Futa Akure: Àwọn aláṣẹ iléẹ̀kọ́ FUTA ní akẹ́kọ̀ọ́ náà, Adeyinka Daniel tí kú kí wọ́n tó gbe wá sí ''health Centre'' FUTA

Awọn alaṣẹ ileẹkọ Fasiti Federal University of Technology Akure, FUTA ti ba ẹbi ati ara akẹkọọ wọn Adeyinka Daniel kẹdun lori iku akẹkọọ naa.
Akọwe ileewe naa, Richard Arifalo ninu atẹjade ti ileewe naa fi lede salaye ohun to ṣẹlẹ nipa iku akẹkọọ naa.
Arifalo ni iroyin to tẹ awọn lọwọ ni pe lẹyin iṣẹlẹ ijamba ọkọ to waye pẹlu awọn akẹkọọ marun un naa ni agbegbe Oyemekun, ni wọn kọkọ gbe awọn marun un ọhun lọ si ileewosan aladani.
- Olórí ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ PDP sọ àbùkù ọ̀rọ̀ sí Ààrẹ Buhari àti SGF, ẹ̀wọ̀n jàntò ló rí he!
- Tunde Bakare journey in life: Bàbá bàbá mi ni Lèmọ́mù àkọ́kọ́ ní Sodeke Abeokuta ṣùgbọ́n..
- Ẹ wó bí akẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ìṣègùn ṣe rí òkú ọ̀rẹ́ rẹ̀ nínú kílásìí...
- Dáa padà! Àwa kìí ṣe ẹgbẹ́ kan náà pẹ̀lú APC tó dojú Nàìjíríà kodò -PDP sí Jega
- Wo àmí ẹ̀yẹ tí Abba Kyari tí gba gẹ́gẹ́ bí ògbóǹtagìrì ọlọ́pàá kí wọ́n tó fi ẹ̀sùn ìwà àjẹbánu kàn án
- Ta ni Tunji Disu ti wọ́n kéde láti rọ́pò Abba Kyari?
Amọ awọn mẹrin to n gba iwosan n, ti wọn si n ṣe daadaa amọ Daniel ko yipada lasiko to n gba iwosan.
Eyi lo mu ki ileewosan ni ki wọn gbe e lọ si ileewosan ijọba ni ilu Ọwọ, amọ awọn obi ọmọ naa wo pe ilu ọwọ jina ti wọn si gbe ọmọ naa lọ si ileewosan Health centre ti ileewe naa.
Amọ dokita ni igba ti wọn ma a fi de ileewosan naa, dokita to wa lẹnu iṣẹ gbiyanju lati doola ẹmi rẹ ni nkan bi aago mẹta oru, amọ o ti jẹ Ọlọrun nipe.
Gbogbo igbiyanju wọn lati doola ẹmi ọmọ naa jasi pabo, ti wọn si fẹ gbe e lọ si ile igbokusi ni idaji ni nkan bi aago mẹta owurọ pẹlu ọkọ pajawiri ileewe naa.
Amọ, dokita naa ni awọn obi kọ, ti wọn si gba lati gbe e lọ si ile lati lọ sin

Awọn akẹkọọ di opopona Akure si Ilesa lati fẹhọnuhan
Nibayii, awọn akẹkọọ ti di oju ona opopona Akure si ilesa lati fi ẹhọnu wọn han nipa akẹgbẹ wọn to ku naa, pẹlu alaye pe awọn aṣọna ni ko gba ki wọn tete gbe akẹkọọ naa lọ si ilewosan.
Awọn afẹhọnuhan naa ni ileewosan tun sọ wi po ko si epo ninu ọkọ pajawiri ti yoo gbe ọmọ naa kuro ni ileewosan naa fun itọju to peye.
Wọn ni dandan, adari ileewe naa ni awọn fẹ ba sọrọ, ti wọn si sọ wi pe ko si iṣẹ loni lati ṣedaro akẹgbẹ wọn to papoda.
Bakan naa ni awọn ọlọpaa ti wa nibẹ lati ri pe ifẹhọnuhan naa ko jasi rogbodiyan, ti ohun gbogbo si n lọ ni rọwọrọsẹ.
Wo ǹkan tí a mọ̀ nípa akẹ́kọ̀ọ́ fásitì FUTA tó kú àti ìdí tí àwọn akẹ̀kọ̀ọ́ fi faraya
Awọn akẹkọọ ileewe giga Fasiti,FUTA ni ilu Akure ti bọ si igboro lati fi ẹhọnu han lẹyin ti ọkan lara wọn gbẹ mi mi ni oru mọju lẹyin ijamba ọkọ.
Akọroyin BBC to wa nibi ifẹhọnu han naa ni inu awọn akẹkọọ naa ko dun rara, ti wọn si ti gbogbo ọna mejeeji to wọ inu ile iwe naa.
Ọkan lara awọn akẹkọọ to n fẹhọnu han naa salaye bi iṣẹlẹ to gbẹmi akẹkọọ 200 level naa ṣe waye.
''Akẹkọọ to wa ni ipele Keji (200 Level) Daniel Akinyele wa ninu ijamba ọkọ pẹlu awọn akẹkọọ mẹrin miran ni alẹ ana ni ita ileẹkọ naa.''
''Awọn akẹgbẹ rẹ gbe e digba digba lọ si ileewosan ni ita ileewe naa, amọ ileewosan naa ni ki wọn gbe lọ si ileewosan Health centre to wa ni ileẹkọ naa fun iwọsan to peye.''
''Igbiyanju awọn akẹkọọ bii tirẹ lati gbe lọ si ileewosan to wa ninu ọgba fasiti naa ni ko lọ ni irọwọrọṣẹ nitori awọn aṣọle ẹnu ọna ọgba naa ko tete fun wọn laaye lati wọn ileewe naa.''

''Lẹyin ọpọlọpọ awuye wuye ti wọn wọle tan, ni awọn oṣiṣẹ ileewosan fasiti naa ni awọn ko ni epo ninu ọkọ pajawiri to le e gbe akẹkọọ naa lọ si ileewosan ijọba ni igboro ni kiakia fun ayẹwo to peye.''
Gẹgẹ bi ọrọ awọn akẹkọọ naa, ileewosan ninu ọgba ileẹkọ naa ni Daniel dakẹ si lai gba iwosan to peye.
Awọn akẹkọọ na n fayara pe awọn alaṣẹ ileewosan ati ileewe naa to fi mọ awọn aṣọbode ti ko tete ṣilẹkun lo jẹ ki akẹkọọ naa gbẹmi mi lai tọjọ.
- Ìjọba Amẹ́ríkà ti kó abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19 mílíọ̀nù mẹ́rin fún Nàìjíríà
- Taní Wolí rẹ̀? Èmí ti jèrè ''Minister''; Woli Joshua Iginla fí ọkọ̀ ńla ta mí lọ́rẹ- Alaseyori tó kọ orin Oniduromi
- Àwọn dókítà da iṣẹ́ sílẹ̀ káàkiri Naijiria, ilé ìwòsàn dá páròpáro!
- Kí ni yóò ṣẹlẹ̀ sí gbajúmò ọlọ́pàá, Abba Kyari tí wọ́n kó pọ̀ mọ́ "rógà" pẹ̀lú Hushpuppi?
- Njẹ́ o mọ̀ pé bíi ọdún 700 sẹ́yìn ni wọ́n ti ń bọ Osun-Osogbo? Mọ̀ síi nípa ìtàn ojúbọ̀ nàá


















