Unilag shut down?: Àwọn aláṣẹ Fásitì UNILAG ti ibùgbé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pa torí ọwọ́jà Covid-19

Unilag

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn alaṣẹ ileewe naa gbe igbesẹ naa lati da abo bo awọn akẹkọọ naa lọwọ ajakalẹ aarun Coronavirus ti ọwọja kẹta ni ipinlẹ Eko.

Awọn alaṣẹ ileẹkọ Fasiti ipinlẹ Eko (UNILAG) ti paṣẹ ki gbogbo awọn akẹkọọ kuro ni ọgba ileẹkọ naa.

Awọn adari ileẹkọ naa ni ki awọn akẹkọọ naa kuro ni yara igbe ileẹkọ naa.

Àkọlé fídíò, Coronavirus after one year in Nigeria: Níbo ni ọ̀rọ̀ Covid 19 dé dúró ní Nàìjíríà?

Bakan naa ni wọn kede pe awọn akẹkọọ yoo bẹrẹ ẹkọ kikọ lori ẹrọ ayelujara lati Ọjọ Kẹrindinlọgbọn, Oṣu Keje, ọdun 2021.

Awọn alaṣẹ ileewe naa gbe igbesẹ naa lati da abo bo awọn akẹkọọ naa lọwọ ajakalẹ aarun Coronavirus ti ọwọja kẹta ni ipinlẹ Eko.

Bakan naa ni wọn fi lede pe ọpọlọpọ akẹkọọ lọ ti wa ni ileewosan lori aisan to ṣeeṣe ko niiṣe pẹlu aarun Coronavirus.