Ọlọ́pàá yìbọn pa ọkùnrin tó gún èèyàn márùn ún pa nílé ìtàjà ìgbalódé

Oríṣun àwòrán, Getty image
Ọkunrin kan ti gun ọmọ oṣu mẹsan an pa nile itaja Westfield shopping centre, to wa nilu Sydney, Australia.
Oni ọjọ kẹtala, oṣu Kẹrin, ọdun 2024 niṣẹlẹ naa waye.
A gbọ pe afurasi naa gun eeyan marun-un lọbẹ pa gẹgẹ bi ẹka iroyin abẹle ṣe wi, bẹẹ ni ọmọ oṣu mẹsan-an kan naa wa lara awọn to gun.
O si tun ṣe ọpọ awọn eeyan mi-in leṣẹ.
Ṣaaju ni awọn ọlọpaa to wa nitosi ti ni kawọn eeyan tete fi ile itaja naa silẹ, ki ọlọpaa obinrin kan too yinbọn pa afurasi ọhun.
Fidio to ṣafihan iṣẹlẹ yii lori ayelujara, gbe ọpọlọpọ awọn eeyan to farapa sita pẹlu.
Àwọn ó ṣojú mi kòró sọ bó ṣe ṣẹlẹ̀ gan-an

Oríṣun àwòrán, APTN
Obinrin kan to wa nile itaja naa lasiko iṣẹlẹ ọhun sọ pe, ‘’Were gbaa ni, niṣe ni gbogbo wa n sare kiri. Awọn eeyan ti fara pa yanna-yanna.’’
Bakan naa lobinrin kan ṣalaye fun ileeṣẹ iroyin Reuters, pe lojiji lawọn ri ọkunrin naa to gbe ọ̀bẹ nla kan dani.
O ni irisi rẹ jọ ti ẹni to fẹẹ maa pa awọn eeyan lọ .
"Ọkunrin naa n rin bọ niwaju wa pẹlu ọbẹ yẹn. Mo n gbọ tawọn ọlọpaa n sọ fun un pe ko gbe ọbẹ naa silẹ.
‘’Bi ọlọpaa obinrin kan ṣe yinbọn fun un niyẹn.
‘’Bi wọn ko ba yinbọn fun un bẹẹ, ko ba maa rin lọ bẹẹ ti yoo si maa paayan lọ ni.’’
Olootu ilẹ Australia naa loun ti gbọ nipa iṣẹlẹ yii.
Oju opo X rẹ lo ti ba awọn eeyan tiṣẹlẹ naa kan kẹdun, o si gboriyin fọlọpaa obinrin to tete mu apaayan naa balẹ.
Ọmọ oṣu mẹsan-an naa pẹlu awọn yooku ti ọkunrin naa gun ti n gbatọju.

Oríṣun àwòrán, BBC/ GOOGLE














