Ọlọ́pàá mú èèyàn méjì ní Naijiria lẹ́yìn ikú ọmọdé tó gbẹ̀mí ara rẹ̀ ní Australia

Oríṣun àwòrán, NSW Police
Eeyan meji ti dero atimọle ni Naijiria lori iku ọdọkunrin kan to gbẹmi ara rẹ ni Australia.
Iroyin ni awọn meji ti ọlọpaa mu naa gbimọ pọ lati gba owo lọwọ oloogbe ọhun lẹyin ti wọn dunkoko mọ pe awọn yoo fi aworan ihoho rẹ lede.
Ọlọpaa orilẹede Australia ni ọdọkunrin naa ti ọjọ ori rẹ ko tii to ogun ọdun fi aworan ihoho rẹ ranṣẹ si ẹnikan, ti ẹni naa si ni oun yoo fi aworan naa lede ayafi to ba san owo gọbọi.
Lẹyin iwadii ọlọpaa agbaye, ọwọ tẹ awọn ọkunrin meji to n dukoko mọ oloogbe naa, wọn yoo si kawọ pọn rojọ niwaju adajọ.
Ọlọpaa ko fi orukọ tabi ọjọ ori oloogbe naa to n gbe lagbegbe New South Wales lede lọna ati daabo bo ẹbi rẹ.
Ileeṣẹ ọlọpaa New South Wales ni awọn afurasi naa dukoko mọ ọmọdekunrin ọhun pe awọn yoo fi aworan ihoho naa ranṣẹ si awọn ọrẹ ati mọlẹbi rẹ to ba kọ lati fun ni owo ti iye rẹ to $330.
Adari ẹka to n ṣewadii iwa ọdaran ori ayelujara Matthew Craft, sọ fun ileeṣẹ iroyin Sydney Morning Herald pe “Atẹjisẹ ti wọn fi sọwọ si ọmọ naa buru jọjọ jai, wọn halẹ mọ pe o gbọdọ san owo naa ni kankan.”
Alẹ ọjọ naa gan ni ọmọde ọhun gbẹmi ara rẹ.
Awọn akọṣẹmọṣẹ agbofinro lati Australia, South Africa ati Naijiria lo ṣiṣẹ papọ lati fi ṣikun ofin mu awọn afurasi ọhun.
Iwadii ọlọpaa fi han pe awọn afurasi naa n wu irufẹ yii kan naa si awọn ẹlomiran lor ayeliujara.














