JJC Skillz, ọkọ Funke Akindele tẹ́lẹ̀ padà sínú ẹ̀sìn Islam, o ní Allah dáríjín mi!

Aworan JC Skillz

Oríṣun àwòrán, "JC Skillz

Agba ọjẹ akọrin takasufe, to tun jẹ ọkọ nigba kan fun gbajumọ oṣere, Funke Akindele, Abdulrasheed BelloJJC Skillz, sọ pe oun ti pada sinu ẹsin Islam.

Ninu ọrọ kan to kọ si ori ayelujara Instagram rẹ, ni JJC Skillz ti sọ pe oun ti sọnu tẹlẹ, amọ ni bayii, ọlọrun ti wa oun rí.

O ni “Allah, mo tọrọ aforijin ati irọrun ninu ẹsin mi ati igbe aye mi.”

Ninu fidio naa lo ti ṣafihan ara rẹ ni mọṣalaaṣi kan niluu Abuja, to si n tọrọ awọn nkan to nilo fun igbeaye irọrun ninu ẹsin Islam.

Ṣaaju fidio naa, lo ti n kọ awọn ọrọ nipa ẹsin Islam lati bi ọjọ diẹ sẹyin.

Ṣugbọn nkan ti ko han ni pe boya JJC Skillz fi igba kankan ṣe ẹsin miran lasiko to fi kọ Islam silẹ.

Taa ni Abdulrasheed Bello?

Ilu Kano ni wọn bi Abdulraheed Bello si, lọdun 1977.

Orilẹ-ede Naijiria lo gbe titi to fi lọ si UK lọmọ ọdun mẹrinla, nibi to gbe dagba.

Ilumọọka olorin ni nilẹ okeere ati ni Naijiria.

Yatọ si pe o jẹ akọrin, o tun jẹ olootu orin ati oludari orin ati fiimu.

Oṣu Kẹjọ, ọdun 2016 ni oun ati Funke Akindele ṣe igbeyawo wọn niluu London, ti wọn si bi ibeji lọdun 2018.

Gẹgẹ bi tọkọtaya, wọn jọ gbe awọn ere ati orin oriṣiriṣi jade.

Ọdun 2022 ni Abdulrasheed Bello kede pe igbeyawo wọn ti tuka, lẹyin ọdun mẹfa.