Lagos Covid-19 Test: N50,400 géérégé lẹ ó san láti ṣe àyẹ̀wò Covid-19

Ọjọgbọn Akin Abayomi

Oríṣun àwòrán, @ProfAkinAbayomi

Lara akitiyan ati tun fogun mọ arun Coronavirus, ijọba ipinlẹ Eko ti fun awọn ileewosan aladani kan ni Eko niwe aṣẹ ṣiṣe ayẹwo Covid-19.

Ọjọ aje ọjọ kọkandilọgbọn oṣu kẹfa ọdun 2020 ni wọn ṣe ifilọlẹ apapọ ẹgbẹ awọn yara ayẹwo ti awọn eeyan ti le maa lọ ṣe ayẹwo arun Covid-19 nipinlẹ Eko.

Ẹwẹ, nigba ti BBC Yoruba kan si ọkan lara awọn laabu ayẹwo naa, wọn fi aridaju han pe irinwo le ẹgbẹrun lọna aadọta Naira (N50,400) n owo ti eeyan kọọkan to ba wa ṣe ayẹwo yoo maa san.

Owo yii kii ṣe ipinu laabu ti a pe nikan o, agbẹnusọ ti a ba sọrọ jẹ ko di mimọ pe iye kan naa ni awọn laabu toku naa yoo maa gba.

Kọmisana eto ilera fun ipinlẹ Eko, Ọjọgbọn Akin Abayomi fi si oju opo Twitter rẹ pe lẹyin ọpọlọpọ ayẹwo ifigagbaga, awọn yara ayẹwo meje ti ijọba Eko yan ni:

·Total Medical Services

·SynLab

·54 Gene

·Medbury medical Services

·Biologix Medical Services

·02 Medical Services

·Clina Lancent Lab

Awọn aṣoju awọn laabu pẹlu Kọmisana eto ilera ipinlẹ Eko, Akin Abayomi

Oríṣun àwòrán, @ProfAkinAbayomi

Agbẹnusọ ọkan lara awọn laabu ti a pe yii lati mọ boya lootọ ni iroyin ti a gbọ pe N50,400 ni ẹni to ba fẹ ṣe ayẹwo yoo maa san ṣalaye pe bẹẹ ni ṣugbọn ijọba Eko ko mu u ni dandan fawọn eeyan.

O ṣalaye pe kii ṣe gbogbo ile iwosan aladani lo n ṣe ayẹwo naa ṣugbọn awọn ni anfani lati wa lara awọn to n ṣe e.

Kẹẹ to lọ fun ayẹwo, ẹ o pe nọmba laabu ọhun wọn yoo si fi atẹjiṣẹ kan ti ijọba pese ranṣẹ sii yin eyi ti ẹ o lo lati forukọ silẹ lọdọ wọn ki wọn to dajọ ayẹwo fun yin.

Àkọlé fídíò, Seyi Makinde; Ilé iwosan kan ṣoṣo tó wà ní Idí-Iroko /Adewole tí bàjẹ́ pátápátá.

Nibi eto ifilọlẹ naa, ọjọgbọn Akin Abayomi jẹ ko di mimọ pe awọn laabu ti wọn yan yii ni gbogbo irinṣẹ ati ohun to tọ lti ṣe ayẹwo Covid-19 tori naa ni wọn ṣe yan wọn.

Ni ipari, aṣoju gbogbo laabu ti wọn yan fọwọ si iwe adehun ni kọọkan pẹlu ijọba ipinlẹ Eko.

Àkọlé fídíò, Láàrín ìdílé ẹlẹ́ni márùn ún yìí, ọmọ kan ṣoṣo ló léè sọ̀rọ̀