Food and Cattle Union: Á gba ₦4.75bn lọ́wọ́ ìjọba ká tó gbé oúnjẹ síta fún títà

oja

Oríṣun àwòrán, others

Agbarijọpọ ẹgbẹ awọn to n ta ounjẹ ati maalu nilẹ Ariwa Naijiria ti ṣeleri lati dawọ duro lori kiko ounjẹ wa si ẹkun iwọ oorun guusu.

Ẹgbẹ naa sọ pe awọn yoo mu ileri yii ṣẹ laarin ọsẹ mẹta si asiko yii, ti ijọba ba kọ lati ṣe nkan si awọn ohun ti wọn n beere fun.

Alaga ẹgbẹ naa, Muhammed Tahir to ba awọn akọroyin sọrọ lẹyin ipade ẹgbẹ to waye lọjọ Iṣẹgun lo fi ọrọ yii lede.

O ni lati igba ti Gomina ipinlẹ Kogi ti dasi aawọ to wa nilẹ tẹlẹ ni nkan bi ọṣu mẹta sẹyin, awọn ko gbọ ohunkohun mọ lati ọdọ ijọba nipa ohun tawọn beere.

Àkọlé fídíò, Tunde Gbadamosi: Kìí ṣe Tinubu ní ipò ààrẹ̀ tọ́ sí, ìgbà wo ní ìtan ajá ń kan lèmọ́mù?

Ẹgbẹ awọn ontaja ounjẹ lati ẹkun ariwa naa ni ijọba jẹjẹ lati fun awọn ni owo gba ma binu toto biliọnu mẹrin ati miliọnu lna ọtalẹẹdẹgbẹrin o din mẹwa naira (N4.75bn)

Owo yii ni wọn ni ijba fẹ san lati tu awọn ninu nitori adanu to ba awọn lati ipasẹ ija to waye ni ọja Sasa nilu Ibadan losu kẹta ọdun yii.

Bẹẹ ba gbagbe, ọjọ mẹfa ni wọn fi kọ lati ko ounjẹ wa si guusu Naijiria ni osu kẹta ọdun 2021, ki Gomina Kogi, Yahaya Bello ti ijọba yan lati pari aawọ naa, fi pẹtu si wọn ninu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nkan to mu ki ẹgbẹ naa dawọ kiko ounjẹ wa si awọn ipinlẹ Yoruba, ko ṣẹyin ikọlu to waye ni ọja Sasha ni Ibadan.

Wọn fẹsun kan awọn Yoruba pe wọn n ṣeku pa awọn ọmọ ẹgbẹ awọn, ti wọn si tun da wọn lọna lati maa gba owo lọwọ wọn.

Tahiru ṣalaye pe, lẹyin tawọn ṣagbeyẹwo gbogbo ọrọ to wa nilẹ yii, awọn ti pinnu lati se atilẹyin fun awọn ontaja alubọsa to ti dawọ kata kara duro.

O ni ti ijọ́ba ba kọ lati wa wọrọkọ fi ṣada lori ohun tawọn n fẹ lẹyin ọsẹ mẹta awọn yoo gunle iyansẹlodi.

Àkọlé fídíò, Adebayo Shittu: Èmi kò ṣẹ Abiola Ajimobi nígbà ayé ẹ, òun ló ṣe mi ṣùgbọ́n.....

Pupọ ounjẹ bi ẹwa, agbado ati nnkan elo bi timaati ati ata, lawọn oniṣowo Hausa n ko wa si guusu Naijiria fun tita.

Nigba ti wọn dawọ kiko ounjẹ wa lọjọ mẹfa ninu oṣu Kẹta, n ṣe ni ọwọn gogo ounjẹ waye, ti araalu si n ke irora.