Wo àwọn ibi tí òkùnkùn birimù yóò ti bo ayé mọ́lẹ̀ lónìí ọjọ́ Ajé

osupa

Oríṣun àwòrán, AFP

OKUNKUN BIRIMU

Oríṣun àwòrán, NASA

Bi oṣupa ba gba aarin-gbungbun ori ilẹ aye ta a wa yii kọja loju ọrun, to di gaga mọ òòrùn lati ràn ni awọn onimọ sayẹnsi n pe ni Eclipse.

Bi Yoruba yoo ba ṣe atupalẹ rẹ, wọn aa ni ọsan di oru. Awọn mi-in n pe ni Iṣiji-bo- oṣupa abi okunkun.

Irawọ ọsan to ohun ti agbalagba n peju wo ni ọrọ okunkun ojiji yii maa n jẹ, idi ni pe ki i saaba waye.

Ṣugbọn bi awọn awoye oju ọjọ ṣe wi, okunkun yoo bolẹ lojiji lọjọ Aje ọsẹ yii, ọjọ kẹjọ, oṣu kẹrin ọdun 2024.

Okunkun ti yoo bolẹ birimu ni wọn pe e, gbogbo aye ni yoo si fẹẹ ri i!

Oorun yoo de apa ibi ti oṣupa wa, yoo gba aarin aye ta a n gbe yii kọja, yoo si fi awọ pupa, ofeefe (yellow) ati wura bo oju oṣupa mọlẹ.

Eclipse ọdun 2024 yoo bẹrẹ lati Penrhyn Atoll, ninu agbami okun Pacific Ocean.

Ibẹ ni oorun yoo wọ si, ti ko ni i ran titi di aago 4:40 GMT, b’awọn aworawọ ṣe sọ.

Irú àwọn òkùnkun mélòó ló wà?

Okunkun birimu ti ọsan yoo da bi oru ni wọn n pe ni Total Eclipse.

Oorun, aye funra rẹ ati oṣupa yoo pade loju kan naa, oṣupa yoo waa bo oorun mọlẹ patapata.

O le ma ju fun akoko diẹ lọ ti yoo fi ṣẹlẹ, o si le gba to iṣẹju aaya.

Oju ọrun yoo dudu bii pe alẹ ni.

Juan Carlos Beamin, onimọ nipa awọn iṣẹda Ọlọrun bii Irawọ, Oṣupa, Oorun pẹlu awọn aye mi-in to tun wa (Astronomy) pin awọn okunkun ojiji naa si:

Òkùnkùn Òòrùn (Eclipse of the sun)

Nigba mi-in, bi oṣupa ba gba inu aye, yoo gba inu oorun naa kọja.

Imọlẹ kan ko ni i ti ara irawọ jade lasiko naa, okunkun yoo si bolẹ dudu.

O le yipada nigba mi-in ti oṣupa yoo bo aye mọlẹ birimu.

Òkùnkùn òòrùn tó kárí ayé (Total solar eclipse)

Eyi yoo bolẹ lọsan-an gangan, yoo si da bii pe oru ni.

O maa n ṣẹlẹ nigba ti Oorun, Aye ati Oṣupa ba kora pọ, ti agbara Oṣupa si borii gbogbo wọn.

Gẹgẹ bi ajọ NASA ( National Aeronautics and Space Administration) ṣe wi, iṣokunkun to pẹ ju yoo lo iṣẹju meje ati winni-winni mejilelọgbọn (7 minutes, 32 seconds)

Ẹẹkan laarin oṣu mejidinlogun ni wọn ni iru eclipse yii maa n ṣẹlẹ.

Okunkun yipo oṣupa Annular eclipse

Nigba ti Oṣupa ba sun kuro loju aye, to si kere si i, ko ni i bo gbogbo oju oorun tan.

Oorun naa yoo da bii oruka kekere lara Oṣupa, okunkun ko si ni i bolẹ tan.

Eyi ni awọn aworawọ pe ni Annular eclipse.

Ọjọ keji, oṣu kẹwaa ni afojusun wa pe Annular eclipse yoo ṣẹlẹ ni Ariwa ati Guusu Amẹrika.

Wọn ni yoo kan Antarctica, agbami okun Pacific, okun Atlantic ati apa kan Iwọ Oorun Afrika.

Oṣuoa laarin okunkun

Oríṣun àwòrán, Getty Image

Oṣupa alawọ meji

Oríṣun àwòrán, AFP

Okunkun onipele meji(Twin eclipses)

Beamín ṣalaye pe, "nigba ti oṣupa ba jinna sibi to ti le bo oorun mọlẹ, bo ṣe n sun siwaju lo n jinna saye si i titi ti ko fi le bo oorun mọ.

Eyi lo maa n yipada di ohun ti an pe ni Twin eclipse.

‘’O le yipada ko di Annular eclipse, abi ko di okunkun birimu pata. (Total eclipse)

Iru eyi waye gbẹyin logunjọ oṣu kẹrin, 2023.

NASA ti kede pe omi-in yoo waye loṣu kọkanla ọdun 2031.

Osupa laarin okunkun

Oríṣun àwòrán, Getty Image

Lunar Eclipse

Maa n waye nigba ti Aye ba wọnu Oorun ati Oṣupa, to dí imọlẹ pa.

Total lunar eclipse

Oorun ati Oṣupa yoo kọju sira wọn nigun mejeeji Aye.

Ajọ NASA ṣalaye pe imọlẹ oorun diẹ maa n de ọdọ Oṣupa ninu eyi.

Oorun naa yoo gba Aye kọja, ina alawọ buluu ni yoo si mu wa.

Eyi lo maa n jẹ ki oṣupa pọn bii ẹjẹ bi iru okunkun yii ba ṣẹlẹ.

Oun ni wọn si maa n pe ni ‘’Oṣupa ẹjẹ.’’

Oṣupa ẹjẹ

Oríṣun àwòrán, NASA

Okunkun kekere (Small lunar eclipse)

Gẹgẹ bi orukọ okunkun yii to n tumọ si kekere, apa kan Oṣupa yoo wọnu ojiji Aye lati mu okunkun wa.

O le jẹ dudu, o si le pupa bii ẹjẹ, ṣugbọn okunkun naa ni.

Oṣupa kekere

Oríṣun àwòrán, Getty Image