Tanzania: Lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́wàá, ajínigbé dá Dewji olówó sílẹ̀

Oríṣun àwòrán, AFP
Ọ̀dọ́mọdekùnrin olówó ilẹ̀ Áfíríkà Mohammed Dewji tí wọ́n jí gbé ní ọjọ́ mẹ́wàá sẹ́yìn ti di rírí báyìí.
Olówó ọmọ orílẹ̀èdè Tanzania náaà sọ ọ́ di mímọ̀ lójú òpó Twitter rẹ̀ fún ra rẹ̀ wí pé òun ti padà sílé lálàáfíà.
Mínísítà fún ọ̀rọ̀ àyíká lóríllèdè Tanzania, January Makamba tó tún jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ rẹ̀ fi hànde wí pé òun bá Dewji àti bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀.
Makamba sọ pé àwọn tó jí Mo gbé pa á tì sórí pápá kan lẹ́bàá ilé ijó Gymkana ni Dar es Salam èyí tíí ṣe olú ìlú kátàkárà Tanzania.
Ìròyìn tó ń tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni wí pé ìlera pípé ni olówó oníṣòwò náà wà súgbọ́n ó fara pa lọ́wọ́ àti ẹsẹ̀ nítorí ẹ̀wọ̀n irin tí wọ́n kò síì lọ́wọ́.
Kò sí àrídájú bóyá ẹnikẹ́ni san owó ìtanràn kí wọ́n tó dá a sílẹ̀.
Ní ọjọ́ mẹ́wàá sẹ́yìn
Ọdọmọkunrin tó lówó jùlọ ní Afrika ti di awati ni olu ilu orileede Tanzania, Dar es Salaam. nigba ti awọn aijinigbe ji gbe.
Awọn ọlọpaa to kede ijinigbe naa ni Mohammed Dewji n lọ fún ifaralokun to ma n se laarọ ní àwọn ajinigbe ṣadede gbé sálọ.
Wọn ni ọwọ ti tẹ eeyan mẹta kan ti wọn si ni meji ninu wọn kii ṣe ọmọ orileede Tanzania.
Pato idi ti wọn fi ji ọgbẹni Dewji gbe ko ti jẹyọ.
Ta ni Mohammed Dewji?

Iwe iroyin nipa ọrọ aje, iyẹn Forbes Magazine so pe biliọnu dola kan le diẹ ni ọrọ Mohammed ti o si jẹ wi pe oun nikan lo ni owo to to bẹ ni Tanzania.
Ninu iwadi kan to jadi ni ọdun 20117, wọn ni ọgbẹni Dewji ni ọdọmọkunrin tó lówó jùlọ ní Afrika.
Ogbẹni Dewji si tun jẹ alatilẹyin fun ọkan lara awọn ilumọka ẹgbẹ agbabọọlu ni Tanzania ti orukọ rẹ njẹ Simba
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Iwe iroyin Forbes so pe ni ọdun 2016, o fi idaji owo rẹ se itọrẹ.
Inagijẹ ti ọpọ eeyan mọ si ni Mo.
Ile iṣẹ rẹ METL pẹka ni orileede Afrika mẹfa ti wọn si n ṣe aṣọ,ounjẹ ati ororo.

Ṣe ijinigbe wọ pọ ni Dar es Salaam
Lati ọwọ Athuman Mtulya,Akoroyin BBC Africa, Dar es Salaam
Lati inu ede larubawa ni wọn ti ya orukọ ilu Dar es Salaam ti o tunmọ si ''Agọ Alafia'' city's name comes from Arabic, and literally means Abode of Peace.
Ti a ba se akawe laarin ilu bi Eko tabi Johannesburg ti wọn jẹ olu ilu Nigeria ati South Africa,ko fẹ si wahala pupọni Dar es Salaam.
Lootọ awọn ikọlu kọọkan ti waye ti ijinigbe awọn oloselu kan si waye laipe yi,eyi ni igba akọkọ ti wọn yoo ji onisowo gbe ni Tanzania paapa julọeleyi ti o lorukọ bi ọgbẹni Dewji.
Ko si ifoya fun awọn onisowo ti ọpọ ninu wọ́n a si ma rin lalai ni ẹsọ.
Fun idi ẹyi, ijinigbe ọgbẹni Dewji jẹ oun iyalẹnu.














