eeyan mọ.

Wọn ni wọn yoo maa rina ti wọn ba ra lo fun ogun wakati abi ju bẹẹ lọ.

Ajọ NLC fariga fun NERC, wọn lawọn ko gba afikun wọle

Ajọ to n ri si ọrọ awọn oṣiṣẹ lorilẹ-ede Naijria, Nigeria Labour Congress, (NLC), ti ni awọn ko faramọ afikun owo ina NERC rara.

Olori ẹka iroyin olu ileeṣẹ NLC, Benson Upah, sọ fun ẹka iroyin Daily Trust pe iwa ika ati airo ti ẹnikeji mọ tara ẹni ni NERC hu.

Upah sọ pe, ‘’afikun yii ko niran lasan, o tun fi han pe ika ni wọn pẹlu.

‘’Afikun to le sọ eeyan di alaini ni, paapaa awọn oṣiṣe olowo oṣu ti iye ti wọn n gba ko yipada.

‘’Koda, afikun yii ko le jẹ kawọn onileeṣẹ fọkan balẹ ṣiṣẹ’

‘’Yoo mu owo ọja wọn si i ni, o si le fa kawọn ileesẹ kan ko gba wọle, awọn eeyan yoo si padanu iṣẹ wọn.

O ni NLC yoo gbe igbesẹ lori afikun yii, lẹyin tawọn ipade to yẹ ba ti waye.

Ìjọba àpapọ̀ ṣe àfinkún owó iná mọ̀nàmọ́ná

Electricity

Oríṣun àwòrán, getty images

Ijọba apapọ ti kede afinkun owo ina mọnamọna fun awọn onibara to wa ni ipin A, iyẹn ‘band A.’

Igbakeji alaga ajọ to n bojumọ ọrọ ina mọnamọna ni Naijiria, Nigerian Electricity Regulatory Commission (NERC), Musuliu Oseni, lo fi ọrọ naa lede niluu Abuja.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, awọn onibara naa yoo bẹrẹ si n san owo ti iye rẹ jẹ ₦225 lori kilowaati laarin wakati kan dipo ₦66 ti wọn n san lọwọ yii.

Awọn wo lo wa lori Band A?

Gẹgẹ bii ohun ti NERC sọ, awọn onibara ti wọn n lo ina ijọba fun o kere tan, ogun wakati lojumọ kan lo wa ni ipin naa.

To n tumọ si pe kii ṣe gbogbo eeyan ni afikun naa kan, bi ko ṣe awọn to n lo ina ijọba daadaaa.

Oseni sọ siwaju si pe apapọ awọn onibara naa lo jẹ ida 15% ninu miliọnu mejila eeyan to n lo ina ijọba ni Naijiria.

O fi kun pe ajọ naa tun ti ja awọn kan lati band A si band B.

Ninu alaye rẹ, eredi jija awọn onibara lati ipele ti wọn wa tẹlẹ si isalẹ ko ṣẹyin bi wọn ko ṣe lagbara lati fun awọn onibara ọhun ni ina to bo ṣe yẹ.

Ẹwẹ, ọpọ ọmọ Naiiria lo ti bẹrẹ si n fi erongbsa wọn lede lori igbesẹ tuntun naa.

Bo tilẹ jẹ ijọba ti kede ṣaaju pe igbesẹ yii yo waye, awọn eeyan kii ṣe akoo yii yti nnkan le kmoko lo yẹ ki ijọba fi kun owo ina.