Láti orí Fayoṣe dé Yahaya Bello, wo àwọn gómìnà tí wọ́n ti pitú fún EFCC rí

Oríṣun àwòrán, Fayose/Okorocha/Obiano/Bello/ Twitter/ Facebook
Ọrọ gomina ana nipinlẹ Kogi, Yahaya Bello, ko ti i kuro lẹnu awọn eeyan, pẹlu bi EFCC ṣe n wa a toun si ti wabi kan gba lọ.
O fẹrẹ to wakati mẹwaa ti EFCC, ajọ to n gbogun ti ajẹbanu lorilẹ-ede yii, fi n wa Yahaya Bello nile rẹ l’Abuja l’Ọjọruu to kọja yii.
Wọn n gbiyanju lati mu lorii ṣiṣe owo ti iye rẹ to biliọnu mẹrinlelọgọrin (84b) mọkumọku.
Ṣugbọn Gomina Kogi lọwọ yii, Usman Adodo, lo agbara ipo rẹ, o si daabo bo Yahaya Bello, o gbe e lọ ki EFCC ma baa mu.
Awọn ololufẹ Yahaya naa kun un lọwọ, wọn ko jẹ kawọn oṣiṣẹ EFCC wọle.
Eyi lo mu EFCC kede Bello bii ẹni tijọba n wa, ajọ to n ri si irinajo kuro nilẹ yii paapaa si ti kede rẹ bii ẹni ti wọn n ṣọ.
"Yahaya Bello kọ́ ni Gomina àkọ́kọ́ tí EFCC yóò fọwọ́ òfin mu"
Eyi kọ lakọọko tawọn gomina yoo ti fọgbọn alumọkọrọyi japa mọ EFCC lọwọ, ti ajọ naa yoo si pada fọwọ ofin mu wọn.
Nibi ti eto gidi ba wa, ajọ to fẹẹ mu afurasi yoo ranṣẹ pe e, pe ko wa.
Wọn le ti i mọle bi ọrọ rẹ ba gba bẹẹ, wọn si le yọnda rẹ ko maa tile waa yọju si wọn ki wọn too lọ si kootu.
Ṣugbọn ki i saba ri bẹẹ ni Naijiria, bii ki ẹni ti wọn fẹẹ mu maa sa kiri lo maa n ṣe wọn.
Èyí ni ìgbà mẹ̀ta míí táwọn gómìnà ti pitú fun EFCC bí wọ́n bá fẹ́ẹ́ mú wọn

Oríṣun àwòrán, Lere Ọlayinka
‘EFCC, emi ree o’- Fayoṣe
Ayọdele Fayoṣe, gomina Ekiti nigba kan, ko ti i pari saa rẹ to fi lọọ fa ara rẹ le ajọ EFCC lọwọ lọjọ Kerindinlogun, oṣu kẹwaa ọdun 2018.
Fayoṣe funra rẹ mọ pe EFCC yoo wọdii oun boun ba pari saa naa.
Eyi lo fi tete lọọ fara rẹ fun wọn lọjọ to ku ọla ti wọn yoo bura fun gomina tuntun, Kayọde Fayẹmi.
Ọna to pa ni lẹrin-in ni Fayoṣe gbe e gba, ‘’EFCC, emi ree o’’ ni wọn kọ sara aṣọ to wọ lọ si ọfiisi ajọ naa l’Abuja.
Bakan naa lo tun fi fọto ara rẹ sori ẹka Twitter bo ṣe n de ọfiisi ajọ EFCC.
Koda, gomina tẹlẹ naa gbe aṣọ ti yoo fi sun dani pẹlu irọri, o lo ṣee ṣe ki wọn ti oun mọ ọdọ wọn.
Oun ṣetan lati sun tiwọn di igbakigba ti wọn ba fẹ.
Ọjọ diẹ sigba naa ni EFCC pe Fayoṣe lẹjọ si kootu, ẹsun ajẹbanu lọna mọkanla ni wọn fi kan an.
Owo to to 6.9 billion ni wọn lo ji ko l’Ekiti.
Ẹjọ naa ṣi wa ni kootu titi donii, wọn o gbọ ọ tan.
Wọ́n fẹ́ẹ́ wáá yìnbọn fún mi ni o - Okorocha

