US Consulate: Ojú lálákàn fí n ṣọ́ri l‘Eko báyìí, wo ìlànà tó tẹ̀lé fún ààbò ẹ̀mí rẹ

Ojú lálákàn fí n ṣọ́ri nìlú Eko lásìkò yìí, wo àwọn ìlànà tó yẹ kí ó tẹ̀lé fún ààbò tó yẹ

Ilé iṣẹ́ asoju ilẹ́ Amẹrika ni Nàìjíríà ti gbé atẹjáde kan sita lori bó ṣe yẹ kí àwọn ènìyàn máa rìn ní ìlú Eko, kí wọ́n má bá bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọdaran.

Nínú àtẹjáde náà ni ilé iṣẹ́ ilẹ̀ Amerika ti ni àwọn ti gbúro àwọn ìgárá ọlọ́sà nípìnlẹ̀ Eko pàápàá jùlọ ni agbegbe Ikoyi àti Victorial Island, ti wọn ti n se ọsẹ julọ.

Bakan naa lo fikun pe ọwọ ti iwa idigunjale ati alọnilọwọgba se n pelkeke si nilu Eko gba ifura, ti ọpọ awọn onisẹ ibi naa si maa n fọ digi ọkọ lati ja araalu lole ojukoroju.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Atẹjade naa salaye pe se ni awọn ọlọkada maa n yọ tẹle awọn mọto ti wọn ba fẹ ja lole loju popo, titi ti awakọ naa yoo fi duro lasiko ti ina to n dari ọkọ ba ni ko duro, ti wọn yoo si raye ja onitọun lole dukia rẹ.

Ileesẹ asoju ijọba ilẹ Amẹrika ni Naijiria tun tẹsiwaju pe yatọ si pe awọn isẹlẹ idigunjale naa maa n waye ni aaji, loru dudu, amọ sibẹ, ọpọ irufẹ isẹlẹ naa tun waye ni ọsan gangan.

Screenshot

Oríṣun àwòrán, Screenshot

Atjade naa wa rọ awọn araalu, paapaa awọn ajeji lati ilẹ Amẹrika lati maa fi oju sọri nitori awọn isẹlẹ idigunjale ọhun maa n mu ẹmi lọ nigba miran.

Ìlànà ààbò mẹ́wàá tó ṣe kókó fún olùgbé ìlu Eko:

  • Lá ojú rẹ̀ sílẹ̀ dáada tí o bá n rí ni alẹ́, ti gbogbo ilẹ̀kùn ọkọ̀ rẹ nígbà gbogbo paàápàá jùlọ lásìkò tí o bá wà nínú súkẹrẹ fàkẹrẹ
  • Má dá wà nínú ọkọ rẹ kí o sì má dúró gbé ẹnikẹ́ni tí o kò mọ̀ rí. lójú pópó.
  • Kó owó rẹ, Laptop, Kamẹra, báàgì àti àwọn nǹkan mííràn pamọ́ dáadaa tí o bá n wakọ lọ́wọ́
  • Gbé ọkọ̀ rẹ sí agbégbé tí iná bá ti mọ́lẹ̀ rekete ni alẹ́.
  • Fi ọ̀rọ̀ rẹ ṣe ojú ni alákan fi n sọ́rí ti ọ bá fẹ́ wọ inú ọkọ̀ rẹ, wó àyíká fún ẹnikẹni tabá òhunkohun ti ko tọ́ lágbègbè ti o wà.
  • Dẹ́kun kọ̀ọ̀rọ̀ gbigba ti ilẹ̀ bá tiṣú, tọ ojú ọ̀nà gbaara.
  • Má dá rìn lálẹ́, ẹni a bí i re kìí rin rìn òru..
  • Dèédé iye owó tí o nílò ni asiko kan.
  • Tí o bá nilo ki o rin irin ajo ni alẹ́, má jẹ́ kí o wọ aago mẹ́wàá ki ó to wá ibi wọ̀ sí.
  • Gbìyànjú láti maṣe fi bi o ṣe to han ninu imúrà tàbi ìsọ̀rọ̀ si rẹ ni ita gbangba, ilé iwe, ilé ìwòsàn, ilé ijọsin tàbi lẹ́nù iṣẹ́, tó fi mọ́ garajì ọkọ̀.
  • Máa fi gbogbo ìgbà yí irìnajò rẹ pada, jìnà si ibi ti èrò ń péjọ sí, má lọ fún òde ifẹhọnuhan, mú káàdì ìdánimọ̀ rẹ dáni nigbagbogbo, kí o sì má gbọ́ ìròyìn lóòrè kóòrè fún ọ̀rọ̀ ètò ààbo