Fífi owó tẹ́tẹ́ san ìdá mẹ́wàá dàbí rìbá níwájú Ọlọ́run - Mike Bamiloye

Oríṣun àwòrán, Instagram.com/p/Cmewretrc58/
Ilumọọka ajihinrere to tun jẹ oṣere fiimu Kristni, Mike Bamiloye ti ṣe ikilọ fun awọn ọmọ lẹyin kristi lori fifi owo tẹtẹ san ida mẹwaa nile ijọsin.
Bamiloye, to jẹ oludarí Mount Zion Drama Ministry, sọrọ yii lori opo ayelujara rẹ, Instagram, O ni o ya oun lẹnu bi awọn Kristẹni kan ṣe ro pe owo tẹtẹ le pẹtu si Ọlọrun lọkan.
O sapejuwe irufẹ igbesẹ naa gẹgẹ bii fifi riba lọ Ọlọrun
This article contains content provided by Instagram. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read Instagram cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of Instagram post
“Egbọn, o ta tẹtẹ, o jẹ, o tun wa yọ ida mẹwaa nibẹ fun ile Oluwa, lati ri oju rere Oluwa. Ṣe o rope o le fi ọwọ bo oju Oluwa, ko wa fi owo oẹtu si ọkan pẹlu riba?”
Lọdun to kọja ni ilumọọka ajihinrere to tun jẹ oṣere fiimu Kristni, sọ oko ọrọ sita lori ọrọ ayajọ ololufẹ ti ọpọ mọ si Valentine.
O sọrọ naa ni ayajọ ololufẹ ku ọla lọdun to lọ ni bi awọn mii ṣe n gbaradi fun ayajọ ọjọ ololufe ti o maa n waye ni ọjọ kẹrinla, oṣu keji ọdun.











