BBC Igbo Townhall meeting: Kìí ṣe jàgídíjàgan ni ọ̀nà àbáyọ sí ìṣòro Naijiria - Ohaneze, Mefor, Briggs

Godson, Ankio Briggs, Alex Ogbonna, Nnedinso Ogachie,Uche Mefor

Awọn onimọ kan to jẹ ẹya Igbo ni Naijiria ti sọ pe iwa jagidijagan kọ ni ọna abayọ si iṣoro ti Naijiria n koju lọwọ yii.

Awọn eeyan naa lo sọ ọrọ ọhun lasiko ifọwerọ kan ti BBC ṣe onigbọwọ rẹ.

Lara awọn to wa nibi ifọrọwerọ naa ni Alex Ogbonna lati ẹgbẹ Ohaneze, Mazi Ogbonnaya ati Annkio Briggs.

Briggs sọ pe oun ti gbọn lasiko ogun abẹle Biafra, iriri ogun naa kii ṣe iriri ti oun fẹ lati ri lẹẹkan sii.

O ni "Mo ranti daadaa pe asiko ogun abẹle, awọn ohun to ṣẹlẹ ṣaaju ogun naa lo tun n ṣẹlẹ bayii laye ode oni."

h

Oríṣun àwòrán, Other

Briggs ṣalaye pe awọn ohun to n ṣẹlẹ nilẹ Igbo lọwọ awọn eeyan lati ilẹ okeere ninu, awọn eeyan naa si n gbimọ lati da omi alaafia agbegbe naa ru ni.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, inu awọn eeyan ilẹ Igbo ko dun si ohun to n lọ lọwọ ni Naijiria bayii.

Àkọlé fídíò, Ogbomoso: Ẹ kálọ sí Ajilete láti mọ àwọn ibùdó tó mú kí ìlú náà yàtọ̀

Sugbọn ni ṣe lo yẹ ki gbogbo ipinlẹ to wa nilẹ Igbo ṣe ara wọn ni oṣuṣu ọwọ ju ki wọn maa da wahala silẹ lọ.

O pari ọrọ rẹ pe, kii ṣe Naijiria nikan ni awọn eeyan ti n binu si ijọba.

Amọ̀, tilẹ jẹ pe o jọ bi ẹni pe ijọba Naijiria ko naani awọn ẹya Igbo, rukerudo kọ ni ọna abayọ.

h

Oríṣun àwòrán, Other

Ẹwẹ, nigba to n da si ọrọ naa, Alex Ogbonna sọ pe irufẹ ọrọ odi ti awọn eeyan n sọ lo tubọ n da kun wahala to wa nilẹ tẹlẹ.

O ni gẹgẹ bii iriri ti oun ti ri, ipade apero ni ọna to dara ju lati yanju aawọ ju rogbodiyan lọ.

Àkọlé fídíò, Alakuko/Elega Schools: Aráàlú ní olùkọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ti sá ní kíláàsì tí kò dára

Bo tilẹ jẹ pe o ni inu oun dun si agbekalẹ ikọ alaabo Ebube Agu ti awọn gomina iha naa ṣagbekalẹ rẹ, o ni ikọ naa ni lati ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ lati daabo bo awọn eeyan agbegbe wọn.

Annkio Briggs

Oríṣun àwòrán, Annkio Briggs

Ni ti Mazi Ogbonnaya, o sọ pe o yẹ ki awọn eeyan ẹya Igbo gbagbe ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin, ṣugbọn ki wọn maa wo ọjọ iwaju.

John Godson

O ni o yẹ ki awọn ọdọ lọ yẹ iwe itan wo, ki wọn mọ ohun to ti ṣẹlẹ sẹyin ki wọn to maa ṣe awọn ohun ti wọn n ṣe.

Àkọlé fídíò, Alakuko/Elega Schools: Aráàlú ní olùkọ̀ọ́ àti akẹ́kọ̀ọ́ ti sá ní kíláàsì tí kò dára

O pari ọrọ rẹ pe ki awọn ọdọ dẹkun ati maa ba awọn adari ja ṣugbọn ki wọn wo bi wọn ṣe le kin wọn lẹyin ki wọn le ṣe aṣeyọri.