Seyi Makinde: Gbígbégilé ojú òpó Twitter yóò ba ọrọ̀ ajé Naijiria jẹ́ ní àgbáyé

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ti bu ẹnu atẹ lu bi ijọba apapọ ṣe ti oju opo ikansiraẹni Twitter kaakiri orilẹede Naijiria.

Ninu atẹjade ti Gomina Makinde fi lede, O ni o pọn dandan lati fi ero rẹ lede lori igbesẹ ijọba Naijiria pẹlu bi wọn ṣe ti oju opo Twitter pa ni Naijiria.

Makinde ni gẹgẹ bi adari, ko yẹ ki ijọba apapọ hu iwa bẹẹ nitori ọrọ ti awọn eniyan n sọ ko ba wọn lara mu.

O ni o yẹ ki ijọba kọkọ fi oju sunnukun wo ipalara ti igbesẹ wọn lati ti oju opo ikansiraẹni Twitter yoo ni lori awọn ọmọ Naijiria.

''O yẹ ki ijọba Naijiria mọ wi pe gbigbegile oju opo Twitter lorilẹede Naijiria yoo fa ifaṣẹyin fun orilẹede Naijiria, eleyii ti yoo mu ki awọn orilẹede lagbaye tẹmbẹlu Naijiria lori ọrọ aje ati ibagbepọ ni awujọ.''

''Oju opo Twitter jẹ gbagede ti awọn ọdọ ati gbogbo awọn ọmọ Naijiria ti n fi ẹhọnu wọn han lati sọrọ nipa ohun ti ko ba tẹ wọn lọrun''

Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Twitter/Seyi Makinde

''Bakan naa ni awọn ijọba n lo oju opo yii lati ri bi igbesẹ ati eto wọn ṣe ri lara awọn ọmọ Naijiria, eleyii to n mu ki ijọba ṣe atunṣe.''

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Seyi Makinde ni o yẹ ki ijọba apapọ mọ nipa ati bi awọn ọdọ ṣe n lo oju opo yii fun ọrọ aje ati igbelarugẹ iṣẹ ọwọ ti wọn yan laayo.

Seyi Makinde ni eto ibanisọrọ igbalode ni oju opo Twitter ti awọn eniyan nilo lati fi pa awọn eniyan sọrọ, bẹẹ si ni awọn ti ko ni ile itaja tabi sọọbu n lo awọn oju opo yii lati ta ọja wọn.

Gomina naa wa kesi ijọba apapọ lati tun ero wọn pa lori igbesẹ naa, ki eto ọrọ aje ma ba a dẹnukọlẹ patapata ni Naijiria.