Ọwọ́ ba Gbadebọ tí wọ́n ló lu èèyàn pa níbi ìsìnkú bàbá rẹ̀

Aworan ọwọ ti wọn ko ṣẹkẹṣekẹ si

Ọkunrin kan, Gbadebọ Okekenu, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37) ti wa lahaamọ awọn ọlọpaa bayii nipinlẹ Ogun.

Wọn lo lu mọlẹbi rẹ kan, Adebayọ Gbenro, pa nibi isinku baba wọn l’Abẹokuta.

Ẹka iroyin ayelujara Punch, ṣalaye pe ọjọ Satide ọsẹ to kọja ni iṣẹlẹ naa waye, lagbegbe Ijẹmọ-Agbadu.

O ṣoju mi koro kan to ba ẹka iroyin naa sọrọ, ṣalaye pe ayẹyẹ isinku naa fẹẹ waye lọjọ Sannde ọsẹ yii ni, ti eto si ti bẹrẹ pẹrẹwu.

Nibi eto naa ni wọn wa lọjọ Satide ti ayẹyẹ ku ọla, ti ọrọ kan fi ṣe bii ọrọ laarin Gbadebọ ati Gbenro.

Nnkan bii aago mẹjọ alẹ ni ija naa ṣẹlẹ bo ṣe wi, Gbadebọ gba Gbenro lẹṣẹẹ laya.

‘Bó ṣe gbá Gbenro lẹ́ṣẹ̀ẹ́ láyà ló ṣubu’

Aburo oloogbe, Bọsẹ Ajani, sọ fun Punch pe bi Gbadebọ ṣe gba ẹgbọn oun lẹṣẹẹ laya lo ṣubu lulẹ.

O ni wọn sare gbe e lọ sileewosan ijọba to wa n’Ijaye, l’Abẹokuta, ṣugbọn dokita sọ pe o ti ku.

Ohun to fa ija ọhun ko to nnkan bo ṣe wi.

Ati pe ko sẹni to mọ pe inu le bi Gbadebọ to bẹẹ to fi fẹṣẹ pa Gbenro toun naa jẹ mọlẹbi oku ti wọn fẹẹ ṣe ayẹyẹ rẹ.

Ọlọ́pàá láwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí

SP Ọmọlọla Odutọla (Alukoro ọlọpaa Ogun)

SP Ọmọlọla Odutọla, Alukoro ọlọpaa Ogun, sọ pe awọn ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ yii, bi Gbadebọ ṣe ti wa lakata awọn.

Odutọla fidi ẹ mulẹ, pe ẹka to n tọpinpin iwa ọdaran lawọn yoo taari afurasi yii si.

O ni yoo si foju bale-ẹjọ lati jẹjọ rẹ bo ṣe yẹ lẹyin iwadii.