Ọwọ́ tẹ ọmọ ọdún mẹrìnlélógún tó jí ara rẹ̀ gbé ní Kwara

Oríṣun àwòrán, Kwara Police
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin ẹni ọdun mẹrinlelogun kan, Wasiu Afọlabi ti wọn lo pinnu lati ji ara gbe, to si n beere owo itusilẹ lọwọ awọn obi rẹ.
Afọlabi ni wọn lo n beere owo ti ko din ni miliọnu mẹta naira lọwọ awọn obi rẹ gẹgẹ bi owo itusilẹ, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ, wọn pada jọ duna-dura si idaji miliọnu kan naira.
Ọga ọlọpaa nipinlẹ naa, Victor Ọlaiya lo ṣalaye ọrọ yii lẹkunrẹrẹ fawọn akọroyin niluu Ilọrin lasiko to n ṣafihan Afọlabi lori iwa ọdaran to hu.
Ọlaiya ni ọjọ kẹtadinlogun osu kẹta, ọdun 2024 ni ẹgbọn Waisu to n jẹ Lekan Afọlabi to n gbe lagbegbe Mọyọ lo fi to awọn ọlọpaa leti wi pe awọn ajinigbe ti ji aburo oun gbe.
Lekan ni miliọnu mẹta naira ni awọn ajinigbe naa n beere lọwọ awọn mọlẹbi gẹgẹ bi owo itusilẹ, ṣugbọn lẹyin ọpọlọpọ ẹbẹ ati idunadura, wọn gba pe awọn yoo gba ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta (500,000) naira lọwọ awọn.
O fi kun-un pe, ajọsọ awọn, faye gba, ki awọn kọkọ san ẹgbẹrun lọna igba (200,000) naira gẹgẹ bi owo asan-silẹ.
Ọga ọlọpaa ṣalaye pe lẹyin ti awọn gbọ eyi ni ẹka ileeṣẹ wọn to n ri sọrọ ijinigbe bẹrẹ iṣẹ iwadii, ṣugbọn ti aṣiri pada tu si wọn lọwọ pe Wasiu gan-an lo wa nidi ijingbe ọhun
Victor Olaiya sọ pe, ọwọ tẹ Wasiu Afọlabi, ọwọ tun tẹ Moshood Sulaiman, to jẹ oniṣowo POS, to n gbe ni agbegbe Oyun, ẹni ti wọn jọ gbimọ papọ.
A gbọ pe Moshood Sulaiman yii lo ṣeto idunadura ati bi wọn yoo se san owo naa.
Ẹwẹ, Wasiu funra rẹ ti jẹwọ pe lotitọ loun ji ara oun gbe lati beere, ati pe oun nilo owo naa ni, bẹẹ lo bẹbẹ pe ki wọn fi oju aanu wo oun.
Ju gbogbo rẹ lọ, ileeṣẹ ọlọpaa ti jẹ ko di mimọ pe Waisu yoo fi oju ba ile-ẹjọ lati lọ ṣalaye ohun to ri lọbẹ, to fi gaaru ọwọ fun adajọ.















