Oyo beggars: Ìjọba Oyo ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kó àwọn oníbárà kúrò láàrin ìgboro ìlú Ibadan

Gomina Seyi Makinde

Oríṣun àwòrán, Seyi Makinde

Ijọba ipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ sini ko awọn onibara kuro ni ibugbe wọn to n bẹ lopopona Jẹmibẹwọn ni agbegbe Sabo nilu Ibadan lo si ibugbe tuntun ni agbegbe Akinyẹle.

Igbesẹ naa ti ijọba ti n gbero lati bi oṣu kan sẹyin lo bẹrẹ ni nnkan bi aago meje owurọ ọjọ Iṣẹgun lẹyin ti awọn aṣoju ẹya Ariwa ati awọn onibara naa ṣe abẹwo si ibugbe naa lọjọ Abamẹta.

Kọmisana fun ọrọ ayika n'ipinlẹ Ọyọ, Amofin Idowu Oyeleke to le iwaju iṣọri kọkọ awọn onibara naa lọ si Akinyẹle ṣe alaye wi pe ibugbe naa kun fun awọn ohun amayedẹrun bi ile ẹkọ, ile iwosan, ati ibudo. igbafẹ.

Àkọlé fídíò, 'Ọwọ́ mi ti ń jẹ́rà ká tó mọ̀ pé àfi kí wọ́n tún gé e bí mo bá ṣì fẹ́ máa ṣe iṣẹ́ awakọ̀ lọ'
Awọn Alagbe

Atẹjade lati ọwọ akọwe iroyin fun Gomina Ṣeyi Makinde, Arakunrin Taiwo Adisa tọka pe lara awọn ẹka ileeṣẹ ijọba to ṣe agbekalẹ eto naa ni, ẹka to n ri si ọrọ awọn obinrin ati amojuto tolori-tẹlẹmu, ẹka iroyin, aṣa ati irinajọ igbafẹ, ẹka to n risi ọrọ ijọba ibilẹ ti ọrọ oye tofimọ ọfisi akọwe ajọ to n ṣe akoso owo iranwọ nipinlẹ Ọyọ eleyii Kọmisana ọlọpaa tẹlẹri, Fatai Owoṣeni n ṣe akoso rẹ.

Ni aago mẹjọ owurọ oni, ọkọ akero nla mẹta lo ti kun fun awọn onibara ti ijọba n ko kuro lati opopona Jẹmibẹwọn nilu Ibadan lọ si Akinyẹle.

Iroyin sọ wi pe awọn eero ti ọkọ yoo ko ṣi ṣẹku.

Àkọlé fídíò, 'Sister Tope Alabi yà mí lẹ́nu gan o pé "Oniduro mi" kìí ṣe orin tó yẹ kí ọlọ́run fún mi'