Israel ju àdó olóró sí àárín gbùngbùn Iran, ariwo sọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ado oloro ti ilẹ Israel sọ ti balẹ si arin gbungbun orileede Iran, awọn alakoso ilẹ Amẹrika ni wọn ṣalaye eyi fun ileeṣẹ iroyin CBS to ni ajọṣepọ pẹlu BBC
Ariwo idungbamu naa lo rinlẹ laarin gbungbun ilu Isfahan, eyi to mu ki wọn paṣẹ pe ọkọ baalu kankan ko gbọdọ fo, ileeṣẹ iroyin orileede Iran lo sọ eyi.
Iran la gbọ pe wọn ti gbaradi gidi nigba ti awọn Israel sọ pe awọn yoo gbẹsan ikọlu ti awọn ara Iran ṣe si wọn lọjọ Abamẹta to kọja.
Kini Iran ti kọkọ ṣe ṣaaju?
Ko din ni ọọdun ibugbamu oju ofurufu ti a mọ si drone ati missiles ti wọn sọ pe Iran ti fi ṣe ikọlu si Israel.
Pupọ rẹ si la gbọ pe awọn ọmọ ogun oju ofurufu Israel pẹlu ajọṣepọ Amẹrika, UK ati awọn oluranlọwọ miran n da duro lati ma ṣe balẹ.
Awọn iwe iroyin Iran kankan ko tii sọ boya ipalara kankan wa, ṣugbọn ti wọn ni gbogbo awọn nnkan ija ogun oju ofurufu wọn lo wa nibi aabo. Bẹẹ si lawọn Israel ko tii tako eyi.
Ẹkun Isfahan lo jẹ gbagede ibi ti wọn ti n ṣe ọpọ awọn nnkan ija ogun oju ofurufu bii missiles ati nuclear weapons.
Ileeṣẹ iroyin Fars ti ilẹ Iran sọ pe awọn gbo iro ibugbamu nitosi papakọ ofurufu Isfahan ati ileeṣẹ ologun niluu Isfahan, eyi to ta awọn ologun ji.
L’Ọjọbọ, ọsẹ yii, awọn alakoso orileede Iran ti ṣe ikilọ wi pe ikọlu ti Israel ba ṣe si wọn yoo jẹ ki awọn naa koju wọn pada.
Oriṣiriṣi igbesẹ ni awọn ajọ agbaye ti gbe lati le jẹ ki awọn orileede mejeeji jawọ ninu ogun ti gbe dide si ara wọn, ti wọn si n fẹ ki alaafia jọba.
Ìbẹ̀rù-bojo gbọkàn àwọn èèyàn Iran lórí ìkọlù sí Israel

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Inú fu, àyà fu ni àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè Iran wà báyìí lórí ìkọlù tí ikọ̀ ọmọ ogun Islamic Revolutionary Guards Corps (IRGC) ṣe sí Israel ní òpin ọ̀sẹ̀.
Àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Iran kan ní omi inú ń kọ àwọn lórí ipa tí ogun máa ní lórí àwọn ènìyàn orílẹ̀ èdè náà pàápàá lásìkò yìí tí ètò ọrọ̀ ajé àwọn dẹnu kọlẹ̀.
Nínú lẹ́ta kan tí àwọn èèyàn náà fi ránṣẹ́ sí BBC Persian ni àwọn ọmọ orílẹ̀ èdè Iran kan nílé àti lẹ́yìn odi ti bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù Iran sí Israel.
Wọ́n ní àwọn ń rí ìkọlù náà bíi ìfẹ́ inú ìjọba lòdì sí nǹkan tí àwọn èèyàn orílẹ̀ èdè náà ń fẹ́ gangan.
Wọ́n ní ìjọba gbé àkọ́lé kan sí òde pé Tel Aviv ni àwọn máa lò láti láti jagun kìí ṣe Tehran.
Orílẹ̀ èdè Amẹ́ríkà ni àwọn tó máa fi àwọn òfin tó lágbára de Iran láìpẹ́ ọjọ́ sí àsìkò yìí.
Akọ̀wé ètò ìsúná Amẹ́ríkà, Janet Yellen ní ẹ̀ka epo rọ̀bì tí Iran máa ń ta sí ilẹ̀ òkèrè ni àwọn ń wò lọ́wọ́ láti fi òfin dè wọ́n.
Yellen ṣàlàyé pé Iran ń fi àláfíà ẹkùn Middle East tàfàlà àti pé gbogbo àwọn orílẹ̀ èdè tí àwọn ní àṣepọ̀ pẹ̀lú ni àwọn máa bá sọ̀rọ̀ láti má fùn-ún Iran láàyè láti da agbègbè náà rú.
Ohun tí Yellen ń sọ yìí ló ń wáyé lẹ́yìn tí Israel ní kí àwọn orílẹ̀ èdè àgbáyé fi òfin de Iran lórí ìkọlù tí ó ṣe sí ohun.
Bákan náà ni iléeṣẹ́ olọgun Israel ní àwọn ṣì ń wo ọ̀nà tí àwọn máa gbà fi ṣe ìkọlù padà sí Iran nítorí àwọn kò ní jẹ́ kí ìkọlù tí wọ́n ṣe sí àwọn lọ lásán.
Agbẹnusọ iléeṣẹ́ ológun Israel ní Iran kò ní lọ láì j]iyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
Ààrẹ Iran, Ebrahim Raisi ṣèkìlọ̀ pé ẹnikẹ́ni tó bá ṣe ìkọlù sí àwọn ni àwọn máa fèsì fún padà pẹ̀lú ìkọlù tó lágbára.
Ohun tí a mọ nípa ìkọlù Iran sí Isreal
O le ni ado oloro igba ti orilẹede Iran fi ransẹ si orilẹede Isreal bayii.
Ninu atẹjade kan ni agbẹnusọ IDF, Rear Admiral Hagari ti kede ikọlu naa, to si ni ado oloro n lọ lọtun losi ni awọn ibi kan ni Isreal.
Hagari ni obinrin kan ni awọn le fidi rẹ mulẹ pe o farapa bayii, ti ado oloro naa si ba awọn ibi kan jẹ ni abudo awọn ọmọ ologun.
Hagari ko sọrọ lori obinrin to farapa naa sugbọn awọn eleto ilera ti balẹ ni ibudo naa lati ṣe itọju ọmọ ọdun meje to farapa ni agbegbe Bedouin ni Arad.
Ọpọ awọn olori orilẹede lagbaye lo ti bu ẹnu atẹlu ikọlu Iran si Israel.
Aarẹ Joe Biden ti ilẹ Amẹrika ni yoo pe ipade pajawiri awọn orilẹede G7 loni ọjọ Aiku lati bẹrẹ ijiroro lori ikọlu naa.
Olotu ijọba UK, Rishi Sunak, naa pẹlu awọn olori to ti bu ẹnu atẹlu ikọlu naa, to si se ileri pe orilẹede UK yoo gbaruku ti ilẹ Israel ati awọn orilẹede mii to yi wọn ka lasiko yii.
Olotu Ijoba Canada Justin Trudeau naa jẹ ko di mimọ pe orilẹede oun lo di ikọlu Iran si Israel, to si tun jẹ ko di mimọ pe Canada setan lati duro ti Israel lasiko yii.
Akọwe agba fun ajọ isọkan agbaye, United Nations, Antonio Guterres naa ti ke sita pe agbaye ko ni okun lati tun bẹrẹ ogun bayii.
Guterress rọ awọn igun mejeeji lati sẹwọ ogun duro lati fi aye silẹ fun ogun ti yoo jasi ki awọn ọmọ ologun ma kọju ija si arawọn ni apa Middle East.
“Mo ti sọ ni ọpọ igba, awọn agbegbe ati gbogbo agbaye ko le koju ogun kankan.”

