Olawale Ibrahim Olofooro Brymo: Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ lọ ní sùúrù kí ẹ dàgbà díẹ̀ síi, Aṣiwaju ló ní ìrírí àti àṣìrí tó fi lè ṣe é lásìkò yìí

Àkọlé fídíò, Olawale Ibrahim Olofooro Brymo:Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ẹ lọ ní sùúrù kí ẹ dàgb[pa díẹ̀ síi, Aṣiwaju ló

Nitootọ ni Tinubu fun mi lowo 'ẹ ṣeun' nigab kan ṣugbọn.....- Brymo

Olawale Ibrahim Ashimi to jẹ gbajugbaja olorin ti ba BBC Yoruba sọrọ lori ibeere ti awọn eeyan n beere nipa idi to fi n pariwo Tinubu kiri lasiko yii.

Brymo sọ pe ko si idi fun awọn ẹya tabi eeyan iran kankan to n ba oun binu lori ayelujara ati loju aye nitori irufẹ ẹni to wu oun lati dibo oun fun.

O sọ nipa iriri ati imọ agba ati pe oun ko ri oun to buru ninu ọjọ ori Bola Tinubu to n dije dupo aarẹ pẹlu awọn mii bii Peter Obi, Atiku Abubakar ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Saaju ni awọn kan ti n sọ pe ki awọn eeyan ma dibo fun Brymo lati gbami ẹyẹ AFRIMA nitori pe wọn ni o n ṣatileyin fun Tinubu to si n sọro lodi si oludije mii.

Brymo ṣalaye idi ti oun fi n ṣatilẹyin pe onikaluku lo le polongo fun e\ni to wu u nigba to ba wu u.