Mo kọ́kọ́ rò pé kò dáa kí onígbàgbọ̀ wá olólùfẹ́ lórí ayélujára 'Dating APP'
Awọn ololufẹ meji ti wọn pade arawọn lori ayelujara ni igbagbọ awọn ni pe ko tọna ki onigbagbọ meji wa ife lọ si ori ayelujara.
Oni Opeyemi ati Ogunlaja Temitope ba BBC Yoruba sọrọ lori irinajo ifẹ wọn ati bi wọn ṣe pade loju opo ayelujara ati iha ti wọn kọ si wi wa ololufẹ lọ ayelujara.
Oni to jẹ ọkunrin ni ọna ti awọn gba pade jẹ ọna ti awọn eeyan ko ki n ro pe o le ṣeeṣe sugbọn awọn mejeeji dupẹ lọwọ Ọlọrun fun bii nnkan ṣe n lọ
O ni ohun akọkọ ti oun kọkọ bere ni pe ṣe o bojumu ki Onigbagbọ wa ololufẹ lori ayelujara ko to di pe o lọ pada iyawo tabi ọkọ rẹ.

“Lọkan mi gẹgẹ bii onigbagbọ, igba ti mo fẹ gba appu ololufẹ si ori foonu mi, mo kọkọ ni lọkan pe ṣe o bojumu pe ki onigbagbọ wa lori ayelujara ololufẹ
“Yatọ si iya mi, o loju awọn eeyan ti mo sọ fun pe ori ayelujara ni mo ti pade iyawo mi nitori gbogbo wa kọ ni a ma kọ ori sibi kan naa.
Temitope to jẹ obinrin ni ọjọ ti oun kọkọ pada ọkọ afẹsọna oun, aworan rẹ da yatọ si eyi ti o gbe sori ayelujara sugbọn oun pada mọ si o ṣe airẹ die nigba ti awọn mejeeji pade.
O ni inu ohun dun pupọ pe nnkan ti oun nifẹ gan ni oun ṣe kongẹ rẹ.
“Oju rẹ yatọ si aworan ti mo ri saaju, o wa ni ki n sin oun lọ gẹ irun, nigba ti awa de ibẹ,
"Ibi o ṣe n gẹrun ni mo ni pe ọmọ ọkunrin yii ma rẹwa o.
“Mo wa ni ri pe n kan ti mo bere fun gan ni mo ri igba.”
















