BBC n wa akọ̀ròyìn tó dántọ́ láti gba àmì ẹ̀yẹ̀ Komla Dumor

Komla Dumor
Àkọlé àwòrán, Ipa ti Dumor ni nilẹ Africa ati gbogbo agbaye ko kere rara, nitori bo ṣe ma n ṣe agbatẹru iṣẹ iroyin to pojuowo.

Ileeṣẹ iroyin BBC n wa awọn akọroyin to jẹ ọdọ to tun dantọ lati gba ami ẹyẹ "BBC World News Komla Dumor Award," ti ọdun 2023.

BBC wa n ke si awọn akọroyin kaakiri ilẹ Afrika lati forukọ silẹ fun ami ẹyẹ naa, pẹlu erongba lati ṣawari awọn akọroyin to pegede nilẹ Afrika.

Ẹnikẹni to ba gba ami ẹyẹ naa yoo lo oṣu mẹta ni olu ileeṣẹ iroyin BBC to wa niluu London, nibi ti yoo ti kọ si nipa iṣẹ akọroyin.

Aago mejila oru, ọjọ kẹrinla, oṣu Keji, ọdun 2023 ni eto iforukọsilẹ naa yoo wa sopin.

Wọn ṣe agbekalẹ ami ẹyẹ Komla Dumor fun iranti akọrọroyin BBC naa, to jẹ ọmọ orilẹ-ede Ghana, fun iṣẹ ribiribi to ṣe gẹgẹ bii akóroyin BBC ko to dagbere faye lẹni ọdun mọkanlelogoji lọdun 2014.

Iyawo rẹ, Kwansema Dumor sọ pe inu oun dun fun ipa ti oloogbe naa ni nileeṣẹ iroyin BBC, ati bi wọn ṣe n ṣe iranti rẹ nipa ami ẹyẹ ọhun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

BBC ti wa rọ awọn akọroyin kaakiri ilẹ Afrika lati forukọsilẹ fun anfaani lati gba ami ẹyẹ ọhun, eyi to jẹ ọna lati mọ riri ati lati gbe awọn akọroyin to tayọ, to n gbe nilẹ Africa l’arugẹ.

Ẹnikẹni to ba gba ami ẹyẹ naa, yatọ si pe yoo gba idanilẹkọọ nileeṣẹ iroyin BBC ni London, yoo tun ni anfaani lati rinrinajo lọ si orilẹ-ede Afrika kan lati jabọ iroyin to ba nifẹ si, eyi ti a o ṣafihan rẹ fun gbogbo agbaye.

Ipa ti Dumor ni nilẹ Africa ati gbogbo agbaye ko kere rara, nitori bo ṣe ma n ṣe agbatẹru iṣẹ iroyin to pojuowo.

O si tun ma n jabọ awọn iroyin to jẹ ojulowo nipa ilẹ Africa.

Nitori naa ni BBC ṣe pinnu lati tẹsiwaju ninu igbe aye rẹ, nipasẹ ami ẹyẹ naa lati le ro awọn akọroyin nilẹ Africa ni agbara fun jijabọ ojulowo iroyin nipa Africa fun awujọ agbaye.

Dingindaba Jonah Buyoya, agbohunsafẹfẹ lati orilẹ-ede Zambia lo gba ami ẹyẹ naa lọdun to kọja – akọroyin akọkọ to gba a lati Gusu Africa.

Lasiko to fi wa pẹlu BBC, o rinrinajo lọ si Seychelles lati jabọ iroyin lori ọna ti awọn irugbin to n dagba lori òkun lorilẹ-ede naa le ṣe iranlọwọ fun amojuto ayipada oju ọjọ.

O ni “awokọṣe ni Komla Dumor jẹ fun mu, nitori naa ni gbigba ami ẹyẹ yii ṣe jẹ nkan ọlá fun mi”.

Liliane Landor, ọga agba kan ni BBC, sọ pe ami ẹyẹ naa ati awọn to ti gba a jẹ ẹri igbeaye ifọkansin Komla si awọn iroyin nipa Africa.

Ta ni Komla Dumor?

Komla Dumor ni sọrọsọrọ lori eto Focus on Africa, eto akọkọ ti BBC gbe kalẹ lori amohunmaworan, eyi ti wọn n ṣe afihan rẹ lojoojumọ fun awọn eeyan ilẹ Africa ni ede Gẹẹsi.

Ori akanṣe iroyin BBC World News ni wọn ti n ṣafihan rẹ tẹlẹ, amọ lọdun yii, yoo darapọ mọ BBC News Channel lati da duro gẹgẹ bi ileeṣẹ amohunmaworan ti yoo ma a gbohun safẹfẹ tọsan-toru.

O tun jẹ ọkan lara awọn sọrọsọrọ lori eto BBC World News’European.

Dumor darapọ mọ BBC lọdun 2007 lẹyin to ti kọkọ ṣiṣe lawọn ileeṣẹ iroyin kan ni Ghana, tii ṣe orilẹ-ede rẹ.

Laarin ọdun 2007 si 2009, oun lo maa n tukọ eto Network Africa fun ẹka "BBC World Service", nigba to kuro nibẹ o darapọ mọ eto "The World Today."

Ni 2009, Dumor ni ẹni akọkọ ti yoo tukọ eto "African Business" lori ikanni BBC World News ati Africa Business report.

O rinrinajo kaakiri ilẹ Afrika, nibi to ti ba awọn alẹnulọrọ nipa owo ṣiṣẹ kaakiri ilẹ Afrika pade.

Lọdun 2013, iwe iroyin New African magazine kede rẹ gẹgẹ bii ọkan lara ọgọrun ọmọ ilẹ Afrika la ipa rere julọ.

Awọn to ti gba ami ẹyẹ naa sẹyin

  • 2015: Nancy Kacungira latiUganda
  • 2016: Didi Akinyelure lati Naijiria
  • 2017: Amina Yuguda lati Naijiria
  • 2018: Waihiga Mwaura lati Kenya
  • 2019: Solomon Serwanjja lati Uganda
  • 2020: Victoria Rubadiri lati Kenya
  • 2022: Dingindaba Jonah Buyoya lati Zambia