Oluwo fi ọ̀pọ̀ mílíọ́nù ró àwọn ọ̀dọ́ tí kò rí owó ra irinṣẹ́ lágbára

Oluwoo ilu Iwo pẹlu awọn ọdọ to ro lagbara

Oríṣun àwòrán, Oluwoo

Olúwòó ti ilu Iwo, nipinlẹ Ọṣun, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, ti fi owo ro awọn ọdọ kan lagbara n'Iwoo, o si tun ṣeleri atilẹyin tuntun fún wọn bí wọn ba fi owo naa ṣe rere.

Ààfin Ọba Adewale ni eto onimiliọnu pupọ naa ti waye, nibi ti Olúwòó ti pin owo fawọn ọdọ ti ọpọ eeyan sọ pe tọọgi, ìyẹn ọmọ iṣọta ni wọn.

Wọn ni oríta káàkiri ni Kabiyesi ti lọọ ko wọn.

Olúwòó nínú ọrọ rẹ, sọ pe b'awọn eeyan ti ẹ n foju ọmọkọmọ wo àwon èèyàn naa, o loun ko ri wọn bẹẹ ni toun.

Búkàtá mi ni yín, àwọn èèyàn ló ń f'oju ọmọọta wò yin - Olúwòó

Awon odo ti Oluwoo ro lagbara

Oríṣun àwòrán, Oluwoo

Kabiyesi Oluwo ṣalaye pe awọn to ti kọṣẹ ọwọ, ti wọn si ti gba ominira lọdọ ọga, ṣugbọn ti wọn ko ri nnkan ṣe nílùú Iwo loun ro lagbara wọnyi.

O ni lóòótọ́ láwọn èèyàn n foju ọmọ iṣọta wo wọn, ti wọn sì n ro pe wọn o le ni láárí mọ.

" Ọpọ eeyan ro pe ọrọ yin o latunṣe mọ, sugbọn emi gbagbọ pe ẹ ṣi máa ṣe rere.

"Bukaata mi ni yín gẹgẹ bi ọdọ Iwo, mi o sì fi ibi ti kaluku yin ti wa ṣe ti mo fi fún yín lowo yii.

" Owo okoowo ni mo fún yín, ki ẹ fi gbe iṣẹ yin larugẹ. ‘’Mo ti ṣe temi fun yin, ẹyin naa ẹ dun mi ninu pada pẹlu atunṣe.

‘’Emi naa yóó máa bojuto bẹ ẹ ba ṣe ṣe e sí.

‘’Iranlọwọ ṣí tun máa wáyé si i fawọn ti wọn ba lo owo yii daadaa ninu yin.’’

Bẹẹ ni Oluwoo sọ.

Tẹ o ba gbagbe, laipẹ yii ni Ọba Adewale Akanbi pin ounjẹ fawọn to ku diẹ kaato fun, awọn arugbo ati bẹẹ bẹẹ lọ niluu Iwo.

Oluwoo ati awon odo naa

Oríṣun àwòrán, OLUWOO