Ọkọ̀ elérò mẹ́fà há ṣójú ọ̀nà tí erin ń gbà, èrin tẹ ìyá kan pa, èèyàn mẹ́rin fara pa

Oríṣun àwòrán, Zambia
Erin ti tẹ iya agba ẹni ọgọrin ọdun kan pa.
Ibudo awọn ẹranko, Kafue National Park, ni iṣẹlẹ naa ti waye ni iwọ oorun orilẹede Zambia.
Fidio kan to ti gba ori ayelujara bayii lo ṣafihan bi erin naa ṣe kọlu ọkọ to gbe eeyan mẹfa, ti ọkọ naa si takiti lọpọ igba.
Keith Vincent, to jẹ adari awọn arinrianjo naa sọ pe ọkọ wọn ha soju ọna eyii to mu ko ṣoro lati gbe kuro nibẹ.
Awọn alaṣẹ ni oloogbe naa, to jẹ ọmọ ilẹ Amẹrika, ku lẹyin to farapa ninu ikọlu erin ọhun, ati pe wọn yoo gbe oku rẹ lọ silẹ Amẹrika laipẹ
Ọkọ ti awọn eeyan naa wa, ha soju ọna to yẹ ki erin gba, lo ba pa obinrin kan, eeyan mẹ́rin farapa"
Yatọ si obinrin to ku, awọn mẹrin mii tun farapa amọ wọn ti n gba itọju lọwọ.
Awọn ọlọpaa, to fi mọ awọn to n bojuto ọgba ẹranko ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa.
Keith Vincent ni “iṣẹlẹ laabi gbaa ni leleyi jẹ, a si ba awọn mọlẹbi alejo to jade laye kẹdun.
“A ti n ṣe awọn atilẹyin to yẹ fun awọn alejo atawọn mii ti ọrọ naa kan.”
Gẹgẹ bii ohun to sọ, iṣẹlẹ naa waye lẹyin ti ọkọ ti awọn eeyan naa wa ha soju ọna to yẹ ki erin to ṣekupa obinrin ọhun gba kọja.
Ẹwẹ, awọn orilẹede to fẹgbẹkẹgbẹ pẹ̀lú Zambia, iyẹn Zimbabwe ati Botswana ti ke gbajare lori bi awọn erin orilẹede wọn ṣe n bimọ.
Iye eeyan ti erin pa ni Zimbabwe ti pọ si laarin ọdun diẹ sẹyin.