Oríṣun àwòrán, EPA
Ki lo ti ṣẹlẹ saaju?
O ti pẹ diẹ ti Iran ti n ṣe ikilọ pe awọn yoo ṣe ikọlu si Israel lati gba ẹsan ado oloro kan ti Israel ju si dukia Iran ni wa ni olu ilu Syria, Damascus ninu oṣu yii.
Awọn ologun Syria ni ọkọ ofurufu Israei kọlu ile kan to jẹ dukia Iran, to wa ni oju ona marosẹ Mexxeh ni Damascus.
Awọn ologun Syria mu lara awọn ado oloro ti Israel ju diẹ balẹ sugbọn awọn kan yabara lọ kọlu ile naa, to si dawo.
Ado oloro naa ṣekupa awọn eeyan to wa ninu ile, ti awọn mii si faraoa yanayana.
Ikọlu yii ṣekupa eeyan meje to jẹ ọmọ ẹgbẹ Iran Islamic Revolution Guard Corps pẹlu olori wọn , Brig- Gen Mohammad Reza Zehedi ati Brig- Gen Mohammad Hadi Haji Rahimi.
Israel ko sọ boya awọn ni awọn ni di dukia Iran to dawo sugbọn wọn jẹ ko di mimọ pe awọn ko kin dasi oro orilẹede mii.
Ẹwẹ, Israel fidi rẹ mulẹ pe awọn ti lọwọ ninu ogunlọgọ juju ado oloro sinu Syria. Iwadii fihan pe kikọlu ati juju ado oloro lati ọwọ Israel lekun si bẹrẹ lati ninu oṣu kẹwaa lẹyin ti ogun bẹ silẹ ni apa ariwa Israel, Hezbollah, to sokunfa ogun Gaza.

Ẹ ma gbiyanju lati fesi si ado oloro ti a ju- Iran tun ṣe ikilọ mii Israel
Orilẹede Iran tun ti ṣe ikilọ mii fun orilẹede Israel lati ma ṣe gbiyanju pe awọn fẹ fesi pada si ado oloro bu gbamu ni Israel nitori o le wu pupọ, to si tun le fa ki wọn tun fi ọpọ ado oloro mii ransẹ si Israel.
Iran ni igbesẹ ti awọn yoo gbe ti Israel ba le fesi pada yoo buru ju ti tẹlẹ lọ.
Ọga agba fun ileeṣẹ ologun fun Iran, Ọgagun Mohannad Bagheri sọ ileeṣẹ momaworan ilu naa pe ti Israel ba fi ni awọn fẹ gba ẹsan, iran yoo dapada fun ni ilọpoilọpo ju ti tẹlẹ lọ.
Bakan naa ni Iran tun kilọ fun orilẹede Amẹrika to n ṣe atilẹyin fun Israel pe awọn yoo kọlu awọn ibudo Amẹrika.













