Ìjọba ṣàwárí ayédèrú òṣìṣẹ́ 40,000

Liberia

Oríṣun àwòrán, Moses Kollie Garzeawu

Ijọba Liberia ni oun ti ṣawari awọn ayederu oṣiṣẹ ti iye wọn to ẹgbẹrun lọna ogiji to n gba owo ijọba lai forukọsilẹ gẹgẹ bii oṣiṣẹ.

Adari ileeṣẹ to n ri si ọrọ oṣiṣẹ lorilẹede naa, Josiah Joekai sọ fun BBC pe niṣe ni awọn kan ṣeṣi fi orukọ awọn ayederu oṣiṣẹ naa sinu iwe akọsilẹ ijọba.

O fi kun pe orukọ awọn eeyan naa ko si ninu akọsilẹ iwe ‘Personnel Action Notice’ (Pan), eyii to jẹ dandan ki gbogbo orukọ oṣiṣẹ ilẹ naa wa.

O kere tan 70,000 oṣiṣẹ ijọba lo wa ni Liberia, ti idaji awọn oṣiṣẹ naa ko si gba abẹ iforukọsilẹ ‘Pan’ yii kọja.

Ọgbẹni Joekai sọ pe akọsilẹ Pan maa n ni gbogbo alaye nipa oṣiṣẹ kọọkan to n ṣiṣe fun ijọba lẹyin ti wọn ba ti pari gbogbo ayẹwo to yẹ ki wọn ṣe tan.

O ni bo tilẹ jẹ pe kii ṣe ẹbi awọn ọṣiṣẹ naa ni pe orukọ wọn ko si ninu akọsilẹ ijọba, ijọba yoo fun fun ni oṣu mẹta pere lati ṣe atunṣe.

Gẹgẹ bii ohun to sọ, gbogbo awọn to ba kọ lati fi orukọ silẹ yoo gba ldaduro lẹnu iṣẹ.

Aarẹ orilẹede naa, Joseph Boakai sọ pe afojusun oun ni lati ri pe ijọba dopin ati maa san owo oṣu fun awọn ayederu oṣiṣẹ.

Bakan naa lo tun ni oun fẹ din iye owo ti ijọba n na laarin ọdun ku.

Amọ ṣa, a ko tii le sọ irufẹ iha ti awọn eeyan orilẹede naa yoo kọ si igbesẹ ọhun.