Orílẹ́èdè Kenya pàṣẹ ìdápadà oògùn ikọ́ ọmọdé Benylin Paediatrics lẹ́yìn ìkìlọ̀ NAFDAC

Benylin Paediatrics Syrup

Oríṣun àwòrán, @IkukuomaC

Ajọ to n ri si oogun lilo lorilẹede Kenya ti paṣẹ ikokuro oogun ikọ ti ajọ NAFDAC Naijiria kede pe o lewu fawọn ọmọde.

Ajọ naa sọ pe oun gba atẹjiṣẹ kan to ṣalaye pe oogun naa le ṣakoba fun ẹnikẹni to ba lo o.

Ninu ọrọ ti o fi lede lori oju opo X rẹ, ajọ naa ni ikilọ ajọ NAFDAC nipa oogun naa loun n gbe igbesẹ le lori.

NAFDAC ni awọn ti ṣawari eroja ‘diethylene glycol’ ninu oogun naa, eyii to le ṣakoba fun agọ ara eeyan.

Ajọ NAFDAC sọ pe lara awọn nkan to le ti ẹyin Diethylene glycol waye ni inu rirun lori dodo, èébì, igbẹ gbuuru, aile tọ, ori fifọ ati ọgbẹ inu kidirin to le ja si iku.

Ajọ to n ṣakoso oogun lilo ni Kenya ti wa paṣẹ fun gbogbo ile ipoogun ati ita-oogun to fi mọ gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto ilera wi pe ki wọn ma fun ẹnikẹni ni oogun ọhun mọ.

Ajọ naa ni oun naa ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori oogun ọhun.

Ile iṣẹ ipoogun Johnson & Johnson to ṣe oogun naa ni South Africa ko tii sọrọ lori oogun naa.

NAFDAC fi ìkìlọ̀ léde nípa oògùn ikọ́ ọmọdé Benylin Paediatrics Syrup

NAFDAC

Oríṣun àwòrán, NAFDAC

Ajọ to n bojuto oogun ati ounjẹ ni Naijiria, NAFDAC ti fofin de oogun Benylin Paediatrics Syrup ti ileeṣẹ Johnson & Johnson po.

NAFDAC ni awọn ti ṣawari eroja ‘diethylene glycol’ ninu oogun naa, eyii to le ṣakoba fun agọ ara eeyan.

Ninu atẹjade kan loju opo ayelujara rẹ ni NAFDAC ti fi ikede naa sita.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Gẹgẹ bii ohun to sọ, inu oṣu Karun un, ọdun 2021 ni wọn po ogun naa pẹlu eyii to ni nọmba 329304.

Bo tilẹ jẹ pe ipari oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni ọjọ ori oogun naa yoo dopin, ajọ NAFDAC ti paṣẹ ki ẹnikẹni maṣe lo ogun naa mọ.

Oogun ọhun lo maa n gbogun ti ikọ lara awọn ọmọde lati ọdun meji si ọdun mejila, amọ NAFDAC ti fofin de bayii latari abajade iwadii rẹ.

NAFDAC ni “iwadii ti a ṣe ninu laabu wa fi han pe oogun naa ni eroja diethylene glycol to pọju bo ṣe yẹ lọ eyii ti a ṣawari pe o ṣakoba fun awọn ẹranko ti a fi n ṣe iwadii.

“Diethylene glycol lewu fun agọ ara eeyan o si le yọri si iku.

“Lara awọn nkan to le ti ẹyin Diethylene glycol waye ni inu rirun lori dodo, èébì, igbẹ gbuuru, aile tọ, ori fifọ ati ọgbẹ inu kidirin to le ja si iku.”

Lẹyin naa ni NAFDAC wa ke si awọn to n ko ọja wọ Naijiria lati ilẹ mii lati sọra, ki wọn si ri daju pe wọn ko ko awọn ọja to le ṣakoba fun araalu wọle.

O fi kun pe ki ẹnikẹni to ba ṣi ni oogun naa lọwọ maṣe ta a fun awọn eeyan mọ, ki awọn to ti ra a ma si ṣe lo mọ.

Ipari oṣu Kẹrin, ọdun 2024 yii ni ọjọ ori abala oogun naa to ni Diethylene glycol ninu yoo dopin.