A tí rí díẹ̀ nínú ìbọn àwọn ọmọ ogun táwọn ọ̀dọ́ ìlú Delta pa, a ṣì ń wá yòókù - Iléeṣẹ́ ológun

Oríṣun àwòrán, Others
Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ mẹ́ta tí àwọn ọ̀dọ́ ìlú Okuama ní ìpínlẹ̀ Delta ṣekúpa àwọn ẹ̀ṣọ́ ọmọ ogun mẹ́rìndínlógún, àwọn èèyàn ìlú náà kò ì tíì ráyè wọ inú ìlú tàbí jáde kúrò nínú ìlú náà.
Èyí kò ṣẹ̀yìn bí iléeṣẹ́ ológun ṣe ń ṣe ìwádìí ní ìlú yìí àti àwọn ìlú mìíràn tó yiká látàrí bí wọ́n ṣe ṣekúpa àwọn iléeṣẹ́ ológun ọ̀hún.
Ní iléeṣẹ́ ìròyìn Arise TV, ọ̀gá àgbà iléeṣẹ́ ológun Nàìjíríà, Christopher Musa ṣàlàyé ìdí tí àwọn olùgbé ìlú Okuama kò ṣì tíì ní àǹfàní láti máa wọ ìlú wọn láti ìgbà táwọn ti gba àkóso ìlú náà.
Ó ṣàlàyé pé iṣẹ́ ìwádìí tí àwọn ń ṣe níbẹ̀ lágbára tó bẹ́ẹ̀ tó jẹ́ pé gómìnà ìpínlẹ̀ náà, Sheriff Oborevwori kò rí ààyè wọ ìlú ọ̀hún nítorí àwọn àyẹ̀wò tí àwọn ń ṣe.
Ó ní àwọn kò ì tíì ṣe àwárí gbogbo àwọn nǹkan ìjà ogun àwọn ọmọ ogun tí àwọn ọ̀dọ́ náà pa tán nítorí ní àwọn fi ń wá gbogbo inú àti ibi kọ́lọ́fín tí àwọn nǹkan ìjà ogun náà lè wà.
Ó sọ pé ọ̀pọ̀ àwọn ọ̀dọ́ ìlú ọ̀hún ni wọ́n ń fi owó tí wọ́n ń rí látara owó epo tí wọ́n ń jí fi ra nǹkan ogun, tí àwọn sì fẹ́ ṣe àrídájú rẹ̀ pé kò sí ohun ìjà ogun tàbí ohun tó lè bú gbàmù ní agbègbè náà kí àwọn tó kúrò.

Oríṣun àwòrán, IJỌBA NAIJIRIA
Ẹ ó rántí pé ìlú Okuama àti Okoloba ti ṣáájú fìjà pẹ́ẹ́ta kí wọ́n tó pa àwọn ọmọ ogun tó fẹ́ lọ pẹ̀tù sí aáwọ̀ náà.
Ní ọjọ́ Kẹrìnlá, oṣù Kẹta, ọdún 2024 ni àwọn ọ̀dọ́ kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọ̀dọ́ ìlú Okuama lọ dènà de àwọn ọmọ ogun tí wọ́n sì ṣekúpa àwọn mẹ́rìndínlógún tó fi mọ́ ọ̀gá ológun kan nínú wọn.
Ní ọjọ́ Kejìdínlọ́gbọ̀n oṣù Kẹta, ọdún 2024 ni wọ́n sin àwọn ọmọ ogun tó pàdánù ẹ̀mí wọn náà ní Abuja, olú ìlú Nàìjíríà. Ààrẹ Bola Tinubu àtàwọn gómìnà ìpínlẹ̀ Delta àti Bayelsa darapọ̀ mọ́ wọn níbi ètò ìsìnkú náà.
Lẹ́yìn tí ìwádìí ikú àwọn ọmọ ogun ọ̀hún bẹ̀rẹ̀ ni iléeṣẹ́ ológun kéde èèyàn mẹ́jọ bí ẹni tí wọ́n ń wá, pé wọ́n lọ́wọ́ nínú ikú àwọn sójà náà.
Nínú àwọn afurasí mẹ́jọ tí iléeṣẹ́ ológun kéde pé àwọn ń wá, ẹnìkan nínú wọn, adarí ìlú Okuama ti fa ara rẹ̀ lé àwọn aláṣẹ lọ́wọ́.
Iléeṣẹ́ ológun lẹ́tọ̀ọ́ láti kélé òfin gbé afurasí

Oríṣun àwòrán, NIGERIAN ARMY
Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí àwọn ẹ̀sùn tí àwọn èèyàn fi ń kan iléeṣẹ́ ológun pé wọ́n ń gba iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe nípa fífi òfin gbé àwọn afurasí ní agbègbè náà, Musa ní àwọn ní àṣẹ láti ṣe ìwádìí àti ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún àwọn afurasí nítorí àwọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni.
Níṣe ni àwọn ènìyàn ń bu ẹnu àtẹ́ lu iléeṣẹ́ ológun nítorí ìwé òfin Nàìjíríà àti òfin ológun kò fàyè gba àwọn ológun láti ṣe ìwádìí ìṣẹ̀lẹ̀ bẹ́ẹ̀.
Musa ní àwọn kò ma ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara àwọn nítor;i àwọn tẹ̀lé ìlànà òfin bí wọ́n ṣe yan àwọn lọrí ìwádìí náà ni.
Ó ní ààrẹ ti fún àwọn láṣẹ láti ṣàwárí àwọn nǹkan ìjà ogun àwọn òṣìṣẹ́ àwọn tó bá ogun lọ, kí àwọn sì nawọ́ gán àwọn afurasí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
“Tí ìgbìmọ̀ àwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò bá ti wà papọ̀, àwọn ológun ilẹ̀, ojú omi, òfurufú àtàwọn ọlọ́pàá ló máa ń wà nínú rẹ̀, tí a bá mú afurasí, a jọ ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò fún wọn ni.”
Ó wá rọ gbogbo àwọn tí wọ́n kéde gẹ́gẹ́ bí ẹni tí wọ́n ń wá láti fa ara wọn kalẹ̀ fáwọn ẹ̀ṣọ́ ààbò, pé ṣíṣe ìkọlù sáwọn ẹ̀ṣọ́ à[bò kìí ṣe ẹ̀ṣẹ̀ kékeré rárá.
Ó ní àwọn tó ṣe ìkọlù sáwọn ọmọ ogun náà ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí wọ́n ń rí àwọn ọmọ ogun ọ̀hún bí i pé wọ́n ń dí àwọn lọ́wọ́ lórí bí wọ́n ṣe ń jí epo rọ̀bì wà lágbègbè náà.















