Ẹ wà lójúfò! Ooru àmújù yóò mú láwọn ìpínlẹ̀ kan ní Nàìjíríà - Nimet

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ Nimet to n ri si ọrọ oju ọjọ ni orilẹede Naijiria ti kilọ fawọn araalu lati wa lojufo fun ooru amuju ti yoo mu lawọn ipinlẹ kan kaakiriri Naijiria.
Ajọ naa ṣalaye wi pe ki awọn eeyan to n gbe ni olu ilu Naijiria, Abuja, Kano, ipinlẹ Osun, Ekiti atawọn ilu mii maa gbaradi fun ooru eyi to le ṣe akoba fun ilera wọn.
Ajọ Nimet ṣalaye loju opo itagun ayelujara Facebook ati X rẹ pe ooru amuju le ṣokunfa oriṣiiriṣii arun to le jasi iku, eyi to maa n ṣẹlẹ nigba ti ooru ba ti pọju fun ara.
‘’A tun ti wọ asiko ooru amuju bayii, awọn eeyan ni lati wa ni imurasilẹ,’’ ajọ Nimet lo sọ bẹẹ.
Ajọ naa sọ pe ilu Abuja, ipinlẹ Sokoto ati Kogi ni ooru naa yoo ti pọ julọ.
Awọn ipinlẹ mii ni Kebbi, Katsina, Adamawa, Gombe, Bauchi, Taraba, Niger.
Ipinlẹ Zamfara, Nasarawa, Jigawa, Benue, ati Kwara naa wa lara awọn ipinlẹ ti ooru amuju yii yoo ti mu.
Bakan naa ni ajọ Nimet sọ fawọn eeyan ipinlẹ Ondo, Bayelsa, Akwa Ibom, Anambra, Delta, Enugu, Edo, Ogun, Plateau, Borno, Imo, Abia, ati Cross River lati gbaradi fun ooru bo tilẹ jẹ pe o le ma pọ to ti awọn ipinlẹ apa ariwa Naijiria.
Kinni ọna abayọ si ooru amuju to n mu ni Naijiria?
- Rii wi pe o n mu omi daadaa loorekoore lasiko ooru.
- Gbiyanju lati duro si ibi to tutu lati simi.
- Ma ṣe fi awọn ọmọde si inu ọkọ papaa julọ nigba ti ọkọ ko ba wa lori irin.
- Gbiyanju lati maa wọ awo si oju rẹ nigba kugba ti o ba jade sita.
- Aṣọ to fẹlẹ ni o dara lati maa wọ lasiko ooru.
- Ma ṣe rin ninu oorun ati pe dẹkun jijade laarin ago mejila ọsan si ago mẹrin irọlẹ.
Abọ iwadii awọn onimọ sayẹnsi kan ti fihan pe ayipada oju-ọjọ eyi tawọn eeyan ṣe okunfa rẹ lo fa ooru amuju to mu lẹkun iwọ-oorun ilẹ Afrika loṣu Keji to kọja ninu ọdun 2024 yii.
Awọn onimọ sayẹnsi ti wa kilọ pe bawọn eeyan ko ba dẹkun awọn ohun to n ṣokunfa ayipada oju-ọjọ bi eefin epo rọbi to n lọ soju ọrun, ooru amuju yoo maa mu lọdun meji meji ni ẹkun iwọ oorun Africa.
Oṣu Keji ọdun 2024 lo tii gbona julọ lagbaaye, ohun naa lo si jẹ oṣu Kẹsan an ti ooru yoo mu lera lera.












