Twitter ban, NBC, media agencies: Ẹ̀yin iléesẹ́ ìròyìn gbogbo ní Nàìjíríà, Ẹ dẹ́kun líló 'Twitter' bí bẹ́ẹ̀ kọ́...- NBC

Oríṣun àwòrán, Naijanews.com
Leyin ikede ti ijọba Naijiria ti fopin sin lilo ọna ibaraẹnisọrọ 'Twitter', ajọ to n mojuto ọrọ awọn ileesẹ iroyin gbogbo ni Naijiria, National Broadcasting Commission (NBC) ti fi asẹ mii sita.
Ajọ NBC kede pe lati asiko yii lọ gbogbo ile isẹ iroyin ni Naijiria bii, Redio, Amohunmaworan ati bẹẹ bẹẹ lọ gbọdọ fopin si lilo 'Twitter'bayii.
Ojogbọn Armstrong Idachaba lo fi atẹjade naa sita pe ijọba koro oju si bi awọn ileesẹ iroyin kan ni Naijiria si se n lo 'Twitter'titi di asiko yii.
- Ìwádìí tí bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí Olùkọ́ lu akẹ́kọ̀ọ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn án pa
- Mọ̀ si i nípa ìtàn eégún Gelede àti pàtàkì eégún náà sí àwọn obìnrin nílẹ̀ Yoruba
- Wo àwọn nkán tó ṣẹlẹ̀ níbi ìwọ́de Yoruba Nation tó ti wáyé sẹ́yìn
- Dejọ Tunfulu àti Aisha Lawal dárà láti sàmì ọjọ́ ìbí wọn
- Alaafin Oyo, Oba Adeyemi yarí lórí isẹ̀lẹ̀ ìsekúpani tó wáyé ní Igangan
Idachaba ni: " Lataari asẹ ijọba Naijiria, a gba imọran pe ki awọn ileese iroyin ni Naijiria dẹkun lilo 'Twitter'ati lilo o gẹgẹ bii UGC ti wọn fi n yẹ iroyin wọn wo.

Oríṣun àwòrán, NBC
Abala 2 (1) ninu iwe ofin NBC sọ pe NBC ni agbara lati rii daju pe gbogbo ileesẹ iroyin mu asẹ ijọba se nigba gbogbo ni eyi to maa mu adinku ba iwa ibajẹ ni awujọ wa".
Bakan naa lo menuba abala 5, 6, ati 3 iwe alakalẹ naa to sọ pe ileese iroyin gbọdọ sọra fun lilo ohun eelo iroyin to le fa iyapa, ija tabi asọ ni awujọ.
Eyi ja si pe ko bojumu to ki ileese iroyin ni Naijiria maa lo "Twitter' lẹyin ti ijọba ti fofin de wọn.










