Crowwe: Ìdí tí mo fi ní kí Google yọ Crowwe Aapù mí kúro - Adamu Garba

Ìdí tí mo fi ni kí Google yọ Crowwe áàpù mí kúro-Adamu Garba

Oríṣun àwòrán, Adamugarbaii/instgagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Alákoso àti olùdásilẹ̀ ẹgbẹ́ IPI Adamu Garba sọ pé ki Google yọ áàpù òun Crowwe kúrò lórí ayélujára nítóri àwọn àtunṣe kan wa ti ọ nílò àtunṣe ni àwọn ṣe pè fún yíyọ rẹ̀.

Garba tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọnolóyè ẹgbẹ́ òṣèlú All Progress Congress sọ èyí nínú ìtakùrọsọ pẹ̀lú ìwé iròyìn Punch.

O ni ó pẹ́ jù áápù náà yóò pada sójú òpó goggle lónìí ọjọ́ Iṣẹgun.

Àkọlé fídíò, Bí wọ́n ṣe ya Sinima Ayinla Omowura rèé, BBC Yorùbá fọ̀rọ̀ wá àwọn òṣèré lẹ́nu wò

Olóyè ẹgbẹ́ òṣèlú APC òun ló gbé ilé iṣẹ́ twitter lọ sí ilé ẹjk ni ọdún tó kọjá lórí ipa tí wọ́n kó lásìkò ìwọ́de #ENDSARS.

Ó sọ pé láti ọjọ́ mẹ́wàá sẹ́yìn tí ìjọba ti fòfin de se iṣẹ́ Twitter ni Nàìjíríà ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ àwọn ènìyàn ló ti wá sí ojú òpó Crowwe.

Garba ni èyí ló fàá tí àwọn ṣe nílò láti ṣe àwọn àtúnṣe kan láti fi ààyè gba àwọn tó ń darapọ̀, èyí ní òun ṣe ni ki Google yọ ná.

Lórí ìbéèrè pé bóyá wọ́n yọ áàpù náànítolripé àwọn ọmọ Nàìjíríà kọ nǹkan ti kò dára nípa rẹ̀ ni wọ́n se yọ. Garba ni irọ́ ni èyí àti pẹ google kii yọ áàpù nítorí pé àwọn ènìyàn sọ nǹklan tí kò dára nípa rẹ̀.

Ìdí tí mo fi ni kí Google yọ Crowwe áàpù mí kúro-Adamu Garba

Oríṣun àwòrán, Adamu Garba

Garba ni pé "awa ni a yọ kúrò nítorí à nilò láti ṣe àtúnṣe kan lórí rẹ̀, kí a sì dá pada.

A rí àwọn nǹkan ti ko ni jk kí ó ṣiṣẹ́ dáradara lọ́jọ́ ìwájú nítori rl ni a ṣe ni kí a tètè mójútó ki a yọ kúrò kí a sì fi síbẹ̀ padà.

Ẹ̀wẹ́, títí di àsìkò yìí google ko tí fi ọ̀rọ̀ léde ìdí tí wọ́n fi yọ crowwe, sùgbọ́n àwọn òfin to dí ibi ti àwọn ápù sí (Play store) fi han pé àwọn máá n yọ áàpù tó bá tẹ́ òfin wọn lójú mọ́lẹ̀ ni.

Skip Instagram post
Allow Instagram content?

This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of Instagram post

" Tí wọ́n bá ti yọ áàpù, èyí tó wà lárí Play Store ko ni ṣiṣẹ́ mọ́ titi tí àtúnṣe yóò fi wa lórí rẹ̀.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'