June 12: Iléeṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Eko láwọn kò mọ ohun kan nípa ìwọ́de láti ṣeàyájọ́ ọ́jọ́ June 12

Oríṣun àwòrán, Babajide Sanwo-Olu
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ti sọ pe awọn ko mọ ohun kan nipa iwọde tawọn eeyan n sọ lori ayelujara pe yoo waye lọjọ Satide tii ṣe June 12.
Ọjọ kejila oṣu kẹfa naa ni ayajọ ijọba awarawa lorilẹede Naijiria, ọjọ kan naa lawọn kan ti n sọ pe awọn yoo ṣe ifẹhonuhan lori bi ilu ko ṣe fararọ lasiko yii.
Amọ, ninu atẹjade kan ti kọmiṣọnaa ọlọpaa ipinlẹ Eko, CP Hakeem Odumosu fi sita lati ọwọ alukoro ileeṣẹ ọlọpaa, Olumuyiwa Adejobi, o ni awọn ọlọpaa ko gbọ nipa iwọde ọhun.
- Wo ọ̀rọ̀ tí ọ̀gá àgbà ọlọ́pàá ní Nàìjíríà sọ lórí ìfẹ̀hónúhàn June 12
- Ìrora iṣẹ́ abẹ ìdí tí mo ṣe pọ̀jù, mò ń kú lọ, mo fẹ́ padà sí bí mo ṣe wà tẹ́lẹ̀ - Bobrisky
- Àṣìgbé ọmọ wọ́ọ̀dù ni Seyi Makinde - Àgbààgbà PDP l‘Oyo ka ẹ̀sùn sí gómìnà l'ẹ́sẹ̀
- Wo ọ̀nà tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi fẹ́ sàmí June 12 lọ́la, tí ariwo fi gbalẹ̀
- "Bí Buhari kò bá dáàbò bo aráàlú, Sunday Igboho àtàwọn èèyàn míì yóò ṣé"
- Agbébọn pa akẹ́kọ̀ọ̀ kan, jí ọ̀pọ̀ míràn gbé lọ ní Poly Kaduna
- "Bí Buhari kò bá dáàbò bo aráàlú, Sunday Igboho àtàwọn èèyàn míì yóò ṣé"
CP Odumosu ni kawọn olugbe ipinlẹ fi ọkan balẹ, ki wọn si jade lọ si ibi iṣẹ lọjọ Satide nitori eto abo to peye yoo wa fun wọn.
Kọmiṣọnaa ọlọpaa ni ki wọn kọ eti iku si awọn kan to n sọ kaakiri wi pe ki wọn maa jade lọjọ Abamẹta
CP Odumosu to sọ ninu atẹjade naa pe ileeṣẹ ọlọpaa ti ṣe agbekalẹ awọn ọlọpaa ti yoo palẹmọ awọn ọdaran to n jawọn eeyan ipinlẹ Eko lole ninu sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ loju popo.
Kọmiṣọnna ọlọpaa fawọn agbofinro ọhun ni ọkọ atawọn nkan mii ti wọn nilo lati ṣiṣẹ wọn.
O ṣalaye pe awọn ọlọpaa naa ṣetan lati pese abo to peye lori afara Eko Bridge, Apongbon, Cele, Ijora, Ojota/7up, Mike 12 ati agbegbe Surulere tawọn ọdaran ti n ṣọṣẹ julọ lasiko yii.
''Wámú wámú làwa ọlọ́pàá ń dúró de àwọn tó bá fẹ́ fa wàhálà lọ́jọ́ June 12''
Wamu wamu ni ileeṣẹ ọlọpaa duro ṣaaju iwọde tawọn eeyan kan n gbero lati ṣe lọjọ Abamẹta tii ṣe June 12.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Osun, SP Yemisi Opalola lo fidi ọrọ yii mulẹ fun BBc Yoruba.
''Kiki ni awọn ọlọpaa wa bi ibọn fawọn to ba fẹ da rogbodiyan silẹ lọjọ June 12 nipinlẹ Osun.
Gbogbo awọn ẹṣọ eleto aabo to fi mọ awọn sọja atawọn ẹṣọ eleto abo mii ni wọn ti parapọ ti wọn si n gbaradi fun iwọde June 12.

Oríṣun àwòrán, Facebook/Nigeria Police Force
Koda awọn ẹṣọ eleto abo ti n wọde kaakiri ilu fun igbaradi ṣaaju ayajọ ijọba awarawa ni Naijiria.
Igbaradi to gbopọn wa nilẹ lati ọdọ awọn oṣiṣẹ eleto abo ṣaaju ọjọ Abamẹta yii.
Awọn ọlọpaa atawọn ẹṣọ eleto abo mii naa mọ nipa gbogbo bo ṣe n lọ nipa ifẹhonuhan tawọn eeyan kan fẹ ṣe.
Ṣugbọn o yẹ ka kọgbọn nipa iwọde EndSARS lọdun 2020 to mu ẹmi lọ,'' agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa ṣalaye.
O ni ''kii ṣe pe ṣiṣe iwọde ko tọna labẹ ofin, ṣugbọn mo n fi asiko yii rọ awọn eeyan lati ma jẹ ki nkan bajẹ si ju ti tẹlẹ lọ.
Ọpọ eeyan lo fẹ fi iwọde boju lati wu oriṣiriṣii iwa ọdaran lọjọ June 12.''
Ninu ọrọ tiẹ, alukoro fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, Okasanmi Ajayi ti fawọn araalu lọkan balẹ lati ma ṣe foya lori iwọde tawọn eeyan kan n gbero lati ṣe lọjọ June 12.
SP Ajayi sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ṣetan lati daabo bo awọn eeyan lọjọ iwọde naa ati nigba gbogbo.
''Awọn ọlọpaa tun ti gbaradi lonii kaakiri ipinlẹ Kwara ọjọ Ẹti ṣaaju ayajọ June 12.
Wọn ṣe eyi lati jẹ ki awọn eeyan mọ wi pe ko si ewu loko fun ẹnikan kan lọjọ June 12.












