John Magufuli: Ọ̀pọ̀ ọmọ ilẹ̀ Tanzania ni Magufuli mú àyípadà rere bá orílẹ́èdè náà

Àkọlé fídíò, Magufuli mú àyípadà rere bá orílẹ́èdè Tanzania- Ònwòye

Bi a ku laa dere, eeyan o sunwọn laaye. Awọn ọmọ orilẹede Tanzania ti n ṣe idaro Aarẹ John Magufuli to papoda lẹni ọdun mọkanlelọgọta.

Ọpọ eeyan nilẹ naa fẹran Magufuli, wọn gbagbọ pe iṣẹ ribi ribi lo ṣe nipa gbigbe ogun ti iwa ajẹbanu.

Onwoye kan, Atilio Tagailile tiẹ sọ pe ọga ni Magufuli pẹlu ohun to ṣe lẹyin to di aarẹ orilẹede Tanzania titi o fi ku.

Wọn dibo yan John Magufuli gẹgẹ bi Aarẹ karun un Tanzania lọdun 2015.

Katakata ''bulldozer'' ni wọn n pe e wọn gboriyin fun Magufuli fun bi o ti gbogun ti iwa ajẹbanu ati inakuna ijọba lorilẹede naa.

Magufuli ni arun jẹjẹrẹ ni iwa ajẹbanu eyi to nilo ki ijọba fi ọwọ lile mu.