Yoruba Nation: Ó yẹ ká jókòó sọ̀rọ̀ kó má baà di ogun àti ìjà - Alara ti ilara-Epe

Àkọlé fídíò, A ti ń fẹ́ Hausa, Ibo, ó sàn ka jọ ṣe é ní tùbí-ǹ-nùbí lórí ọ̀rọ̀ Nàìjíríà ju ìjà ogun lọ - Ọba Alara

Alara ti ilu Ilara-Epe ni bi a ba wo o daadaa, atigba ogun Biafra ni iṣoro ti Naijiria paapaa ilẹ Yoruba n koju bayii toripe "awọn nkan ti a ro pe a ti bori nigba ogun naa lo wa n ṣẹl bayii".

Lori eto abo to mẹhẹ lorilẹede Naijiria, Ọba Olufolarin Ogunsanwo mẹnuba eyi to kan ilẹ Yoruba nibẹ.

Ninu ifọrọwanilẹnuwo pẹlu ileeṣẹ iroyin BBC Yoruba tun sọ bi iṣoro yii ṣe le ṣakoba.

"Egungun ti wọnu iṣan, iṣan ti wọ inu iṣa, awọn ọmọ wa ti n fẹ ọkọ loke ọya, wọn n fẹ Ibo, torinaa, o dara ki a jọ jokoo ka ṣe apero lori ọrọ Naijiria".

Kabiyesi ni nigba ti awọn oyinbo alawọfunfun ṣe eto idapọ ipinlẹ meji ni Naijiria iyẹn "Amalgamation" mọ ohun ti wọn ri ti wọn fi ṣe bẹẹ́.

Bakan naa o tọka si idi ti orilẹede Naijiria tilẹ fi maa n pin agunbanirọ si ipinlẹ mii ti kii ṣe tirẹ eyi ti gbogbo ẹni to kawe gboye ni iriri rẹ.

Ọba Alara rọ awọn ọmọ Yoruba pe ki wọ́n ṣe pẹlẹpẹlẹ ki wọn si farabalẹ dipoo gbigbero ati gbigbe igbesẹ lati tuka.