Olùkọ́ Kano sọ abiyamọ sí ìbànújẹ́, Ó lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Awọn alaṣẹ ni ijọba ibilẹ Fagge ni Kano sọ pe awọn ti ti ileẹ̀kọ́ kan pa lẹyin iroyin to gbode pe olukọ kan lu akẹkọọ kan pa nibẹ.
Awọn obi ọmọ ọdun mẹsan naa Surajo Surajo fẹsun kan olukọ rẹ ni ileẹ̀kọ́ El-Salam Success Academy to wa ni Kurna pe o lu ọmọ wọn pa.
Ileeṣẹ ọlọpaa Kano sọ pe awọn ti mu afurasi tọrọ naa kan.
- Wámú-wámú ni àwọn òṣìṣẹ́ aláàbò ti dúró fún ìwọ́de Yoruba Nation ní Ado-Ekiti
- 'Mo bá òkú Blessing tí wọ́n so ọwọ́ ẹ̀ sẹ́yìn pẹ̀lú ìwé pélébé tí wọ́n kọ pé ...'
- Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ṣàwárí ibi tí wọ́n ti ń rọ ìbọn AK-47 lábẹ́lé ní Jos
- Makinde ṣàfikún owó oṣù àwọn àgùnbánirọ̀ ìpinlẹ Ọyọ láti ẹgbẹ̀rún márùn ún sí ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀dógún náírà
Hajia Salma to jẹ iya ọmọ ọdun mẹsan an naa sọ fun BBC pe ko si nkankan to ṣe ọmọ oun nigba to lọ sileẹ̀kọ́ lọjọ Iṣẹgun ṣaadede ni wọn kan sọ pe o rẹ ti oun si gbe lọ si ile iwosan.
''Nigba ti mo gbe lọ si ile iwosan awọn dokita ko kọkọ fọwọ kan ti wọn si beere pe ki lo ṣe ọmọdekunrin yi.
Mo sọ fun wọn pe Olukọ rẹ lo sọ pe o n ke irora lo jẹ ki n wa gbe e wa si ọdọ yin.''
''Dokita wa da mi lohun pe awọn ko le ṣe nkankan mọ nitori nise lo n pọ ẹjẹ lẹnu ati imu''
Hajia Salma pada si ile ẹkọ naa nibi ti Olukọ ọhun ti sọ pe oun ko ni le tẹle lọ si ile iwosan.
O ṣalaye pe niṣe lawọn Oluko meji to ku parọwa si pe ko tẹle wi pe ko si nkan ti yoo ṣẹlẹ si.
Nigba ti wọn yoo fi pada de ile iwosan oku ọmọ naa ni wọn ba.
Lẹyin ti o gbo ohun to ṣẹlẹ.Alhaji Muhammad Abdullahi, to jẹ alaga ijọba ibilẹ Fagge paṣẹ ki wọn ti ileẹ̀kọ́ naa pa lati le jẹ ki iwadii waye.
''Mo ni ki wọn ti ileẹ̀kọ́ naa pa pẹlu bi igboro ti ṣe fẹ daru lori iṣẹlẹ yi tawọn kan si fẹ dana sun ileẹ̀kọ́ naa.
Emi ati awọn agbagba ni ki awọn ọlọpaa lọ sun ileẹ̀kọ́ naa mọjumọ ki awọn eeyan ma ṣe le dana sun''.
Arakunrin Sunday Daniles to jẹ ouldasilẹ ileẹ̀kọ́ naa sọ pe iwadii ti ohun ṣe fihan pe awọn ko mọ nkan to ṣe iku pa ọmọ naa.
O ni awọn n duro de abajade iwadii ọlọpaa lori iṣẹlẹ ọhun.
- Wo ìdí tí àgbẹ̀ kan, Muhammad fi da májèlé sínú kànga mẹ́sàn án tí àwọn èèyàn ń mu
- Ilé aṣòfin Naijiria buwọ́lu òfin tí yóò fi òpin sí ìdẹ́yẹsí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ní ìwé ẹ̀rí HND
- Nàìjíríà ti di orílẹ̀èdè tó ń ṣàn fún ìbànújẹ́ àti ìpayínkeke- Obasanjo
- Àjọ NYSC kò gbèrò rírán àwọn àgùnbánirọ̀ lọ sójú ogun- Àjọ NYSC
- 'Mo bá òkú Blessing tí wọ́n so ọwọ́ ẹ̀ sẹ́yìn pẹ̀lú ìwé pélébé tí wọ́n kọ pé ...'



















