Timi Dakolo: Gbajúgbajà olórin sọ ìdí tí òun àti ìyàwó rẹ̀ ṣe sọ fún àwọn ọmọ wọn nípa bí wọ́n ṣe fí ipá bá ìya wọn lọ̀pọ̀

Oríṣun àwòrán, Instagram/Timi Dakolo
Gbajugbaja olorin, Timi Dakolo ti ni oun ati iyawo oun Busola Dakolo sọ fun awọn ọmọ wọn nipa bi pasitọ kan ṣe fi ipa ba iya wọn lopo ni igba to wa ni kekere.
Ọdun 2019 ni Busola Dakolo jade sita lati sọ bi gbajugbaja pasitọ kan ṣe fi ipa ba oun lopo nigba to wa ni ọmọde, ti kii si ṣe igba kan ni pasitọ naa hu iru iwa bẹẹ pẹlu rẹ.
Timi Dakolo sọ ọrọ yii lasiko ifọrọwanilẹnuwo pẹlu gbajugbaja sọrọsọrọ, Toke Makinwa lori ẹrọ ayelujara.
- Ọdun 2019 ni Busola Dakolo jade sita lati sọ bi gbajugbaja pasitọ kan ṣe fi ipa ba oun lopo ni gba to wa ni ọmọde.
- Rahmon ń múra láti lọ rí ìyàwó àti ìbèjì tó bí ní US ni wọ́n bá pa á níbi ìjà tó bẹ́ sílẹ̀ ní Iwo road
- Olólùfẹ́ méjì lẹ̀pọ̀ lásìkò ìbálòpọ̀, ni wọn bá figbe ta
- Alhaji Sikiru Ayinde Barrister ṣí fìlà gba àdúrà ọjọ́ iwájú fún mi ni - Besco Azeez Tijani
Dakolo ni lootọ ni awọn sọ fun awọn ọmọ wọn nipa iṣẹlẹ naa ki wọn ba le mọ nitori bi awọn ṣe tọ awọn ọmọ wọn yatọ si ti ẹlomiran.
O ni awọn ọmọ awọn mọ bi wọn ṣe n sọ nipa ohun ti wọn ba n la kọja lai fi nkankan pamọ fun awọn obi wọn.

Oríṣun àwòrán, Instagram/Timi Dakolo
''Mo jẹ ki wọn mọ wi pe eniyan nla ati eniyan pataki to ni igboya ni iya wọn to si la iṣoro to bani ni inu jẹ kọja ni kekere.''
''Bi o tilẹ jẹpe ko ye wọn dajudaju gbogbo nkan to waye ni ọdun 2019, amọ wọn mọ wipe inu iya awọn ko dun, ti wọn si ma n di mọ ọ ni gbogbo igba ti wọn ba ti lọ si ọdọ rẹ.''

Oríṣun àwòrán, Instagram/Timi Dakolo
Lori ibeere wi pe ṣe ọrọ ti iyawo rẹ sọ nigba naa nipa bi wọn ṣe fi ipa ba lopo ni ipa buburu lori iṣẹ rẹ gẹgẹbi olorin, Dakolo ni oun ko fi igba kankan rọnu nipa ibeere naa nitori oun gbe ẹbi oun saaju ohun gbogbo.
- Bìlísì míì wáyé n‘Ibadan, ọmọ ìṣọta kọlu OPC, ẹ̀mí bọ́
- Lóòótọ́ ni màmá mi ní àìsàn ọpọlọ 'Schizophrenia' kó tó kú - Iyabo Ojo
- Àwọn ọ̀dọ́ Yoruba Nation tún ya bo Idi Iroko láti ṣí ẹnu bodè sílẹ̀, àmọ́...
- Àlùfáà kan níbi tí wón bí Jesu sí tan àbẹ̀là nítorí ikú T.B. Joshua
- Àwọn ọlọ́pàá máa ń yọ Baba Ijesha jáde látimọ́lé lálaalẹ́ - Princess
''Nigba ti eniyan kan bere ibeere yii lọwọ mi, oun ti mo sọ ni wi pe mi o le se alaimọ orin kọ, ti eniyan miliọnu mẹfa ba ko ara wọn jọ, ma a ṣi kọrin ti gbogbo eniyan yoo si fẹran mi.''
''Ohun ti mo mọ ni wi pe ibi ti a ba ti pe ni ori, a ko gbọdọ fi tẹlẹ, gẹgẹ bi ọkọ ninu ile, a gbọdọ jẹ awokọṣe nipa gbigbe awọn ẹbi wa larugẹ ati ṣiṣe itọju wọn''

Oríṣun àwòrán, Instagram/Timi Dakolo
Bakan naa ni Timi Dakolo ni o ṣoro fun iyawo oun lati ba oun sọrọ nipa ibapabanilopọ naa nitori ọpọ igba ti o ba fẹ sọrọ ni oun kii fun ni aaye, amọ nigba ti oun gbọ nipa oun ti iyawo oun la kọja naa, inu oun bajẹ gidigidi.
Timi Dakolo wa parọwa si awọn tọkọ-taya lati ma a ba ara wọn sọ otitọ ọrọ loore-koore nitori igbeyawo kii ṣe oun ti eniyan n danikan pero lati ṣe, awọn mejeeji gbọdọ fi ọwọ sowọpọ.













