Ọlọ́pàá ṣekúpa agbẹjọ́rò tó lọ sanwó ìtúsílẹ̀ ẹbí rẹ̀ tó wà lákàtà ajínigbé

ELIAS UGWU

Oríṣun àwòrán, ELIAS UGWU/FACEBOOK

Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi ní àwọn kò mọ̀-ọ́n-mọ̀ pa agbejọ́rò Elias Ugwu àti pé àṣìṣe ni ikú rẹ̀ jẹ́.

Ní ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ Kẹjọ, oṣù Kẹta ni agbejọ́rò Elias Ugwu pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ sọ́wọ́ ìbọn àwọn ọlọ́pàá ní agbègbè Anyigba, ìpínlẹ̀ Kogi.

Ugwu ló lọ sí ìpínlẹ̀ Kogi láti lọ san owó ìtúsílẹ̀ fún àwọn ajínigbé tó jí ẹbí rẹ̀ kan gbé ní ọjọ́ mélòó kan sẹ́yìn.

Àtẹ̀jáde kan tí agbenusọ iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi, Williams Anya fi léde ní àwọn rò pé ọkan lára àwọn ìgárá ọlọ́ṣà tó wá ṣọṣẹ́ ní àwọn ilé ìfowópamọ́ kan ní agbègbè náà ni Ugwu kí wọ́n tó yìnbọn fun.

Anya nínú àtẹ̀jáde náà ṣàlàyé pé àwọn adigunjalè ṣọṣẹ́ ní àwọn ilé ìfowópamọ́ mẹ́ta, tí wọ́n sì tún ṣe ìkọlù sí àwọn àgọ́ ọlọ́pàá ní ọjọ́ Keje, oṣù Kẹta ní Anyigba, ìjọba ìbílẹ̀ Dekina.

Ó ní èyí ló mú kí àwọn da àwọn ọlọ́pàá láti dá àláfíà padà sí agbègbè náà, kí wọ́n sì ri pé ọwọ́ tẹ àwọn adigunjalè ọ̀hún.

Anya ṣàlàyé pé àwọn gba ìpè látọ̀dọ̀ àwọn ará ìlú náà pé àwọn ń ṣe àkíyèsí ọkọ̀ kan tó ń lọ, tó ń bọ̀ fún bí ọjọ́ méjì, tó sì ń bèèrè ọ̀nà ní agbègbè ibi tí àwọn adigunjalè tó ṣọṣẹ́ gbé ọkọ̀ méjì àti ọ̀kadà wọn kalẹ̀ sí.

Ó tẹ̀síwájú pé èyí ló mú kí àwọn àti ikọ̀ fijilanté lọ dọdẹ ọkọ̀ náà àmọ́ nígbà tí àwọn ń gbìyànjú láti dá ọkọ̀ náà dúró, wọ́n kọ̀ láti dúró fún àwọn ni wọ́n ṣe yìnbọn sí táyà ọkọ̀ ọ̀hún láti dá dúró.

Ó fi kun pé nígbà tí àwọn súnmọ́ ọkọ̀ náà ni àwọn ri pé àwọn mẹ́ta ló wà nínú rẹ̀, tí ẹni tó sì wa ọkọ̀ tí farapa.

"A gbe lọ sí ilé ìwòsàn Maria Goretti, Ayingba níbi tó ti padà jáde láyé ní ọjọ́ kejì."

Agbẹnusọ ọlọ́pàá náà ní àwọn méjì tó wà nínú ọkọ̀ ló ṣàlàyé pé láti inú Alade ni àwọn ti ń bọ̀, pé àwọn lọ gba ẹnìkan kalẹ̀ ní àkàtà àwọn ajínigbé ni.

Ó ní wọ́n ṣàlàyé pé àwọn kò mọ nǹkankan nípa ìdigunjalè tó wáyé ní Ayingba àti pé àwọn kò sọ ní àgọ́ ọlọ́pàá pé wọ́n jí ẹnikẹ́ni gbé.

Ó fi kun pé Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá Kogi bá àwọn ẹbí olóògbé náà kẹ́dùn lórí ìpapòdà ènìyàn wọn àti pé tó bá jẹ́ pé wọ́n dúró nígbà tí àwọn ọlọ́pàá dá wọn dúró ni, àṣìṣe náà kò ní wáyé.

ELIAS UGWU

Oríṣun àwòrán, ELIAS UGWU/FACEBOOK

Ẹ̀wẹ̀, ẹgbẹ́ àwọn agbejọ́rò Nàìjíríà, NBA tẹ̀ka Nsukka ní àwọn kò faramọ́ ohun tí iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kogi sọ lórí ikú Elias Ugwu.

Alága NBA Nsukka, Sunny Okoro nínú àtẹ̀jáde kan ní àwọn ọlọ́pàá kàn dá ẹ̀mí ọmọ ẹgbẹ́ àwọn náà légbodò láì ní ìdí kan pàtó.

Okoro ní ẹgbẹ́ àwọn kò ní dákẹ́ àyàfi tí àwọn bá rí ìdájọ́ òdodo gbà lórí ikú Ugwu.

Ó ní lòdì sí ọ̀rọ̀ tí agbenusọ ọlọ́pàá Kogi sọ pé Ugwu kò fi ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé ẹbí rẹ̀, Alexander Ugwu tó ọlọ́pàá, ó ṣàlàyé pé Ugwu fi ẹjọ́ náà sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀.

Ó tún sọ pé Ugwu tún sọ fún àwọn ọlọ́pàá nígbà tó fẹ́ ṣe ìrìnàjò sí ìpínlẹ̀ Kogi láti lọ san owó ìtúsílẹ̀ tí wọ́n ń bèèrè fún.

Bákan náà ló ní kìí ṣe inú igbó ni wọ́n ti pá Ugwu àti pé kìí ṣe táyà ọkọ̀ ni ọlọ́pàá tó gbẹ̀mí rẹ̀ yìnbọn lù bíkòṣe orí, tó sì pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ilé ìwòsàn.