Ọkọ̀ ojú omi tó rì mú ẹ̀mí èèyàn 90 lọ ní Mozambique

Oríṣun àwòrán, Getty images
O le ni aadọrin eeyan to ti padanu ẹmi wọn lẹyin ti ọkọ oju omi kan ri ni Ariwa Mozambique.
Awọn adoola ẹmi lagbegbe Nampula ti iṣẹlẹ naa ti waye sọ pe awọn doola eeyan marun un ninu 130 to wa ninu ọkọ oju omi naa.
Akọwe ijọba ni Nampula, Jaime Neto ni ṣe lawọn eeyan ọhun n sa fun arun cholera to bẹ silẹ ki wọn to ṣe ṣababi ajalu naa.
O ni “nitori iye ero inu ọkọ naa to pọ ju lo jẹ ki ọkọ oju omi ọhun ri.”
Fidio kan ti a ko le fidi rẹ mulẹ lori ayelujara ṣafihan ọpọ oku to lefo lori omi.
A gbọ pe agbegbe Lunga ni ọkọ naa ti n rinrinajo lọ si Mozambique Island, iyẹn leti okun Nampula.
Ajọ unicef sọ pe arun cholera to bẹ silẹ nibẹ buru ju eyii ti wọn ti n koju lati ọdun marundinlogun sẹyin lọ.
Lati inu oṣu Kẹwaa ti arun naa ti bẹ silẹ ni Mozambique, eeyan 130,000 lo ti lugbadi rẹ, ti ọgbọn eeyan si ti ku.
Yatọ si arun yii, awọn alakakiti ẹsin Islam ni Cabo Delgado to sunmọ agbegbe naa tun ti gbẹmi ẹgbẹrun mẹrin eeyan, ti wọn si tun sọ miliọnu kan di alairilegbe.
Fun nnkan bii irinwo ọdun ni erekusu Mozambique fi jẹ olu ilu to wa labẹ isinru Porugal ni ila oorun Afrika.
Ibẹ si ni ajọ Unesco kede gẹgẹ bii ojuko iṣembaye ti awọn oyinbo alawọ funfun ti n ko awọn alawọ dudu lọ ṣe ẹru loke okun.