Oríṣun àwòrán, Screengrab
Ni ti Rochas Okorocha, gomina Imo tẹlẹ, oun ṣe fidio ori ayelujara lorii Facebook ni, nigba ti EFCC ya wọ ile rẹ.
Okorocha pariwo pe awọn ajọ naa fẹẹ yinbọn foun bi wọn ṣe wọle oun ni.
Lọjọ kẹrinlelogun oṣu karun-un ọdun 2022, EFCC ya wọ ile Rochas Okorocha to wa ni Maitama, Abuja.
Wọn duro fun ọpọlọpọ wakati, wọn ko ri Okorocha ko yọju, ni wọn ba bẹrẹ si i fọ ilẹkun ki wọn le raye wọle pẹlu tulaasi.
Bi wọn ṣe n fọ ilẹkun ni Okorocha gba ori afẹfẹ lọ lati inu palọ rẹ, o n pariwo ni Facebook pe wọn fẹẹ yinbọn mọ oun ninu ile.
O ni gbogbo ilẹkun akọtami toun ṣe ni wọn ti wo lulẹ, oun o mọ ohun ti wọn waa ṣe o.
EFCC gun orí àjà mú Okorocha tó lìkì mọ́lé
Wọn pada mu Rochas Okorocha lọjọ naa nigba ti wọn gba ori àjà ile rẹ wọle.
Eyi waye lẹyin ti ajọ EFCC ti yin tajutaju si awọn alatilẹyin rẹ ti wọn ko fẹ kawọn oṣiṣẹ ajọ naa wọle.
Wọn pada gbe oloṣelu Owerri naa lọ si kootu, niwaju Adajọ Inyang Ekwo ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja.
Ẹsun mẹtadinlogun ni wọn fi kan an, owo to to 2.9biliion ni wọn lo ji.
Ẹjọ ọhun n bẹ ni kootu doni, wọn o ti i da a.
Obiano fẹ́ẹ́ jápa lọ s’Ámẹ́ríkà, EFCC ká a mọ́ pápákọ̀ òfúrufú Muritala n’Íkẹja

Oríṣun àwòrán, Wille Obiano @Facebook
Gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ, Willie Obiano, n mura ati tẹkọ leti lọ sorilẹ-ede Amẹrika ni EFCC da a duro.
Ọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹta ọdun 2022 ni.
Obiano ṣẹṣẹ kuro nibi eto iburawọle fun Chukwuma Soludo to gba ipo lọwọ rẹ ni, lo ba fẹẹ gba Amẹrika lọ lẹyin eto naa.
Ṣugbọn ajọ EFCC to ti n ṣọ ọ ko jẹ ko ri bẹẹ, wọn ka a mọ papakọ ofurufu Murtala Mohammed n’Ikẹja, niluu Eko.
Wọn ni ko le tirafu kankan.
EFCC sọ pe Obiano fẹẹ dọgbọn ka a nilẹ lẹyin ajẹbanu to ṣe fawọn eeyan Anambra ni.
Nnkan bii aago mẹjọ aabọ alẹ ọjọ naa ni Obiano fẹẹ japa lọ si Houston,l’Amẹrika, ki EFCC too lọọ ti i mọle fọjọ diẹ.
Biliọnu mẹrin owo naira ti i ṣe tawọn eeyan Anambra ni wọn ni Willie Obiano ji ko.
O foju ba kootu loṣu kin-in-ni ọdun yii.
Ẹjọ naa ṣi wa niwaju Adajọ Inyang Ekwo ti ile-ẹjọ giga ilu Abuja.
Agbára wo ni EFCC ní lábẹ́ òfin?
Olootu ati Minista fun eto idajọ ni Naijiria, Lateef Fagbemi, ṣalaye pe EFCC ni agbara lati ranṣẹ pe ẹnikẹni lati wadii lẹnu rẹ bo ti wu ki ẹni ọhun lọla to.
“ Mo n rọ ẹnikẹni ti EFCC ba ranṣẹ pe lati huwa ọmọluabi, nipa yiyọju si wọn.
Dipoo ki wọn maa sa kiri bawọn eeyan ṣe n ṣe nilẹ yii, eyi to n jẹ ki wọn maa foju abuku wo wa loke okun.”
Kemi Pinheiro, lọọya agba lorilẹ-ede yii (SAN) naa ṣalaye pe ajọ EFCC lẹtọọ lati fọ́ ibi ti afurasi ba sa si, ki wọn mu un jade.
O ni ipin kejila, ẹka keji ti eto idajọ ACJA (Section 12(2) of ACJA) sọ pe ọlọpaa le wọle afurasi, ki wọn tu ibẹ yẹbẹyẹbẹ lati mun un.
Amofin Pinheiro sọ pe ọlọpaa le ja ilẹkun tabi ferese abawọle to ba n di wọn lọna, bi ẹni ti wọn waa mu ko ba fun wọn laye lati wọle lọọ ba a.














