Ekiti rape cases: Ìjọba ìpínlẹ̀ Ekiti ké gbàjarè lórí bí fífi ipá bá èèyàn lòpọ̀ ṣe pọ̀ níbẹ̀

Ifipalopo

Oríṣun àwòrán, @Embyr

 Ijọba ipinlẹ Ekiti ti leri lati gbe ẹnikẹni to ba ṣe idiwọ tabi tako fifi iya jẹ ẹni to ba fi ipa ba eeyan ni ibalopọ, labẹ òfin.

Gẹgẹ bi ileesẹ iroyin abẹle, Channels Television ṣe so, ijọba sọ pe oun yoo gbẹsẹ le ilé ti wọn ba ti fi ipa ba ọmọdé lopọ.

Ninu atẹjade ti agbejọro Agba nipinlẹ naa, Wale Fapounda fi ọwọ si, ijọba Ekiti sọ pe o le ni ọgọfa ẹjọ ifipabani lopọ, to n lọ lọwọ ni awọn ile ẹjọ jakejado nipinlẹ naa.

Koda, o ni pe wọn jẹ pe pupọ ninu awọn ti wọn fi ipa balopọ ni ko setan láti yanju rẹ ni ilana òfin.

Ọgbẹni Fapounda ni botilẹjẹ pe iye àwọn to setan pẹlu ẹbi wọn lati satilẹyin fun ijọba ko gbeja wọn, ni ọgọfa, o ni awọn ti ko fẹ igbenija ofin pọ ju bẹẹ lọ.

Bakan naa ni ijọba ipinlẹ naa n sagbatẹru aba ofin ti yoo sọ ọ di ẹsun ọdaran fun ẹnikẹni to ba ni ki ẹni ti wọn fi ipa balopọ ma ṣe ẹjọ mọ, paapaa àwọn to ma n kọ lẹta pe awọn ko ṣe ẹjọ mọ.

Àkọlé fídíò, Rape cases in Nigeria: Ọmọ ọdun 5 àti 14 ni Kalu wà nígbà tí obìnrin fipá ba lòpọ̀

"Ẹ̀wọ̀n ọdun marun-un ni fún ẹni to ba jẹbi ẹsun yii.

Yatọ si aba ofin yii, wọn tun fẹ ṣe eyi ti yoo mu ki aabo wà fun ẹni to ba tu asiri ẹni to fi ipa báni lopọ.

Àkọlé fídíò, Blessing Olajide: Ẹ̀bí akẹ́kọ̀ọ́jáde fásitì Ilorin tí wọn pa ṣàlàyé ikú rẹ̀

Gẹgẹ bi Fapounda ṣe sọ, ijọba yoo gbẹsẹ le ile tabi ile itura ti wọn ba ti fi ipa ba ọmọdé lopọ, wọn o si tun gba iwe àṣẹ onilẹ (CofO) lọwọ ẹni to ni ile.

Àkọlé fídíò, Olagunsoye Oyinlola: Kí Olorun dáríjì wá lórí ọ̀rọ̀ yíi, a ti kùnà ìlérí wa fún ìran Yorùb

Ipinlẹ Ekiti jẹ pataki lara awọn ipinlẹ ni Naijiria, to fi ọwọ líle mu ẹsun ifipabani lopọ, pẹlu ijiya to lagbara.

Koda, ipinlẹ naa ni iwe to n kọ orúkọ àwọn afipabanilopọ si, to si tun ma n fi aworan wọn han fun gbogbo aye.

Àkọlé fídíò, Peter Fatomilola: Robbery burú ju Yahoo lọ, iṣẹ́ ọpọlọ lọmọ Yahoo fi ń gba owó ìran baba